Jeremiah

Jeremiah 32

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible · tap any highlighted word for context

Jeremiah 32 — Scripture text (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Èyí ni ọ̀rọ̀ tó tọ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa ní ọdún kẹwàá ọba , èyí tí ó jẹ́ ọdún kejìdínlógún ti . Àwọn ogun ọba ìgbà náà há ẹmu mọ́. A sì sé wòlíì mọ́ inú túbú tí wọ́n ń ṣọ́ ní àgbàlá ilé ọba . Nítorí ọba ti há a mọ́lé síbẹ̀; pé, “Kí ló dé tí ìwọ fi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀? Tí o sì wí pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Èmi ń bọ̀ wá fi ìlú yìí fún ọba , tí yóò sì gbà á. Sedekiah ọba kò lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn , ṣùgbọ́n à ó mú fún ọba , yóò sì bá sọ̀rọ̀ ní ojúkojú; yóò sì rí pẹ̀lú ojú rẹ̀. Yóò mú lọ sí tí yóò wà títí èmi yóò fi bẹ̀ ọ́ wò ni Olúwa wí. Tí ẹ̀yin bá bá àwọn ará jà, ẹ̀yin kì yóò borí wọn.’ ” wí pé, “Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: Hanameli ọmọkùnrin Ṣallumu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yóò tọ̀ ọ́ wá pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní ; nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹni tó súnmọ́ wọn, ẹ̀tọ́ àti ìṣe rẹ ní láti rà á.’ “Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ, Hanameli ọmọ ẹ̀gbọ́n mi tọ̀ mí wá ní àgbàlá túbú wí pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní tí ó wà ní ilẹ̀ , èyí tí ó jẹ́ pé ẹ̀tọ́ rẹ ni láti gbà á àti láti ni, rà á fún ara rẹ.’ “Nígbà náà ni èmi mọ̀ wí pé ọ̀rọ̀ Olúwa ni èyí. Bẹ́ẹ̀ ni; èmi ra pápá náà ní láti ọwọ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n mi. Mo sì wọn ìwọ̀n ṣékélì àti fàdákà mẹ́tàdínlógún fún un. Mo fọwọ́ sínú ìwé, mo sì dì í pa. Mo pe ẹlẹ́rìí sí i, mo sì wọn fàdákà náà lórí òsùwọ̀n. Mo mú ìwé tí mo fi rà á, èyí tí a di pa nípa àṣẹ àti òfin wa, àti èyí tí a kò lẹ̀. Èmi sì fi èyí fún , ọmọ , ọmọ , ní ojú , ọmọ ẹ̀gbọ́n mi àti níwájú àwọn ẹlẹ́rìí tí ó ti fi ọwọ́ sí ìwé àti ní ojú àwọn Júù gbogbo tí wọ́n jókòó ní àgbàlá ilé túbú. “Ní ojú wọn ni èmi ti pàṣẹ fún pé, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run ẹli wí; mú àwọn ìwé tí a fi rà á wọ̀nyí, àti èyí tí a lẹ̀ àti èyí tí a kò lẹ̀, kí o wá gbé wọn sínú ìkòkò amọ̀, kí wọn ó lè wà ní ọjọ́ púpọ̀. Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run ẹli wí; àwọn ilẹ̀, pápá àti ọgbà àjàrà ni à ó tún rà padà nílẹ̀ yìí. “Lẹ́yìn tí mo ti fi ìwé rírà náà fún ọmọkùnrin , mo gbàdúrà sí Olúwa wí pé: “Háà! Olúwa Olódùmarè, ìwọ tí o dá ọ̀run àti ayé pẹ̀lú títóbi agbára rẹ àti gbogbo ọ̀rọ̀ apá rẹ. Kò sí ohun tí ó ṣòro fún ọ láti ṣe. O fi ìfẹ́ hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n o gbé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba lé àwọn ọmọ lẹ́yìn wọn. Ọlọ́run títóbi àti alágbára, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ. Títóbi ni ìgbìmọ̀, àti alágbára ní í ṣe, ojú rẹ̀ ṣì sí gbogbo ọ̀nà àwọn ọmọ ènìyàn; láti fi fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ ọ̀nà rẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí èso iṣẹ́ rẹ̀. O ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá ní . O sì ń ṣe é títí di òní ní ẹli àti lára ọmọ ènìyàn tí ó sì ti gba òkìkí tí ó jẹ́ tìrẹ. O kó àwọn ẹli ènìyàn rẹ jáde láti pẹ̀lú iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu nínú ọwọ́ agbára àti nína apá rẹ pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá. Ìwọ fún wọn nílẹ̀ yìí, èyí tí o ti ṣèlérí fún àwọn baba ńlá wọn; ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin. Wọ́n wá, wọ́n sì gba ilẹ̀ náà ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ tàbí tẹ̀lé òfin rẹ. Wọn kò ṣe ohun tí o pàṣẹ fún wọn, nítorí náà ìwọ mú àwọn ibi yìí wá sórí wọn. “Wò ó, bí àwọn ìdọ̀tí ṣe kórajọ láti gba ìlú. Nítorí idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, sì fi ìlú lé ọwọ́ àwọn ará tí ń gbóguntì wọ́n. Ohun tí ìwọ sọ ṣẹ gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i. Síbẹ̀ a ó fi ìlú náà fún àwọn ará , ìwọ Olúwa Olódùmarè sọ fún mi pé, ‘Ra pápá náà pẹ̀lú owó fàdákà, kí o sì pe ẹlẹ́rìí.’ ” Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wá pé: “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run gbogbo ẹran-ara. Ǹjẹ́ ohun kan ha a ṣòro fún mi bí? Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí, Èmi ṣetán láti fi ìlú yìí fún àwọn ará àti fún ọba ẹni tí yóò kó o. Àwọn ará tí ó ń gbógun tí ìlú yóò wọ ìlú. Wọn ó sì fi iná sí ìlú; wọn ó jó o palẹ̀ pẹ̀lú ilé tí àwọn ènìyàn ti ń mú mi bínú, tí wọ́n ń rú ẹbọ tùràrí lórí pẹpẹ fún tiwọn sì ń da ẹbọ ohun mímu fún àwọn ọlọ́run mìíràn. “Àwọn ènìyàn ẹli àti kò ṣe ohun kankan bí kò ṣe ibi lójú mi láti ìgbà èwe wọn. Nítorí àwọn ọmọ ẹli ti fi kìkì iṣẹ́ ọwọ́ wọ́n mú mi bínú ni Olúwa wí. Láti ọjọ́ tí wọ́n ti kọ́ ọ, títí di àkókò yìí ni ìlú yìí ti jẹ́ ohun ìbínú àti ìyọnu fún mi tó bẹ́ẹ̀ tí èmi yóò fà á tu kúrò níwájú mi. Àwọn ènìyàn ẹli àti àwọn ènìyàn ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ìbàjẹ́ tí wọ́n ṣe. Àwọn ẹli, ọba wọn àti gbogbo ìjòyè, àlùfáà àti wòlíì, àwọn ọkùnrin àti àwọn ènìyàn ẹmu. Wọ́n kọ ẹ̀yìn sí mi, wọ́n sì yí ojú wọn padà. Èmi kọ wọ́n, síbẹ̀ wọn kò fetísílẹ̀ láti gbọ́ ẹ̀kọ́ tàbí kọbi ara sí ìwà ìbàjẹ́. Wọ́n kó òrìṣà ìríra wọn jọ sí inú ilé tí wọ́n fi orúkọ mi pè, wọ́n sì ṣọ́ di àìmọ́. Wọ́n kọ́ ibi gíga fún ní àfonífojì láti fi ọmọ wọn ọkùnrin àti obìnrin rú ẹbọ sí . Èmi kò pàṣẹ, fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò wá sí ọkàn mi pé kí wọ́n ṣe ohun ìríra wọ̀nyí tí ó sì mú dẹ́ṣẹ̀. “Ìwọ ń sọ̀rọ̀ nípa ti ìlú yìí pé, ‘Pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn ni à ó fi wọ́n fún ọba ,’ ṣùgbọ́n ohun tí Olúwa Ọlọ́run ẹli sọ nìyìí, Èmi ó kó wọn jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo ti lé wọn kúrò ní ìgbà ìbínú àti ìkáàánú ńlá mi. Èmi yóò mú wọn padà wá sí ilẹ̀ yìí; èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó máa gbé láìléwu. Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn. Èmi ó fún wọn ní ọkàn kan àti ìṣe kí wọn kí ó lè máa bẹ̀rù mi fún rere wọn àti fún rere àwọn ọmọ wọn tí ó tẹ̀lé wọn. Èmi ò bá wọn dá májẹ̀mú ayérayé, èmi kò ní dúró láti ṣe rere fún wọn, Èmi ó sì jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rù mi, wọn kì yóò sì padà lẹ́yìn mi. Lóòtítọ́, èmi ó yọ̀ nípa ṣíṣe wọ́n ní rere, èmi ó sì fi dá wọn lójú nípa gbígbìn wọ́n sí ilẹ̀ yìí tọkàntọkàn mi. “Nítorí báyìí ni Olúwa wí, gẹ́gẹ́ bí èmi ti mú gbogbo ibi ńlá yìí wá sórí àwọn ènìyàn yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó mú gbogbo rere tí èmi ti sọ nípa tiwọn wá sórí wọn. Lẹ́ẹ̀kan sí i, pápá yóò di rírà ní ilẹ̀ yìí tí ìwọ ti sọ pé, ‘Ohun òfò ni tí kò bá sí ọkùnrin tàbí àwọn ẹran, nítorí tí a ti fi fún àwọn ará .’ Wọn ó fi owó fàdákà ra oko, wọn yóò fi ọwọ́ sí ìwé, wọn ó dí pa pẹ̀lú ẹlẹ́rìí láti ilẹ̀ àti ní ìlú kéékèèké tí ó yí ẹmu ká, àti ní ìlú àti ní ìlú àwọn ìlú orí òkè, àti ni àwọn ẹsẹ̀ òkè, àti ní gúúsù, èmi ó mú ìgbèkùn wọn padà wá, ni Olúwa wí.”

Every verse in Jeremiah 32

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00