Nehemiah 12:37
“Ní ẹnu ibodè orísun wọ́n ti ń lọ tààrà sí ọ̀nà ní orí àtẹ̀gùn ìlú Dafidi ní orí òkè tí ó kángun sí odi, wọ́n sì gba ẹ̀gbẹ́ ilé Dafidi kọjá títí dé ẹnu ibodè omi ní ìhà ìlà-oòrùn.”
Nehemiah 12:37 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 37 of 47 in Nehemiah chapter 12 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Nehemiah 12 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Àwọn wọ̀nyí ni àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ tí ó bá ọmọ Ṣealitieli àti Jeṣua padà: Seraiah, , Esra, Amariah, Malluki, Hattusi, Ṣekaniah, Rehumu, Meremoti, Iddo, Ginetoni, Abijah, Mijamini, Moadiah, Bilgah, Ṣemaiah, Joiaribu, Jedaiah, Sallu, Amoki, Hilkiah, àti . Wọ̀nyí ni olórí àwọn àlùfáà àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn ní ìgbà ayé e Jeṣua. Àwọn ọmọ ni Jeṣua, Binnui, Kadmieli, Ṣerebiah, Juda àti ẹni tí òun pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ni wọn ṣe àkóso orin ìdúpẹ́. Bakbukiah àti , àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn dúró sí òdìkejì wọn nínú ìsìn. Jeṣua ni baba , Joiakimu ni baba ṣibu, Eliaṣibu ni baba , Joiada ni baba , Jonatani sì ni baba . Ní ìgbé ayé , wọ̀nyí ni àwọn olórí àwọn ìdílé àwọn àlùfáà: ti ìdílé , Meraiah; ti ìdílé , Hananiah; ti ìdílé , Meṣullamu; ti ìdílé , Jehohanani; ti ìdílé , Jonatani; ti ìdílé Ṣekaniah, Josẹfu; ti ìdílé , Adna; ti ìdílé ; ti ìdílé , Sekariah; ti ìdílé , Meṣullamu; ti ìdílé , Sikri; ti ìdílé àti ti ìdílé , Piltai; ti ìdílé , Ṣammua; ti ìdílé Ṣemaiah, Jehonatani; ti ìdílé , Mattenai; ti ìdílé , Ussi; ti ìdílé , Kallai; ti ìdílé , Eberi; ti ìdílé , Haṣabiah; ti ìdílé , Netaneli. Àwọn olórí ìdílé àwọn ọmọ ní ìgbà ayé ṣibu, Joiada, Johanani àti , àti pẹ̀lú ti àwọn àlùfáà ni a kọ sílẹ̀ ní ìgbà ìjọba ará . Àwọn olórí ìdílé láàrín àwọn ọmọ títí di àkókò ọmọ ṣibu ni a kọ sílẹ̀ nínú ìwé ìtàn. Àti àwọn olórí àwọn ọmọ ni Haṣabiah, Ṣerebiah, Jeṣua ọmọ , àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n dúró ní ìdojúkojú wọn láti fi ìyìn àti láti dúpẹ́, apá kan ń dá èkejì lóhùn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ènìyàn Ọlọ́run. Mattaniah, Bakbukiah, , Meṣullamu, Talmoni àti ni aṣọ́nà tí wọ́n ń sọ yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí ní ẹnu-ọ̀nà. Wọ́n ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ìgbà ayé e ọmọ Jeṣua, ọmọ , àti ní ọjọ́ ọ baálẹ̀ àti ní ọjọ́ àlùfáà àti akọ̀wé. Nígbà ìyàsímímọ́ odi ẹmu a mú àwọn ọmọ jáde wá láti ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú wọn wá sí ẹmu láti fi ayọ̀ ṣe ayẹyẹ ìyàsímímọ́ pẹ̀lú orin ìdúpẹ́ àti pẹ̀lú ohun èlò orin kimbali, haapu àti ohun èlò orin olókùn. A kó àwọn akọrin náà jọ papọ̀ láti àwọn ìletò tí ó yí ẹmu náà ká—láti àwọn abúlé , láti -, àti láti àwọn agbègbè àti , nítorí àwọn akọrin ti kọ́ àwọn ìletò fúnra