Psalms 97:4
“Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn ó sì kárí ayé ayé rí i ó sì wárìrì.”
Psalms 97:4 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 4 of 12 in Psalms chapter 97 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Psalms 97 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Olúwa jẹ ọba, jẹ́ kí ayé kí ó yọ̀ jẹ́ kí inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù kí ó dùn. Ojú ọ̀run àti òkùnkùn yíká òdodo àti ìdájọ́ ni ó ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀. Iná ń jó níwájú rẹ̀. Ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ yíkákiri. Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn ó sì kárí ayé ayé rí i ó sì wárìrì. Òkè gíga yọ́ gẹ́gẹ́ bí ìda níwájú Olúwa, níwájú Olúwa gbogbo ayé. Àwọn ọ̀run ròyìn òdodo rẹ̀, gbogbo ènìyàn sì rí ògo rẹ̀. Gbogbo àwọn tí ń sin ère fínfín ni ojú yóò tì, àwọn tí ń fi ère gbéraga, ẹ máa sìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́run! Sioni gbọ́, inú rẹ̀ sì dùn inú àwọn ilé sì dùn, nítorí ìdájọ́ rẹ, Olúwa. Nítorí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ga ju gbogbo ayé lọ ìwọ ni ó ga ju gbogbo òrìṣà lọ. Jẹ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́ Olúwa, kórìíra ibi, ó pa ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́ ó gbà wọ́n ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú. Ìmọ́lẹ̀ tàn sórí àwọn olódodo àti ayọ̀ nínú àlàyé ọkàn. Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olódodo, kí ẹ sì yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.
Every verse in Psalms 97
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.