Deuteronomy

Deuteronomy 2

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible · tap any highlighted word for context

Deuteronomy 2 — Scripture text (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Nígbà náà ni a yípadà, tí a sì mú ọ̀nà wa pọ̀n lọ sí aginjù, a gba ọ̀nà Òkun , bí Olúwa ti darí mi. Ìgbà pípẹ́ ni a fi ń rìn kiri yíká agbègbè àwọn ìlú olókè . Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé, “Ẹ ti rìn yí agbègbè ilẹ̀ olókè yìí pẹ́ tó, nísinsin yìí, ẹ yípadà sí ìhà àríwá. Fún àwọn ènìyàn náà ní àwọn òfin wọ̀nyí: ‘Ẹ ti fẹ́ la ilẹ̀ àwọn arákùnrin yín kọjá, àwọn ọmọ ; àwọn ará tí ń gbé ní . Ẹ̀rù yín yóò bà wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ ṣọ́ra gidigidi. Ẹ má ṣe wá wọn níjà torí pé èmi kò ní fún un yín ní èyíkéyìí nínú ilẹ̀ wọn. Bí ó ti wù kí ó kéré mọ èmi kò ní fún un yín. Mo ti fi ilẹ̀ òkè fún gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀. Ẹ san owó oúnjẹ tí ẹ bá jẹ fún wọn àti omi tí ẹ bá mu.’ ” Olúwa Ọlọ́run yín ti bùkún un yín nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín. Ó ti mójútó ìrìnàjò yín nínú aginjù ńlá yìí. Olúwa Ọlọ́run yín wà pẹ̀lú u yín ní ogójì ọdún wọ̀nyí, dé bi pé ẹ̀yin kò ṣaláìní ohunkóhun. Bẹ́ẹ̀ ni a kọjá ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wa, àwọn ọmọ tí ń gbé ní . A yà kúrò ní ọ̀nà èyí tí ó wá láti àti -, a sì rìn gba ọ̀nà aginjù . Olúwa sì sọ fún mi pé, “Ẹ má ṣe dẹ́rùba àwọn ará bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe bá wọn jagun torí pé n kò ní fi èyíkéyìí nínú ilẹ̀ wọn fún un yín. Mo ti fi fún àwọn ọmọ Lọti bí i ìní.” (Àwọn ti gbé ibẹ̀ rí, àwọn ènìyàn tó síngbọnlẹ̀ tó sì pọ̀, wọ́n ga bí àwọn . Gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn náà pè wọ́n ní ará ṣùgbọ́n àwọn ará pè wọ́n ní . Àwọn ará gbé ní , kí àwọn ọmọ tó lé wọn kúrò níwájú wọn. Wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn, wọ́n tẹ̀dó sí ààyè wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ẹli tí ṣe ní ilẹ̀ tí Olúwa yóò fún wọn ní ìní wọn.) Olúwa sì wí pé, “Ẹ dìde, kí ẹ sì la àfonífojì kọjá.” Bẹ́ẹ̀ ni a la àfonífojì náà kọjá. Ó gbà wá ní ọdún méjìdínlógójì kí ó tó di wí pé a la àfonífojì kọjá láti ìgbà tí a ti kúrò ní ṣi-. Nígbà náà gbogbo ìran àwọn tí ó jẹ́ jagunjagun láàrín àwọn ènìyàn náà ti ṣègbé kúrò láàrín àwọn ènìyàn náà ní àsìkò yìí bí Olúwa ti búra fún wọn. Ọwọ́ Olúwa sì wà lòdì sí wọn nítòótọ́, láti run wọn kúrò nínú ibùdó, títí gbogbo wọn fi run tan. Lẹ́yìn tí ẹni tí ó gbẹ̀yìn pátápátá nínú àwọn jagunjagun àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti kú, Olúwa sọ fún mi pé, “Lónìí ni ẹ̀yin yóò la agbègbè kọjá ní . Bí ẹ bá dé ọ̀dọ̀ àwọn ará , ẹ má ṣe halẹ̀ mọ́ wọn, ẹ kò sì gbọdọ̀ bá wọn jagun, torí pé èmi kì yóò fi àwọn ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ará fún un yín ní ìní. Mo ti fi fún àwọn ọmọ Lọti