Psalms

Psalms 120

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible · tap any highlighted word for context

Psalms 120 — Scripture text (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Èmi ké pe Olúwa nínú ìpọ́njú mi, ó sì dá mi lóhùn. Gbà mí, Olúwa, kúrò lọ́wọ́ ètè èké àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn. Kí ni kí a fi fún ọ? Àti kí ni kí a túnṣe fún ọ, ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn? Òun yóò bá ọ wí pẹ̀lú ọfà mímú ológun, pẹ̀lú ẹ̀yín iná igi ìgbálẹ̀. Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Meṣeki, nítorí èmi gbé nínú àgọ́ ìlú ! Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbé láàrín àwọn tí ó kórìíra àlàáfíà. Ènìyàn àlàáfíà ni mí; ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni dúró fun wọn.

Every verse in Psalms 120

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00