Psalms
Psalms 124
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible · tap any highlighted word for context
Psalms 124 — Scripture text (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
“Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa,” kí ni ẹli kí ó máa wí nísinsin yìí; ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa, nígbà tí àwọn ènìyàn gbógun sí wa, nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa, nígbà náà ni omi wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀, nígbà náà ni agbéraga omi ìbá borí ọkàn wa. Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́n bí ohun ọdẹ fún eyín wọn. Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ; okùn já àwa sì yọ. Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa, tí ó dá ọ̀run òun ayé.
Every verse in Psalms 124
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.