Judges

Judges 6

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible · tap any highlighted word for context

Judges 6 — Scripture text (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Àwọn ọmọ ẹli sì túnṣe ohun tí ó burú ní ojú Olúwa, Ó sì fi wọ́n lé àwọn ará lọ́wọ́ fún ọdún méje. Agbára àwọn ará sì pọ̀ púpọ̀ lórí àwọn ẹli, wọ́n sì hùwà ipá sí wọn, nítorí ìdí èyí, àwọn ẹli sálọ sí àwọn orí òkè, wọ́n sì kọ́ àgọ́ fún ara wọn nínú ihò àpáta, àti nínú ọ̀gbun àti ní ibi agbára nínú àpáta. Ní ìgbàkúgbà tí àwọn ọmọ ẹli bá ti gbin ọ̀gbìn wọn, àwọn ará , àwọn ará àti àwọn ará ìlà-oòrùn mìíràn yóò wá láti bá wọn jà. Wọn yóò tẹ̀dó sí orí ilẹ̀ náà, wọn a sì bá irúgbìn wọ̀nyí jẹ́ títí dé , wọn kì í sì í fi ohun alààyè kankan sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ẹli, kì bá à ṣe àgùntàn, màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọn a máa wá pẹ̀lú ohun ọ̀sìn wọn àti àwọn àgọ́ wọn, wọn a sì dàbí eṣú nítorí i púpọ̀ wọn. Ènìyàn kò sì lè ka iye àwọn ènìyàn náà bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìbákasẹ, wọ́n pọ̀ dé bi pé wọn kò ṣe é kà ní iye, wọn a bo ilẹ̀ náà wọn a sì jẹ ẹ́ run. Àwọn ará sì pọ́n àwọn ọmọ ẹli lójú, wọ́n sọ wọ́n di òtòṣì àti aláìní, fún ìdí èyí wọ́n ké pe Olúwa nínú àdúrà fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà tí àwọn ọmọ ẹli ké pe Olúwa nítorí àwọn ará . Olúwa fi etí sí igbe wọn, ó sì rán wòlíì kan sí wọn, ẹni tí ó wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run ẹli wí: mo mú yín gòkè ti wá, láti oko ẹrú. Mo gbà yín kúrò nínú agbára àti kúrò ní ọwọ́ gbogbo àwọn aninilára yín. Mo lé wọn kúrò ní iwájú yín, mo sì fi ilẹ̀ wọn fún yín. Mo wí fún un yín pé, ‘Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín; ẹ má ṣe sin àwọn òrìṣà àwọn ará , ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé.’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọ́rọ̀ sí ohun tí mo sọ.” Ní ọjọ́ kan angẹli Olúwa wá, ó sì jókòó ní abẹ́ igi óákù èyí ti ṣe ti ṣi ará , níbi tí ọmọ rẹ̀ ti ń lu ọkà jéró, níbi ìpọntí wáìnì láti fi pamọ́ kúrò níwájú àwọn ará . Nígbà tí angẹli Olúwa fi ara han , ó wí fún un pé, “Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, akọni ológun.” Gideoni dáhùn pé, “Alàgbà, bí Olúwa bá wà pẹ̀lú wa, kí ló dé tí gbogbo ìwọ̀nyí fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa? Níbi gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ tí àwọn baba wa ròyìn rẹ̀ fún wa nígbà tí wọ́n wí pé, ‘Olúwa kò ha mú wa gòkè láti ilẹ̀ wá?’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa ti kọ̀ wá sílẹ̀, ó sì ti fi wá lé àwọn ará lọ́wọ́.” Olúwa sì yípadà sí i, ó sì wí fún un pé, “Lọ nínú agbára tí o ní yìí, kí o sì gba àwọn ará ẹli sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ará . Èmi ni ó ń rán ọ lọ.” Gideoni sì dáhùn pé, “Yéè olúwa mi, ọ̀nà wo ni èmi yóò fi gba ẹli là? Ìdílé mi ni ó jẹ́ aláìlera jù ní , àti pé èmi ni ó sì kéré jù ní ìdílé baba mi.” Olúwa sì dáhùn pé, “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì pa gbogbo àwọn ará láì ku ẹnìkankan.” Gideoni sì dáhùn pé, nísinsin yìí tí mo bá bá ojúrere rẹ pàdé, fún mi ní àmì pé ìwọ ni ń bá mi sọ̀rọ̀. Jọ̀wọ́ má ṣe kúrò níbí títí èmi yóò fi mú ọrẹ wá fún ọ kí n sì gbé e sí iwájú rẹ. Olúwa sì wí pé, “Èmi yóò dúró títí ìwọ yóò fi dé.” Gideoni sì yára wọ ilé lọ, ó sì pa ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan, wọ́n sì sè é, ó sì mú ìyẹ̀fun efa kan, ó fi ṣe àkàrà aláìwú. Ó gbé ẹran náà sínú agbọ̀n, ṣùgbọ́n ó fi ọbẹ̀ rẹ̀ sínú ìkòkò, ó gbé wọn jáde tọ angẹli náà wá bí ọrẹ lábẹ́ igi óákù. Angẹli Ọlọ́run náà sì wí fún un pé, “Gbé ẹran náà àti àkàrà àìwú náà, sí orí àpáta yìí, kí o sì da omi ọbẹ̀ rẹ̀ sí orí rẹ̀.” sì ṣe bẹ́ẹ̀. Angẹli Olúwa sì fi orí ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ kan ẹran àti àkàrà àìwú náà. Iná sì jáde láti inú àpáta, ó sì jó ẹran àti àkàrà náà, kò sì rí angẹli náà mọ́. Nígbà tí sì ti mọ̀ dájúdájú pé angẹli Olúwa ni, ó ké wí pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè! Mo ti rí angẹli Olúwa ní ojúkorojú!” Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Àlàáfíà! Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ kì yóò kùú.” Báyìí ni mọ pẹpẹ kan fún Olúwa níbẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní “Àlàáfíà ni Olúwa.” Ó sì wà ní ti títí di òní. Ní òru ọjọ́ náà Olúwa wí fún un pé, mú akọ màlúù baba rẹ, àní akọ màlúù kejì ọlọ́dún méje. Wó pẹpẹ baba rẹ lulẹ̀, kí o sì bẹ́ igi ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ lulẹ̀. Lẹ́yìn èyí kí o wá mọ pẹpẹ èyí tí ó yẹ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ lórí òkè yìí. Kí o sì mú akọ màlúù kejì, kí o sì mú igi ère òrìṣà Aṣerah tí ìwọ bẹ́ lulẹ̀ rú ẹbọ sísun sí Olúwa. Gideoni mú mẹ́wàá nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì ṣe bí Olúwa ti pàṣẹ fún un ṣùgbọ́n, nítorí ó bẹ̀rù àwọn ará ilé baba rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ìlú náà kò ṣe é ní ọ̀sán, òru ni ó ṣe. Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́, tí àwọn ènìyàn ìlú náà jí, wọ́n rí i pé àti fọ́ pẹpẹ àti pé a ti bẹ́ igi ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, a sì ti fi akọ màlúù kejì rú ẹbọ lórí pẹpẹ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ. Àwọn ènìyàn ìlú náà bi ara wọn wí pé, “Ta ni ó ṣe èyí?” Lẹ́yìn tí wọn fi ara balẹ̀ ṣe ìwádìí, wọ́n gbọ́ wí pé, “Gideoni ọmọ ṣi ni ó ṣe é.” Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì wí fún ṣi wí pé, “Mú ọmọ rẹ jáde wá. Ó ní láti kú nítorí pé ó ti wó pẹpẹ lulẹ̀ ó sì ti ké ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀bá rẹ̀ lulẹ̀.” Ṣùgbọ́n ṣi bi àwọn èrò tí wọ́n fi ìbínú dúró tì í wí pé, “Ẹ̀yin yóò ha gbìjà bí? Ẹ̀yin yóò ha gbà á sílẹ̀ bí? Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìjà rẹ̀ kíkú ni olúwa rẹ̀ yóò kú ní òwúrọ̀. Bí bá ṣe Ọlọ́run nítòótọ́ yóò jà fún ara rẹ̀ bí ẹnikẹ́ni bá wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀.” Fún ìdí èyí ní ọjọ́ náà wọ́n pe ní “” wí pé, “Jẹ́ kí bá a jà,” nítorí pé ó ti wó pẹpẹ . Láìpẹ́ jọjọ, àwọn ogun àwọn , ti àwọn àti ti àwọn ènìyàn ìhà ìlà-oòrùn yòókù kó ara wọn jọ pọ̀ ní ìṣọ̀kan, wọ́n sì kọjá wọ́n sì tẹ̀dó sí àfonífojì . Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé , ó sì fun fèrè ìpè, láti pe àwọn ará láti tẹ̀lé òun. Ó rán àwọn íṣẹ́ la ilẹ̀ já pé kí wọ́n dira ogun, àti sí Aṣeri, Sebuluni àti gbogbo pẹ̀lú sì lọ láti pàdé wọn. Gideoni wí fún Ọlọ́run pé, “Bí ìwọ yóò bá gba ẹli là nípasẹ̀ mi bí ìwọ ti ṣe ìlérí— kíyèsi, èmi yóò fi awọ irun àgùntàn lé ilẹ̀ ìpakà ní alẹ́ òní. Bí ìrì bá sẹ̀ sí orí awọ yìí nìkan tí gbogbo ilẹ̀ yòókù sì gbẹ, nígbà náà ni èmi yóò mọ̀ lóòótọ́ pé ìwọ yóò gba ẹli là nípasẹ̀ mi bí ìwọ ti sọ.” Èyí ni ó sì ṣẹlẹ̀. Nígbà tí jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì fún irun àgùntàn náà, ọpọ́n omi kan sì kún. Gideoni sì tún wí fún Ọlọ́run pé, “Jọ̀wọ́ má ṣe bínú sí mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí n tún wá ìdánilójú kan sí i, èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí n fi awọ irun yìí ṣe ìdánwò kan sí i. Ní àsìkò yìí, jẹ́ kí awọ irun yìí gbẹ kí gbogbo ilẹ̀ sì tutù pẹ̀lú ìrì.” Ní òru náà Ọlọ́run ṣe bẹ́ẹ̀, awọ irun àgùntàn nìkan ni ó gbẹ; gbogbo ilẹ̀ yòókù sì tutù nítorí ìrì.

Every verse in Judges 6

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00