Isaiah
Isaiah 21
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible · tap any highlighted word for context
Isaiah 21 — Scripture text (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan aginjù lẹ́bàá Òkun. Gẹ́gẹ́ bí ìjì líle ti í jà kọjá ní gúúsù, akógunjàlú kan wá láti aginjù, láti ilẹ̀ ìpayà. Ìran tí a ń fojú ṣọ́nà fún ni a ti fihàn mí ọlọ̀tẹ̀ ti tu àṣírí, fọ́lé fọ́lé ti kẹ́rù. Elamu kojú ìjà! ti tẹ̀gùn! Èmi yóò mú gbogbo ìpayínkeke dópin, ni ó búra. Pẹ̀lú èyí, ìrora mu mi lára gírígírí, ìrora gbá mi mú, gẹ́gẹ́ bí i ti obìnrin tí ń rọbí, mo ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nítorí ohun tí mo gbọ́, ọkàn mi pòruurù nípa ohun tí mo rí. Ọkàn mí dàrú, ẹ̀rù mú jìnnìjìnnì bá mi, ìmọ́lẹ̀ tí mo ti ń fẹ́ ẹ́ rí ti wá di ìpayà fún mi. Wọ́n tẹ́ tábìlì, wọ́n tẹ́ ẹní àtẹ́ẹ̀ká, wọ́n jẹ, wọ́n mu! Dìde nílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ-aládé, ẹ fi òróró kún asà yín! Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Lọ, kí o bojúwòde kí o sì wá sọ ohun tí ó rí. Nígbà tí ó bá rí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin, àwọn tó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí àwọn tí ó gun ìbákasẹ, jẹ́ kí ó múra sílẹ̀, àní ìmúra gidigidi.” Òun sì kígbe pé, kìnnìún kan, “Láti ọjọ́ dé ọjọ́, olúwa mi, mo dúró lórí ilé ìṣọ́ ní ọ̀sán, a sì fi mí ìṣọ́ mi ní gbogbo òru. Wò ó, ọkùnrin kan ni ó ń bọ̀ wá yìí nínú kẹ̀kẹ́ ogun àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin. Ó sì mú ìdáhùn padà wá: ‘Babeli ti ṣubú, ó ti ṣubú! Gbogbo àwọn ère òrìṣà rẹ̀ ló fọ́nká sórí ilẹ̀!’ ” Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí a gún mọ́lẹ̀ ní ilẹ̀ ìpakà, mo sọ ohun tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ẹli. Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan . Ẹnìkan ké sí mi láti wá, “Alóre, kí ló kù nínú òru náà?” Alóre náà dáhùn wí pé, “Òwúrọ̀ súnmọ́ tòsí, àti òru náà pẹ̀lú. Bí ìwọ yóò bá béèrè, béèrè; kí o sì tún padà wá.” Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan . Ẹ̀yin ẹgbẹ́ èrò ti , tí ó pàgọ́ sínú igbó , gbé omi wá fún àwọn tí òǹgbẹ ń gbẹ; ẹ̀yin tí ó ń gbé , gbé oúnjẹ wá fún àwọn ìsáǹsá. Wọ́n sá kúrò lọ́wọ́ idà, kúrò lọ́wọ́ idà tí a fàyọ, kúrò lọ́wọ́ ọrun tí a fàyọ àti kúrò nínú ìgbóná ogun. Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Láàrín ọdún kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ọgbà, í ti í kà á, gbogbo ògo ìlú yóò wá sí òpin. Àwọn tafàtafà tí ó sálà, àwọn jagunjagun ìlú kò ní tó nǹkan.” Olúwa, Ọlọ́run ẹli ni ó ti sọ̀rọ̀.
Every verse in Isaiah 21
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.