Judges 20:10

“A yóò mú ọkùnrin mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli àti ọgọ́rùn-ún láti inú ẹgbẹ̀rún (1,000) kan àti ẹgbẹ̀rún kan láti inú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) láti máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ-ogun. Yóò sì ṣe nígbà tí àwọn jagunjagun bá dé Gibeah ti àwọn ará Benjamini, wọn yóò fún wọn ní ohun tí ó bá tọ́ sí wọn fún gbogbo ìwà búburú àti ìwà ìtìjú tí wọ́n ṣe yìí ní ilẹ̀ Israẹli.””

Judges 20:10 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 10 of 48 in Judges chapter 20 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Judges 20 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Gbogbo àwọn ọmọ ẹli láti dé ṣeba, àti láti ilẹ̀ jáde bí ẹnìkan ṣoṣo wọ́n sì péjọ síwájú Olúwa ni . Àwọn olórí gbogbo àwọn ènìyàn láti gbogbo ẹ̀yà ẹli dúró ní ipò wọn ní àpéjọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ogún ọ̀kẹ́ (400,000) ọkùnrin ológun ti àwọn àti idà wọn. (Àwọn ẹ̀yà gbọ́ wí pé àwọn ọmọ ẹli yòókù ti gòkè lọ sí .) Nígbà náà ni àwọn ọmọ ẹli wí pé, “Ẹ sọ fún wa báwo ni iṣẹ́ búburú ṣe ṣẹlẹ̀.” Ará náà, ọkọ obìnrin tí wọ́n pa fèsì pé, “Èmi àti àlè mi wá sí ti àwọn ará láti sùn di ilẹ̀ mọ́ níbẹ̀. Ṣùgbọ́n ní òru àwọn ọkùnrin lépa mi wọ́n sì yí ilé náà po pẹ̀lú èrò láti pa mí. Wọ́n fi ipá bá àlè mi lòpọ̀, òun sì kú. Mo mú àlè mi náà, mo sì gé e sí ekìrí ekìrí, mo sì fi ekìrí kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí agbègbè ìní ẹli kọ̀ọ̀kan, nítorí pé wọ́n ti ṣe ohun tí ó jẹ́ èèwọ̀ àti ohun ìtìjú yìí ní ilẹ̀ ẹli. Nísinsin yìí, gbogbo ẹ̀yin ọmọ ẹli, ẹ sọ ìmọ̀ràn yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ yín.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì dìde bí ẹnìkan pẹ̀lú gbólóhùn kan wí pé, “Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tí yóò lọ sí àgọ́ rẹ̀. Rárá o, kò sí ẹyọ ẹnìkan tí yóò padà lọ sí ilé rẹ̀. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ohun tí àwa yóò ṣe sí ní yìí. Àwa yóò lọ kọlù ú bí ìbò bá ṣe darí wa. A yóò mú ọkùnrin mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún nínú gbogbo ẹ̀yà ẹli àti ọgọ́rùn-ún láti inú ẹgbẹ̀rún (1,000) kan àti ẹgbẹ̀rún kan láti inú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) láti máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ-ogun. Yóò sì ṣe nígbà tí àwọn jagunjagun bá dé ti àwọn ará , wọn yóò fún wọn ní ohun tí ó bá tọ́ sí wọn fún gbogbo ìwà búburú àti ìwà ìtìjú tí wọ́n ṣe yìí ní ilẹ̀ ẹli.” Báyìí ni gbogbo àwọn ọkùnrin ẹli parapọ̀ ṣọ̀kan bí ọkùnrin kan ṣoṣo wọ́n sì dìde sí ìlú náà. Àwọn ẹ̀yà ẹli rán àwọn ọkùnrin sí gbogbo ẹ̀yà wí pé, “Kí ni ẹ̀rí sí ìwà búburú yìí tí ó ṣẹlẹ̀ ní àárín yín? Nítorí náà ẹ mú àwọn ẹni ibi ti yìí wá fún wa, kí àwa lé pa, kí a sì fọ ìṣe búburú yìí mọ́ kúrò ní ẹli.” Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà kò fetí sí ti àwọn arákùnrin wọn ọmọ ẹli. Àwọn ẹ̀yà sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú wọn sí láti bá àwọn ọmọ ẹli jà. Ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀ àwọn ará kó ẹgbàá mẹ́tàlá (26,000) àwọn ọmọ-ogun tí ń lọ dájọ́ láti àwọn ìlú wọn, yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin nínú àwọn tí ń gbé . Ní àárín àwọn ọmọ-ogun wọ̀nyí ni ó ti ní àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin tí wọ́n ń lo ọwọ́ òsì, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dára dé bi pé wọ́n lè fi kànnàkànnà ba fọ́nrán òwú ní àìtàsé (wọ́n jẹ́ atamọ́tàsé). Àwọn ọkùnrin ẹli, yàtọ̀ sí àwọn ará , ka ogún ọ̀kẹ́ (400,000) àwọn tí ń fi idà jagun, gbogbo wọn jẹ́ akọni ní ogun jíjà. Àwọn ọmọ ẹli lọ sí , wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run. Wọ́n wí pé, “Ta ni nínú wa tí yóò kọ́ kojú àwọn ará láti bá wọn jà?” Olúwa dáhùn pé, “Juda ni yóò kọ́ lọ.” Àwọn ọmọ ẹli dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n sì dó ti (wọ́n tẹ̀gùn sí ẹ̀bá ). Àwọn ọkùnrin ẹli jáde lọ láti bá àwọn ará jà wọ́n sì dúró ní ipò ogun sí wọn ní . Àwọn ọmọ sì jáde láti wá wọ́n sì pa àwọn ọmọ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) ọkùnrin nínú àwọn ọmọ ẹli ní ojú ogun ní ọjọ́ náà. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin ẹli mú ara wọn lọ́kàn le, wọ́n sì tún dúró sí ipò wọn ní ibi tí wọ́n dúró sí ní ọjọ́ àkọ́kọ́. Àwọn ọmọ ẹli sì lọ wọ́n sọkún ní iwájú Olúwa títí oòrùn fi wọ̀, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa. Wọ́n ni, “Ṣé kí àwa tún gòkè lọ kí a sì bá àwọn ará arákùnrin wa jà?” Olúwa dáhùn pé, “Lọ bá wọn jà.” Àwọn ọmọ ẹli sì tún súnmọ́ tòsí àwọn ará ní ọjọ́ kejì. Ní ọjọ́ yìí nígbà tí ará jáde sí wọn láti , láti dojúkọ wọn, wọ́n pa ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) ọkùnrin ẹli, gbogbo wọn jẹ́ jagunjagun tí ń lo idà. Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ ẹli àní gbogbo àwọn ènìyàn, gòkè lọ sí , níbẹ̀ ni wọ́n jókòó tí wọ́n sì ń sọkún níwájú Olúwa. Wọ́n gbààwẹ̀ ní ọjọ́ náà títí di àṣálẹ́, wọ́n sì rú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà sí Olúwa. Àwọn ọmọ ẹli sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa. (Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run wà níbẹ̀, Finehasi ọmọ ọmọ , ní ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní iwájú rẹ̀.) wọ́n béèrè pé, “Ṣe àwa tún le lọ sí ogun pẹ̀lú arákùnrin wa tàbí kí a má lọ?” Olúwa dáhùn pé, “Ẹ lọ nítorí ní ọ̀la ni èmi yóò fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.” Àwọn ọmọ ẹli sì yàn àwọn ènìyàn tí ó sá pamọ́ yí ká. Wọ́n jáde tọ àwọn ọmọ lọ ní ọjọ́ kẹta wọ́n sì dúró ní ipò wọn, wọ́n sì dìde ogun sí bí wọ́n ti ṣe tẹ́lẹ̀ rí. Àwọn ọmọ sì jáde láti pàdé wọn, àwọn ọmọ ẹli sì tàn wọ́n jáde kúrò ní ìlú náà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣẹ́gun àwọn ọmọ ẹli bí i ti àtijọ́ dé bi pé wọ́n pa bí ọgbọ̀n ọkùnrin ní pápá àti ní àwọn òpópó náà—àwọn ọ̀nà tí ó lọ sí àti èkejì sí . Nígbà tí àwọn ń wí