Judges 18:24

“Ó dáhùn pé, “Ẹ̀yin kó àwọn ère tí mo ṣe, àti àlùfáà mi lọ. Kí ni ó kù tí mo ní? Báwo ni ẹ̀yin ò ṣe béèrè pé, ‘Kí ló ṣe ọ́?’ ””

Judges 18:24 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 24 of 31 in Judges chapter 18 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Judges 18 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àwọn ọmọ ẹli kò ní ọba. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àwọn ẹ̀yà ń wá ilẹ̀ tiwọn, níbi tí wọn yóò máa gbé, nítorí pé títí di àkókò náà wọn kò ì tí ì pín ogún ilẹ̀ fún wọn ní ìní láàrín àwọn ọmọ ẹli. Nítorí náà àwọn ẹ̀yà rán àwọn jagunjagun márùn-ún lọ láti àti Eṣtaoli láti yọ́ ilẹ̀ náà wò àti láti rìn ín wò. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe ojú fún gbogbo àwọn ẹ̀yà wọn. Wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ lọ kí ẹ rin ilẹ̀ náà ká, kí ẹ sì wò ó fínní fínní.” Àwọn ọkùnrin náà wọ àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè òkè , wọ́n sì dé ilé , níbi tí wọ́n sùn ní òru náà. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ tòsí ilé e , wọ́n dá ohùn ọ̀dọ́mọkùnrin náà mọ̀, torí náà wọ́n yípadà, wọ́n sì wọ inú ilé náà lọ wọ́n sì bi í pé, “Tá ni ó mú ọ wa sí ibi? Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín yìí? Èéṣe tí o fi wà ní ibí?” Ó sọ ohun tí ti ṣe fún un, ó fi kún un fún wọn pé, “Ó gbà mí sí iṣẹ́, èmi sì ni àlùfáà rẹ̀.” Wọ́n wí fún un pé, “Jọ̀wọ́ béèrè ní ọwọ́ Ọlọ́run, kí àwa lè mọ̀ bí ìrìnàjò wa yóò yọrí sí rere.” Àlùfáà náà dá wọn lóhùn pé, “Ẹ máa lọ ní àlàáfíà. Ìrìnàjò yín tí ẹ̀yin ń rìn bá ojúrere Olúwa pàdé.” Àwọn ọkùnrin márààrún náà kúrò, wọ́n sì wá sí ṣi, níbi tí wọ́n ti rí i pé àwọn ènìyàn tí ń gbé ibẹ̀ ní ààbò, bí àwọn ará , láìsí ìfòyà àti ní ìpamọ́. Ní ìgbà tí ilẹ̀ wọn kò ṣe aláìní ohunkóhun, wọ́n ní ọrọ̀ púpọ̀. Ibùgbé wọn tún jìnnà sí ti àwọn ará , wọn kò fi ohunkóhun bá ẹnikẹ́ni dàpọ̀. Nígbà tí wọ́n padà sí àti Eṣtaoli, àwọn arákùnrin wọn bi wọ́n léèrè pé, “Báwo ni ibi tí ẹ lọ ti rí? Kí ni ìròyìn tí ẹ mú wá?” Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ dìde ẹ jẹ́ kí a lọ kọlù wọ́n! A wá rí i pé ilẹ̀ náà dára gidigidi. Ṣé ẹ̀yin ó sì jókòó láìsí nǹkan nípa rẹ̀? Ẹ má ṣe lọ́ra láti lọ síbẹ̀ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà. Nígbà tí ẹ̀yin bá dé ibẹ̀, ẹ yóò rí àwọn ènìyàn tí ọkàn wọn balẹ̀ àti ilẹ̀ tí ó tẹ́jú tí Ọlọ́run ti fi fún yín, ilẹ̀ tí kò ṣe aláìní nǹkan kan.” Nígbà náà ni ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin tí ó múra ogun láti ìran , jáde lọ láti àti Eṣtaoli ní mímú ra láti jagun. Wọ́n sì jáde lọ, ní ojú ọ̀nà wọn, wọ́n tẹ̀dó ogun sí ẹ̀bá - ní . Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń gbé ìwọ̀-oòrùn - ni - títí di òní yìí. Láti ibẹ̀ wọ́n kọjá lọ sí àwọn ìlú agbègbè òkè , wọ́n sì dé ilé . Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin márùn-ún tí ó lọ yọ́ ilẹ̀ ṣi wò sọ fún àwọn arákùnrin wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ̀ pé ọ̀kan nínú àwọn ilé yìí ní ẹ̀wù efodu, àwọn yòókù ní òrìṣà, ère gbígbẹ́ àti ère dídà? Ẹ mọ ohun tí ó yẹ kí ẹ ṣe báyìí.” Wọ́n sì yà sí ibẹ̀, wọ́n sì wọ ilé ọ̀dọ́mọkùnrin náà, sí ilé , wọ́n sì béèrè àlàáfíà rẹ̀. Àwọn ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin ará náà tí ó hámọ́ra ogun, dúró ní àbáwọlé ẹnu odi. Àwọn ọkùnrin márùn-ún tí wọ́n lọ yọ́ ilẹ̀ náà wò wọlé lọ wọ́n sì kó ère gbígbẹ́ náà, efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé àti ère dídà náà nígbà tí àlùfáà náà àti àwọn ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin tí ó hámọ́ra ogun dúró ní à bá wọ ẹnu odi náà. Nígbà tí àwọn ọkùnrin yìí wọ ilé e lọ tí wọ́n sì kó ère fínfín náà, efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé mìíràn àti ère dídà náà, àlùfáà náà béèrè lọ́wọ́ wọn wí pé, “Kí ni ẹ̀yin ń ṣe?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Dákẹ́! Ma sọ nǹkan kan, tẹ̀lé wa kí o sì di baba àti àlùfáà wa. Kò ha sàn fún ọ láti máa ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀yà àti ìdílé kan tí ó wá láti ẹli bí àlùfáà ju ilé ẹnìkan ṣoṣo lọ?” Nígbà náà ni inú àlùfáà náà sì dùn, òun mú efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé mìíràn àti ère fínfín náà, ó sì bá àwọn ènìyàn náà lọ. Wọ́n kó àwọn ọmọdé wọn, àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní wọn síwájú, wọ́n yípadà wọ́n sì lọ. Nígbà tí wọ́n ti rìn jìnnà díẹ̀ sí ilé , àwọn ọkùnrin tí ó wà ní agbègbè kó ara wọn jọ, wọ́n sì lé àwọn ará bá. Bí wọ́n ṣe ń pariwo tẹ̀lé wọn lẹ́yìn, àwọn ará yípadà wọ́n sì bi pé, “Kí ló ṣe ọ́ tí o fi pe àwọn ọkùnrin rẹ jáde láti jà?” Ó dáhùn pé, “Ẹ̀yin kó àwọn ère tí mo ṣe, àti àlùfáà mi lọ. Kí ni ó kù tí mo ní? Báwo ni ẹ̀yin ò ṣe béèrè pé, ‘Kí ló ṣe ọ́?’ ” Àwọn ọkùnrin náà dáhùn pé, “Má ṣe bá wa jiyàn, tàbí àwọn íbìínú fùfù ènìyàn lè kọlù yín, ìwọ àti àwọn ìdílé yóò sì sọ ẹ̀mí yín nù.” Àwọn ọkùnrin náà sì bá ọ̀nà wọn lọ. Nígbà tí rí í pé wọ́n lágbára púpọ̀ fún òun, ó sì padà sí ilé rẹ̀. Wọ́n sì kó àwọn ohun tí ti ṣe àti àlùfáà rẹ̀, wọ́n sì kọjá lọ sí ṣi, ní ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó ní ìbàlẹ̀ ọkàn tí wọ́n sì wà ní àlàáfíà. Wọ́n fi ojú idà kọlù wọ́n, wọ́n sì jó ìlú wọn run. Kò sì sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀ nítorí pé ibi tí wọ́n ń gbé jìnà sí àwọn ará , wọn kò sì ní àṣepọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni. Ìlú náà wà ní inú àfonífojì lẹ́bàá a -. Àwọn ará sì tún ìlú náà kọ́, wọ́n sì ń gbé inú rẹ̀. Wọ́n sọ orúkọ ìlú náà ní gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba ńlá wọn , ẹni tí wọ́n bí fún ẹli: bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣi ni orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí. Àwọn ọmọ sì gbé àwọn ère kalẹ̀ fún ara wọn níbẹ̀; Jonatani ọmọ ṣomu, ọmọ , àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni àlùfáà fún àwọn ẹ̀yà títí di àkókò tí a kó ilẹ̀ náà ní ìgbèkùn. Wọ́n tẹ̀síwájú láti lo àwọn ère tí ṣe, ní gbogbo àkókò tí ilé Ọlọ́run wà ní Ṣilo.

Every verse in Judges 18

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00