1 Samuel 5:10
“Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ sí Ekroni. Bí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ṣe wọ Ekroni, àwọn ará Ekroni fi igbe ta pé, “Wọ́n ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Israẹli tọ̀ wá wá láti pa wá àti àwọn ènìyàn wa.””
1 Samuel 5:10 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 10 of 12 in 1 Samuel chapter 5 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
1 Samuel 5 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ti gba àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ, wọ́n gbé e láti sí Aṣdodu. Nígbà tí àwọn gbé àpótí Ọlọ́run náà lọ sí tẹmpili , wọ́n gbé e kalẹ̀ sí ẹ̀bá . Nígbà tí àwọn ará Aṣdodu jí ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ní ọjọ́ kejì, Dagoni ṣubú, ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí Olúwa, wọ́n sì gbé , wọ́n tún fi sí ààyè rẹ̀. Ṣùgbọ́n ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì nígbà tí wọ́n dìde, Dagoni ṣì wá, ó ṣubú ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Orí àti ọwọ́ rẹ̀ sì ti gé kúrò, ó sì dùbúlẹ̀ ní orí ìloro ẹnu-ọ̀nà, ara rẹ̀ nìkan ni ó kù. Ìdí nìyìí títí di òní tí ó fi jẹ́ pé àlùfáà tàbí àwọn mìíràn tí ó wọ inú tẹmpili ní Aṣdodu fi ń tẹ orí ìloro ẹnu-ọ̀nà. Ọwọ́ Olúwa wúwo lára àwọn ènìyàn Aṣdodu àti gbogbo agbègbè rẹ̀: ó mú ìparun wá sórí wọn, ó sì pọ́n wọn lójú pẹ̀lú ààrùn íkókó. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Aṣdodu rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n wí pé, “Àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ti ẹli kò gbọdọ̀ dúró níbí yìí pẹ̀lú wa, nítorí ọwọ́ rẹ̀ wúwo lára wa àti lára ọlọ́run wá.” Nígbà náà ni wọ́n pè gbogbo àwọn olórí jọ wọ́n sì bi wọ́n pé, “Kí ni a ó ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn ẹli?” Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí á gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn ẹli lọ sí .” Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ẹli. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti gbé e, ọwọ́ Olúwa sì wá sí ìlú náà, ó mú jìnnìjìnnì bá wọn. Ó sì pọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà lójú, ọmọdé àti àgbà, pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn íkókó. Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ sí . Bí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ṣe wọ , àwọn ará fi igbe ta pé, “Wọ́n ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ẹli tọ̀ wá wá láti pa wá àti àwọn ènìyàn wa.” Nígbà náà ni wọ́n pe gbogbo àwọn olórí àwọn jọ wọ́n sì wí pé, “Ẹ gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn ẹli lọ: ẹ jẹ́ kí ó padà sí ààyè rẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò pa wá àti àwọn ènìyàn wa.” Ikú ti mú jìnnìjìnnì bá àwọn ará ìlú, ọwọ́ Ọlọ́run sì wúwo lára wọn. Àwọn tí kò kú wọ́n pọ́n wọn lójú pẹ̀lú ààrùn íkókó, ẹkún ìlú náà sì gòkè lọ sí ọ̀run.
Every verse in 1 Samuel 5
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.