Jeremiah 28:6
“Jeremiah wòlíì wí pé, “Àmín! Kí Olúwa kí ó ṣe bẹ́ẹ̀! Kí Olúwa kí ó mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ìwọ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ, láti mú ohun èlò ilé Olúwa àti gbogbo àwọn ìgbèkùn láti ilẹ̀ Babeli padà wá sí ibí yìí.”
Jeremiah 28:6 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 6 of 17 in Jeremiah chapter 28 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Jeremiah 28 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Ní oṣù karùn-ún ní ọdún kan náà, ọdún kẹrin ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba ọba , wòlíì ọmọ , tí ó wá láti , sọ fún mi ní ilé Olúwa tí ó wà ní iwájú àwọn àlùfáà àti gbogbo ènìyàn: “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run ẹli wí: ‘Èmi yóò mú àjàgà ọba rọrùn. Láàrín ọdún méjì, Èmi yóò mú gbogbo ohun èlò tí ọba ; ọba kó kúrò ní ilé Olúwa tí ó sì kó lọ sí padà wá. Èmi á tún mú ààyè ọmọ ọba padà, àti gbogbo àwọn tí ń ṣe àtìpó láti ní ,’ èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa pé, ‘àjàgà yín láti ọwọ́ ọba yóò rọrùn.’ ” Wòlíì wí fún wòlíì ní iwájú ọmọ àlùfáà àti àwọn ènìyàn tí wọ́n dúró ní ilé Olúwa. wòlíì wí pé, “Àmín! Kí Olúwa kí ó ṣe bẹ́ẹ̀! Kí Olúwa kí ó mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ìwọ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ, láti mú ohun èlò ilé Olúwa àti gbogbo àwọn ìgbèkùn láti ilẹ̀ padà wá sí ibí yìí. Nísinsin yìí, ìwọ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí tí mo sọ sí etí rẹ àti sí etí gbogbo ènìyàn. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn wòlíì tí ó ṣáájú rẹ àti èmi ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ogun, ibi àti àjàkálẹ̀ sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Ṣùgbọ́n, àwọn wòlíì tí ó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àlàáfíà ni a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì olóòtítọ́ tí Olúwa rán, tí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ bá wá sí ìmúṣẹ.” Wòlíì gbé àjàgà ọrùn wòlíì kúrò, ó sì fọ́ ọ. Hananiah sọ níwájú gbogbo ènìyàn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Bákan náà ni Èmi yóò fọ́ àjàgà ọrùn , ọba láàrín ọdún méjì.’ ” Wòlíì sì bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ. Láìpẹ́ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì wá lẹ́yìn ìgbà tí wòlíì ti gbé àjàgà kúrò ní ọrùn wòlíì wí pé: “Lọ sọ fún , ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí, ìwọ ti wó àjàgà ígi, ṣùgbọ́n ní ààyè wọn, wà á bá àjàgà írin. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run ẹli wí: Èmi yóò fi àjàgà írin sí ọrùn gbogbo orílẹ̀-èdè láti lè máa sin ọba , àti pé gbogbo yín ni ẹ̀ ó máa sìn ín. Èmi yóò tún fún un ní àṣẹ lórí àwọn ẹranko búburú.’ ” Wòlíì sọ fún wòlíì pé, “Gbọ́ ọ, Hananiah! Olúwa kò rán ọ, síbẹ̀, ìwọ jẹ́ kí orílẹ̀-èdè yìí gba irọ́ gbọ́. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Mo ṣetán láti mú ọ kúrò nínú ayé, ní ọdún yìí ni ìwọ yóò kú nítorí o ti wàásù ọ̀tẹ̀ sí Olúwa.’ ” Ní oṣù keje ọdún yìí ni wòlíì kú.
Every verse in Jeremiah 28
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.