ní ìní.” (A ka ilẹ̀ yìí sí ilẹ̀ àwọn , tí wọ́n ti gbé níbẹ̀ rí, ṣùgbọ́n àwọn ará ń pè wọ́n ní ará . Wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tó lágbára, wọ́n sì pọ̀, wọ́n sì ga gogoro bí àwọn ará . Olúwa run wọn kúrò níwájú àwọn ará , tí wọ́n lé wọn jáde tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn. Bákan náà ni Olúwa ṣe fún àwọn ọmọ , tí wọ́n ń gbé ní , nígbà tí ó pa àwọn ará run níwájú wọn. Wọ́n lé wọn jáde wọ́n sì ń gbé ní ilẹ̀ wọn títí di òní. Nípa ti àwọn ará , tí wọ́n ń gbé ní àwọn ìlú kéékèèké dé , àwọn ará , tí wọ́n jáde láti wá ni ó pa wọ́n run, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn.) “Ẹ gbáradì, kí ẹ sì kọjá odò . Kíyèsi, Mo ti fi ará , ọba Heṣboni àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Ẹ bá ilẹ̀ náà jagun kí ẹ sì gbà á. Èmi bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ìbẹ̀rù àti ìfòyà yín sára gbogbo orílẹ̀-èdè lábẹ́ ọ̀run láti òní lọ. Wọn yóò gbọ́ ìròyìn in yín, wọn yóò sì wárìrì, wọn yóò sì wà nínú ìdààmú ọkàn torí i tiyín.” Mo rán àwọn ìránṣẹ́ láti aginjù lọ́ sọ́dọ̀ ọba Heṣboni pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àlàáfíà wí pé, “Jẹ́ kí a la ilẹ̀ ẹ yín kọjá. Àwa yóò gba ti òpópónà nìkan. A kò ní yà sọ́tùn tàbí sósì. Ẹ ta oúnjẹ tí a ó jẹ àti omi tí a ó mu fún wa ní iye owó wọn. Kìkì kí ẹ sá à jẹ́ kí a rìn kọjá: gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí ó ń gbé ní àti àwọn ará tí ó ń gbé ní , ti gbà wá láààyè títí a fi la já dé ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò fún wa.” Ṣùgbọ́n ọba Heṣboni kò gbà fún wa láti kọjá. Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín ti mú ọkàn rẹ̀ yigbì, àyà rẹ̀ sì kún fún agídí kí ó ba à le fi lé e yín lọ́wọ́, bí ó ti ṣe báyìí. Olúwa sì bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kíyèsi i, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi àti ilẹ̀ rẹ̀ lé e yín lọ́wọ́. Báyìí, ẹ máa ṣẹ́gun rẹ̀, kí ẹ sì gba ilẹ̀ rẹ̀.” Nígbà tí àti gbogbo àwọn jagunjagun rẹ̀ jáde wá láti bá wa jagun ní , Olúwa Ọlọ́run wa fi lé wa lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ ni a ṣẹ́gun rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo ológun rẹ̀. Nígbà náà, gbogbo ìlú wọn ni a kó tí a sì pa wọ́n run pátápátá tọkùnrin, tobìnrin àti gbogbo ọmọ wọn. A kò sì dá ẹnikẹ́ni sí. Ṣùgbọ́n a kó gbogbo ohun ọ̀sìn àti ìkógun àwọn ìlú tí a ṣẹ́gun fún ara wa. Láti , létí odò àti láti àwọn ìlú tí ó wà lẹ́bàá odò náà títí ó fi dé , kò sí ìlú tí ó lágbára jù fún wa, Olúwa Ọlọ́run wa fi gbogbo wọn fún wa. Ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa Ọlọ́run wa, ẹ kò súnmọ́ ọ̀kan nínú ilẹ̀ àwọn ará , bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò dé ilẹ̀ tí ó lọ sí , tàbí ilẹ̀ tí ó yí àwọn ìlú òkè e nì ká.

Every verse in Deuteronomy 2

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00