wọn ní agbègbè ẹmu. Nígbà tí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n ya àwọn ènìyàn sí mímọ́, àti ẹnu ibodè àti odi pẹ̀lú. Mo sì tún yan àwọn olórí láti gun orí odi náà. Mo sì tún yan àwọn ẹgbẹ́ akọrin ńlá méjì láti dúpẹ́. Àwọn kan yóò gòkè odi lọ sí apá ọ̀tún sí ọ̀nà ibodè Ààtàn. Hoṣaiah àti ìdajì àwọn olórí tẹ̀lé wọn, àwọn wọ̀nyí náà sì lọ pẹ̀lú wọn, Asariah, Esra, Meṣullamu, Juda, Benjamini, Ṣemaiah, , pẹ̀lú àwọn àlùfáà díẹ̀ pẹ̀lú ìpè, pẹ̀lú u ọmọ , ọmọ Ṣemaiah, ọmọ , ọmọ , ọmọ , ọmọ , àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, Ṣemaiah, Asareeli, Milalai, Gilalai, Maai, Netaneli, Juda àti —pẹ̀lú ohun èlò orin bí àṣẹ ènìyàn Ọlọ́run. Esra akọ̀wé ni ó ṣáájú wọn bí wọ́n ti ń tò lọ lọ́wọ̀ọ̀wọ́. Ní ẹnu ibodè orísun wọ́n ti ń lọ tààrà sí ọ̀nà ní orí àtẹ̀gùn ìlú ní orí òkè tí ó kángun sí odi, wọ́n sì gba ẹ̀gbẹ́ ilé kọjá títí dé ẹnu ibodè omi ní ìhà ìlà-oòrùn. Àwọn ẹgbẹ́ akọrin kejì gba ọ̀nà òdìkejì lọ. Mo tẹ̀lé wọn ní orí odi, pẹ̀lú ìdajì àwọn ènìyàn, kọjá ilé ìṣọ́ ìléru lọ sí odi fífẹ̀, kọjá ẹnu ibodè ibodè Jeṣana, ẹnu ibodè ẹja, ilé ìṣọ́ àti ilé ìṣọ́ ọgọ́rùn-ún, títí dé ẹnu ibodè àgùntàn. Wọ́n sì dúró ní ibodè ìṣọ́. Àwọn ẹgbẹ́ akọrin méjèèjì tí wọ́n dúpẹ́ wà ní ààyè nínú ilé Ọlọ́run, èmi náà sì dúró ní ààyè mi pẹ̀lú ìdajì àwọn ìjòyè, àti àwọn àlùfáà , Maaseiah, Miniamini, Mikaiah, Elioenai, Sekariah àti pẹ̀lú àwọn ìpè wọn. Àti pẹ̀lú , Ṣemaiah, Eleasari àti , àti , àti , àti , àti . Àwọn akọrin kọrin sókè ní abẹ́ alábojútó . Ní ọjọ́ náà wọ́n rú ẹbọ ńlá, wọ́n ṣe àjọyọ̀ nítorí Ọlọ́run ti fún wọn ní ayọ̀ ńlá. Àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé sì yọ̀ pẹ̀lú. A lè gbọ́ ariwo ayọ̀ tí ó jáde láti ẹmu ní jìnnà réré. Ní àkókò náà, a yan àwọn ènìyàn láti jẹ́ alábojútó yàrá ìṣúra fún àwọn ọrẹ àkọ́so èso àti àwọn ìdámẹ́wàá. Láti inú àwọn oko tí ó wà ní àyíká ìlú ni wọ́n ti ní láti mú wá sínú yàrá ìṣúra, ìpín tí òfin sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ , nítorí inú àwọn ará a yọ́ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ tó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́. Wọ́n ń ṣiṣẹ́ Ọlọ́run wọn àti iṣẹ́ ìyàsímímọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni fún àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà, wọ́n ń ṣe gẹ́gẹ́ bí àti ọmọ rẹ̀ ti pàṣẹ fún wọn. Ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn ní ìgbà àti , ni àwọn atọ́nisọ́nà ti wà fún àwọn akọrin àti fún orin ìyìn àti orin ọpẹ́ sí Ọlọ́run. Nítorí náà ní ìgbà ayé àti , gbogbo ẹli ni ó ń dá ìpín lójoojúmọ́ fún àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà. Wọ́n sì tún yan ìpín mìíràn sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ tókù, àwọn ọmọ náà tún ya ìpín ti àwọn ọmọ sọ́tọ̀ fún wọn.
Every verse in Nehemiah 12
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.