Job 23:12

“Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò padà sẹ́yìn kúrò nínú òfin ẹnu rẹ̀, èmi sì pa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ mọ́ ju oúnjẹ òòjọ́ lọ.”

Job 23:12 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 12 of 17 in Job chapter 23 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Job 23 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ìgbà náà ni sì dáhùn wí pé, “Àní lónìí ni ọ̀ràn mi korò; ọwọ́ mí sì wúwo sí ìkérora mi. Háà! èmi ìbá mọ ibi tí èmí ìbá wá Ọlọ́run rí, kí èmí kí ó tọ̀ ọ́ lọ sí ibùgbé rẹ̀! Èmi ìbá sì to ọ̀ràn náà níwájú rẹ̀, ẹnu mi ìbá sì kún fún àròyé. Èmi ìbá sì mọ ọ̀rọ̀ tí òun ìbá fi dá mi lóhùn; òye ohun tí ìbáwí a sì yé mi. Yóò ha fi agbára ńlá bá mi wíjọ́ bí? Àgbẹdọ̀, kìkì pé òun yóò sì kíyèsi mi. Níbẹ̀ ni olódodo le è bá a wíjọ́, níwájú rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì bọ́ ni ọwọ́ ídàájọ́ mi láéláé. “Sì wò ó, bí èmi bá lọ sí iwájú, òun kò sí níbẹ̀, àti sí ẹ̀yìn, èmi kò sì rí òye rẹ̀. Ni apá òsì bí ó bá ṣiṣẹ́ níbẹ̀, èmi kò rí i, ó fi ara rẹ̀ pamọ́ ni apá ọ̀tún, tí èmi kò le è rí i. Ṣùgbọ́n òun mọ ọ̀nà tí èmi ń tọ̀, nígbà tí ó bá dán mí wò, èmi yóò jáde bí wúrà. Ẹsẹ̀ mí ti tẹ̀lé ipasẹ̀ ìrìn rẹ̀; ọ̀nà rẹ̀ ni mo ti kíyèsi, tí ń kò sì yà kúrò. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò padà sẹ́yìn kúrò nínú òfin ẹnu rẹ̀, èmi sì pa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ mọ́ ju oúnjẹ òòjọ́ lọ. “Ṣùgbọ́n ínú kan ni òun, ta ni yóò sì yí i padà? Èyí tí ọkàn rẹ̀ sì ti fẹ́, èyí náà ní í ṣe. Nítòótọ́ ohun tí a ti yàn fún mi ní í ṣe; ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú ohun bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀. Nítorí náà ni ara kò ṣe rọ̀ mí níwájú rẹ̀; nígbà tí mo bá rò ó, ẹ̀rù a bà mi. Nítorí pé Ọlọ́run ti pá mi ní àyà, Olódùmarè sì ń dààmú mi. Nítorí tí a kò tí ì ké mi kúrò níwájú òkùnkùn, bẹ́ẹ̀ ni kò pa òkùnkùn biribiri mọ́ kúrò níwájú mi.

Every verse in Job 23

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00