pé, “Àwa ti ń ṣẹ́gun wọn bí i ti ìṣáájú,” àwọn ọmọ ẹli ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sá kí a lè fà wọ́n kúrò ní ìlú sí ojú òpópó náà.” Gbogbo àwọn ọkùnrin ẹli dìde kúrò ní ipò wọn, wọ́n sì tẹ̀dó ogun ní -, àwọn ọmọ-ogun ẹli tí wọ́n sá pamọ́ sínú igbó jáde kúrò níbi tí wọ́n wà ní ìwọ̀-oòrùn . Nígbà náà ni ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) àwọn àṣàyàn ológun àwọn ọmọ ẹli gbógun ti láti iwájú ogun náà le gidigidi dé bí i pé àwọn ẹ̀yà kò funra pé ìparun wà nítòsí. Olúwa ṣẹ́gun níwájú àwọn ọmọ ẹli, ní ọjọ́ náà àwọn ọmọ ẹli pa ẹgbàá méjìlá ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà (25,100) ọkùnrin , gbogbo wọn fi idà dìhámọ́ra ogun. Àwọn ẹ̀yà sì rí pé wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn. Àwọn ọkùnrin ẹli fàsẹ́yìn níwájú àwọn ẹ̀yà nítorí pé wọ́n fọkàn tán àwọn tí ó wà ní ibùba ní ẹ̀bá . Àwọn ọkùnrin tí wọ́n lúgọ yára jáde wọ́n sì tètè wọ , wọ́n fọ́nká wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn tí ó wà nínú ìlú náà. Àwọn ọkùnrin ẹli àti àwọn tí o ba ní ibùba sínú igbó ti fún ara wọn ní àmì pé, kí àwọn tí ó ba ní ibùba fi èéfín ṣe ìkùùkuu ńlá láti inú ìlú náà, nígbà náà ni àwọn ọkùnrin ẹli yípadà, wọ́n sá gun. Àwọn ọmọ sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun àti ní pípa àwọn ọkùnrin ẹli tí ó to ọgbọ̀n, wọ́n sì wí pé, “Àwa ń ṣẹ́gun wọn bí ìgbà ìjà àkọ́kọ́.” Ṣùgbọ́n nígbà tí ìkùùkuu èéfín bẹ̀rẹ̀ sí ní rú sókè láti inú ìlú náà wá, àwọn ẹ̀yà yípadà wọ́n sì rí èéfín gbogbo ìlú náà ń gòkè sí ojú ọ̀run. Àwọn ọkùnrin ẹli sì yípadà sí wọn, ẹ̀rù gidigidi sì ba àwọn ará nítorí pé wọ́n mọ̀ pé àwọn wà nínú ewu. Wọ́n sì sá níwájú àwọn ọmọ ẹli sí apá àṣálẹ́, ṣùgbọ́n wọn kò le sálà kúrò lọ́wọ́ ogun náà. Àwọn ọkùnrin ẹli tí ó jáde láti inú àwọn ìlú wọn wá pa wọ́n run níbẹ̀. Wọ́n yí àwọn ẹ̀yà ká, wọ́n lépa wọn, wọ́n sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìrọ̀rùn ní ibi ìsinmi wọn ní agbègbè ìlà-oòrùn . Ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) àwọn ẹ̀yà ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni jagunjagun. Bí wọ́n ṣe síjú padà tí wọ́n sì ń sálọ sí apá ijù lọ sí ọ̀nà àpáta ni àwọn ọmọ ẹli pa ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin ní àwọn òpópónà. Wọ́n lépa àwọn ẹ̀yà títí dé , wọ́n sì tún bi ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọkùnrin ṣubú. Ní ọjọ́ náà ẹgbàá méjìlá ó lé ẹgbẹ̀rún (25,000) jagunjagun tí ń fi idà jagun ní ó ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni ológun. Ṣùgbọ́n ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin yípadà wọ́n sì sá nínú ààlà lọ sí àpáta , níbi tí wọ́n wà fún oṣù mẹ́rin. Àwọn ọkùnrin ẹli sì padà sí àwọn ìlú wọn sì fi idà pa gbogbo ohun tí ó wà nínú àwọn ìlú wọn àti àwọn ẹran àti gbogbo ohun tí wọn ba níbẹ̀. Gbogbo ìlú tí wọ́n bá ní ojú ọ̀nà ni wọ́n fi iná sun.

Every verse in Judges 20

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00