Hosea

Hosea 6

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible · tap any highlighted word for context

Hosea 6 — Scripture text (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Olúwa ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ṣùgbọ́n yóò mú wa láradá Ó ti pa wá lára ṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa. Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jí ní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípò kí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a mọ Olúwa; ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú láti mọ̀ ọ́n. Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ, yóò jáde; yóò tọ̀ wá wá bí òjò, bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.” “Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Efraimu? Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Juda? Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀ bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá. Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì, Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ìdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín. Nítorí àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ; àti ìmọ̀ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ. Bí i , wọ́n da májẹ̀mú wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi níbẹ̀. Gileadi jẹ́ ìlú àwọn ènìyàn búburú tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, a sí ti fi ẹ̀ṣẹ̀ bà á jẹ́. Bí adigunjalè ṣe ń ba ní bùba de àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà, ń parapọ̀; tí wọ́n sì ń pànìyàn lójú ọ̀nà tó lọ sí Ṣekemu, tí wọ́n sì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ni lójú. Mo ti rí ohun tó ba ni lẹ́rù ní ilé ẹli. Níbẹ̀ , fi ara rẹ̀ fún àgbèrè ẹli sì di aláìmọ́. “Àti fún ìwọ, Juda, a ti yan ọjọ́ ìkórè rẹ. “Nígbà tí mo bá fẹ́ dá ohun ìní àwọn ènìyàn mi padà,

Every verse in Hosea 6

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00