Psalms

Psalms 126

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible · tap any highlighted word for context

Psalms 126 — Scripture text (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ padà, àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá. Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín, àti ahọ́n wa kọ orin; nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé, Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn. Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa; nítorí náà àwa ń yọ̀. Olúwa mú ìkólọ wa padà, bí ìṣàn omi ní gúúsù. Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn yóò fi ayọ̀ ka. Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ, tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́, lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá, yóò sì ru ìtí rẹ̀.

Every verse in Psalms 126

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00