Job
Job 25
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible · tap any highlighted word for context
Job 25 — Scripture text (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Nígbà náà ní , ará Ṣuhi, dáhùn wí pé, “Ìjọba àti ẹ̀rù ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀, òun ní i ṣe ìlàjà ní ibi gíga gíga ọ̀run. Àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ní ìyè bí, tàbí ara ta ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kò tàn sí? Èéha ti ṣe tí a ó fi dá ènìyàn láre lọ́dọ̀ Ọlọ́run? Tàbí ẹni tí a bí láti inú obìnrin wá yóò ha ṣe mọ́? Kíyèsi i, òṣùpá kò sì lè tàn ìmọ́lẹ̀, àní àwọn ìràwọ̀ kò mọ́lẹ̀ ní ojú rẹ̀, kí a má sọ ènìyàn tí i ṣe ìdin, àti ọmọ ènìyàn tí í ṣe kòkòrò!”
Every verse in Job 25
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.