Psalms

Psalms 61

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible · tap any highlighted word for context

Psalms 61 — Scripture text (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run; tẹ́tí sí àdúrà mi. Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́, mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀; mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ. Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi, ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá. Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ. Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run; Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ. Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn, ọdún rẹ̀ fún ìrandíran. Kí ó máa jẹ ọba níwájú Ọlọ́run títí láé; pèsè àánú àti òtítọ́ rẹ tí yóò máa ṣe ìtọ́jú rẹ. Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ títí láé kí n san ẹ̀jẹ́ mi ní ojoojúmọ́.

Every verse in Psalms 61

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00