Isaiah

Isaiah 39

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible · tap any highlighted word for context

Isaiah 39 — Scripture text (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ní àkókò náà ni - ọmọ ọba fi ìwé àti ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí , nítorí ó gbọ́ pé ó ṣàìsàn ó sì gbádùn. Hesekiah gba àwọn ikọ̀ yìí tayọ̀tayọ̀, ó sì fi àwọn nǹkan tí ó wà nínú yàrá ìkẹ́rù sí mọ́ hàn wọ́n—fàdákà, wúrà, ohun olóòórùn dídùn, òróró dídára, gbogbo nǹkan ogun rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìṣúra rẹ̀ kò sí ohunkóhun tí ó wà nínú ààfin rẹ̀ tàbí ní ìjọba rẹ̀ tí kò fihàn wọ́n. Lẹ́yìn náà wòlíì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba ó sì béèrè pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí, níbo ni wọ́n sì ti wá?” “Láti ilẹ̀ jíjìnnà,” ni èsì . “Wọ́n wá sọ́dọ̀ mi láti .” Wòlíì náà sì béèrè pé, “Kí ni wọ́n rí nínú ààfin rẹ?” si dáhùn pe, “Wọ́n rí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin mi. Kò sí ohun kankan nínú ìṣúra mi tí èmi kò fihàn wọ́n.” Lẹ́yìn náà ni sọ fún pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Àsìkò ń bọ̀ nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin rẹ, àti ohun gbogbo tí àwọn baba rẹ ti kójọ títí di ọjọ́ òní yóò di kíkó lọ sí . Ohun kankan kò ní ṣẹ́kù ni Olúwa wí. Àti díẹ̀ nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ, àwọn ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara rẹ tí a ó bí fún ọ ni a ó kó lọ, wọn yóò sì di ìwẹ̀fà nínú ààfin ọba .” Hesekiah wí fún pé, “Rere ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ìwọ sọ.” Nítorí ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Àlàáfíà àti ààbò yóò wà ní ìgbà ayé tèmi.”

Every verse in Isaiah 39

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00