Joshua 5:11
“Ní ọjọ́ kejì àjọ ìrékọjá, ní ọjọ́ náà gan an ni, wọ́n jẹ nínú àwọn ìre oko ilẹ̀ náà: àkàrà aláìwú, àti ọkà yíyan.”
Joshua 5:11 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 11 of 15 in Joshua chapter 5 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Joshua 5 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Nígbà tí gbogbo àwọn ọba ti ìlà-oòrùn àti gbogbo àwọn ọba tí ń bẹ létí òkun gbọ́ bí Olúwa ti mú gbẹ ní iwájú àwọn ọmọ ẹli títí ti a fi kọjá, ọkàn wọn pami, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ìgboyà mọ́ láti dojúkọ àwọn ọmọ ẹli. Nígbà náà ni Olúwa wí fún Joṣua pé, “Fi akọ òkúta ṣe abẹ kí o sì kọ àwọn ọmọ ẹli ní ilà ní ìgbà ẹ̀ẹ̀kejì.” Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua sì ṣe abẹ akọ òkúta, ó sì kọ àwọn ọmọ ẹli ní ilà, ní -. Wàyí o, ìdí tí Joṣua fi kọ wọ́n nílà nìyìí. Gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó ti jáde wá, gbogbo àwọn ọkùnrin ogun kú ní aginjù ní ọ̀nà lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ . Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, gbogbo àwọn ọkùnrin tó jáde láti ni a ti kọ ní ilà, síbẹ̀ gbogbo ènìyàn tí a bí nínú aginjù lẹ́yìn tí wọ́n jáde ní ni wọn kò kọ ní ilà. Àwọn ará ẹli rìn ní aginjù fún ogójì ọdún títí gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó tó ogun n jà nígbà tí wọ́n kúrò ni fi kú, nítorí wọn kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa. Nítorí Olúwa ti búra fún wọn pé wọn kò ní rí ilẹ̀ tí òun ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn láti fi fun wa, ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti fún oyin. Bẹ́ẹ̀ ni ó gbé àwọn ọmọ wọn dìde dípò wọn, àwọn wọ̀nyí sì ni Joṣua kọ ní ilà. Wọ́n wà ní aláìkọlà nítorí a kò tí ì kọ wọ́n ní ilà ní ojú ọ̀nà. Lẹ́yìn ìgbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè náà kọ ilà tan, wọ́n dúró ní ibi tí wọ́n wà ní ibùdó títí ilà wọn fi jinná. Nígbà náà ní Olúwa wí fún Joṣua pé, “Ní òní ni mo yí ẹ̀gàn kúrò ní orí yín.” Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ ibẹ̀ ní títí ó fi di òní yìí. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù náà, nígbà tí wọ́n pàgọ́ ní ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ , àwọn ọmọ ẹli sì ṣe ọdún àjọ ìrékọjá. Ní ọjọ́ kejì àjọ ìrékọjá, ní ọjọ́ náà gan an ni, wọ́n jẹ nínú àwọn ìre oko ilẹ̀ náà: àkàrà aláìwú, àti ọkà yíyan. náà sì tan ní ọjọ́ kejì tí wọ́n jẹ oúnjẹ tí ilẹ̀ náà mú jáde, kò sì sí kankan mọ́ fún àwọn ará ẹli, ṣùgbọ́n ní ọdún náà wọ́n jẹ ìre oko ilẹ̀ . Nígbà tí Joṣua súnmọ́ , ó wo òkè ó sì rí ọkùnrin kan tí ó dúró ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú idà ní ọwọ́ rẹ̀. Joṣua sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bi í pé, “Ǹjẹ́ ìwọ wà fún wa tàbí fún ọ̀tá a wa?” “Kì í ṣe fún èyíkéyìí ó fèsì, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí olórí ogun Olúwa ni mo wá nísinsin yìí.” Nígbà náà ni Joṣua sì wólẹ̀ ní iwájú u rẹ̀ ní ìbẹ̀rù, ó sì bi í léèrè, “Kí ni Olúwa ní í sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀?” Olórí ogun Olúwa sì dá a lóhùn pé, “Bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí pé ibi tí ìwọ dúró sí yìí, ilẹ̀ mímọ́ ni.” Joṣua sì ṣe bẹ́ẹ̀.
Every verse in Joshua 5
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.