1 Timothy
1 Timothy 6
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible · tap any highlighted word for context
1 Timothy 6 — Scripture text (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí i ṣe ẹrú lábẹ́ ìsìnrú máa ka àwọn olówó tí ó ni wọ́n yẹ sí ọlá gbogbo, kí a má bà á sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ rẹ̀. Àwọn ti ó ní ọ̀gá ígbàgbọ́, kí wọn má ṣe ṣàìbọ̀wọ̀ fún wọn nítorí tí wọn jẹ́ arákùnrin; ṣùgbọ́n kí wọn túbọ̀ máa sìn wọ́n, nítorí àwọn tí í ṣe alábápín iṣẹ́ rere wọn jẹ́ ígbàgbọ́ àti olùfẹ́. Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa kọ́ ni, kí o sì máa fi gbani níyànjú. Bí ẹnikẹ́ni bá ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ mìíràn, ti kò sì gba ọ̀rọ̀ ti ó yè kooro, ti Olúwa wa, àti ẹ̀kọ́ ti ó bá ìwà-bí-Ọlọ́run mu, Ó gbéraga, kò mọ̀ nǹkan kan, bí kò ṣe ìyànjú àti ìjà nípa ọ̀rọ̀ èyí tí ó ń mú ìlara, ìjà, ọ̀rọ̀ búburú wá, àti ọ̀rọ̀ àríyànjiyàn àwọn ènìyàn ọlọ́kàn èérí ti kò sí òtítọ́ nínú wọn, tiwọn ṣe bí ọ̀nà sí èrè ni ìwà-bí-Ọlọ́run; yẹra lọ́dọ̀ irú àwọn wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn èrè ńlá ni. Nítorí a kò mú ohun kan wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mu ohunkóhun jáde lọ. Bí a sì ni oúnjẹ àti aṣọ, ìwọ̀nyí yẹ́ kí ó tẹ́ wa lọ́rùn. Ṣùgbọ́n àwọn tí ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa bọ́ sínú ìdánwò àti ìdẹ̀kùn, àti sínú òmùgọ̀ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ púpọ̀ tí í pa ni lára, irú èyí tí ó máa ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé. Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo; èyí tí àwọn mìíràn ń lépa tí a sì mú wọn ṣìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì fi ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ gún ara wọn lọ́kọ̀. Ṣùgbọ́n ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, sá fún nǹkan wọ̀nyí; kí ó sì máa lépa òdodo, ìwà-bí-Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́ sùúrù, ìwà tútù. Máa ja ìjà rere ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú nínú èyí tí a pè ọ sí, ti ìwọ sì ṣe ìjẹ́wọ́ rere níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀. Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, tí ń sọ ohun gbogbo di ààyè, àti níwájú , ẹni tí ó jẹ́rìí níwájú Pọntiu , kí ìwọ pa àṣẹ wọ̀nyí mọ́ ní àìlábàwọ́n, ní àìlẹ́gàn, títí di ìfarahàn Olúwa wa . Èyí ti yóò fihàn ní ìgbà tirẹ̀, Ẹni tí í ṣe Olùbùkún àti Alágbára kan ṣoṣo náà, ọba àwọn ọba, àti Olúwa àwọn Olúwa. Ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ àìkú, tí ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí a kò lè súnmọ́, ẹni tí ènìyàn kan kò rí rí, tí a kò sì lè rí: ẹni tí ọlá àti agbára títí láé ń ṣe tirẹ̀. Àmín. Kìlọ̀ fún àwọn tí ó lọ́rọ̀ ní ayé ìsinsin yìí kí wọn ma ṣe gbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run alààyè, tí ń fi ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀lọ́pọ̀ láti lò; kí wọn máa ṣoore, kí wọn máa pọ̀ ní iṣẹ́ rere, kí wọn múra láti pín fún ni, kí wọn ni ẹ̀mí ìbá kẹ́dùn; kí wọn máa to ìṣúra ìpìlẹ̀ rere jọ fún ara wọn dé ìgbà tí ń bọ̀, kí wọn lè di ìyè tòótọ́ mú. Timotiu, máa ṣọ ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ, yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán àti ìjiyàn ohun tí a ń fi èké pè ni ìmọ̀; èyí tí àwọn ẹlòmíràn jẹ́wọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ṣìnà ìgbàgbọ́. Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú rẹ.
Every verse in 1 Timothy 6
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.