1 Kings 21:22

“Èmi yóò ṣe ilé rẹ bí ilé Jeroboamu, ọmọ Nebati, àti bí ilé Baaṣa, ọmọ Ahijah, nítorí ìwọ ti mú mi bínú, ìwọ sì ti mú Israẹli ṣẹ̀.’”

1 Kings 21:22 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 22 of 29 in 1 Kings chapter 21 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

1 Kings 21 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ó sì ṣe lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ará sì ní ọgbà àjàrà kan ní , ní ẹ̀gbẹ́ ààfin ọba . Ahabu sì wí fún pé, “Fún mi ní ọgbà àjàrà rẹ, kí èmi kí ó fi ṣe ọgbà-ewébẹ̀, nítorí tí ó súnmọ́ tòsí ilé mi, èmi yóò sì fún ọ ní ọgbà àjàrà tí ó sàn jù ú lọ dípò rẹ̀; tàbí bí ó bá sì dára ní ojú rẹ, èmi yóò fi iye owó rẹ̀ fún ọ.” Ṣùgbọ́n wí fún pé, “Olúwa má jẹ́ kí èmi fi ogún àwọn baba mi fún ọ.” Ahabu sì wá sí ilé rẹ̀, ó wugbọ́, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí ọ̀rọ̀ tí ará sọ fún un; nítorí tí ó wí pé, “Èmi kì yóò fún ọ ní ogún àwọn baba mi.” Ó sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀, ó sì yí ojú rẹ̀ padà, kò sì fẹ́ jẹun. Jesebeli aya rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí inú rẹ fi bàjẹ́, èéṣe tí ìwọ kò sì jẹun?” Ó sì dá a lóhùn pé, “Nítorí tí mo wí fún ará pé, ‘Ta ọgbà àjàrà rẹ fún mi, tàbí bí ó bá wù ọ́, èmi yóò fún ọ ní ọgbà àjàrà mìíràn ní ipò rẹ̀.’ Ṣùgbọ́n ó wí pé, ‘Èmi kì yóò fún ọ ní ọgbà àjàrà mi.’ ” Jesebeli aya rẹ̀ sì wí pé, “Ṣé báyìí ni ìwọ yóò ṣe ṣe bí ọba lórí ẹli? Dìde, jẹun! Kí o sì jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn. Èmi yóò sì fún ọ ní ọgbà àjàrà ará .” Bẹ́ẹ̀ ni ó kọ̀wé ní orúkọ , ó sì fi èdìdì rẹ̀ dì í, ó sì fi ìwé náà ránṣẹ́ sí àwọn àgbàgbà àti àwọn ọlọ́lá tí ó ń gbé ní ìlú pẹ̀lú rẹ̀. Nínú àwọn ìwé náà, ó kọ pé, “Ẹ kéde àwẹ̀, kí ẹ sì fi sí ipò ọlá láàrín àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n kí ẹ fi ènìyàn méjì, ẹni búburú síwájú rẹ̀ láti jẹ́rìí sí i wí pé, ó bú Ọlọ́run àti ọba. Nígbà náà ni kí ẹ mú u jáde, kí ẹ sì sọ ọ́ ní òkúta pa.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbàgbà àti àwọn ọlọ́lá tí wọ́n ń ṣe ará ìlú sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwé tí kọ ránṣẹ́ sí wọn. Wọ́n sì kéde àwẹ̀, wọ́n sì fi sí ipò ọlá láàrín àwọn ènìyàn. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin méjì sì dé, àwọn ẹni búburú, wọ́n sì jókòó síwájú rẹ̀, wọ́n sì jẹ́rìí lòdì sí níwájú àwọn ènìyàn wí pé, “Naboti ti bú Ọlọ́run àti ọba.” Nígbà náà ni wọ́n mú jáde kúrò ní ìlú, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa. Nígbà náà ni wọ́n ránṣẹ́ sí wí pé, “A ti sọ ní òkúta, ó sì kú.” Bí sì ti gbọ́ pé, a ti sọ ní Òkúta pa, ó sì wí fún pé, “Dìde! Kí o sì jogún ọgbà àjàrà , ará , tí ó kọ̀ láti tà fún ọ kò sí láààyè mọ́, ó ti kú.” Nígbà tí sì gbọ́ pé ti kú, ó sì dìde, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ láti jogún ọgbà àjàrà . Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ ará Tiṣibi wá wí pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ pàdé ọba ẹli, tí ó wà ní . Ó wà ní ọgbà àjàrà báyìí, níbi tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ láti jogún rẹ̀. Sọ fún un pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ǹjẹ́ ìwọ kò ti pa ènìyàn, o sì ti fi agbára gba ogún rẹ̀?’ Nígbà náà ni kí o wí fún un pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Níbi tí ajá gbé lá ẹ̀jẹ̀ , ni àwọn ajá yóò lá ẹ̀jẹ̀ rẹ, àní tìrẹ!’ ” Ahabu sì wí fún pé, “Ìwọ ti rí mi, ìwọ ọ̀tá mi!” Ó sì dáhùn wí pé, “Èmi ti rí ọ, nítorí tí ìwọ ti tan ara rẹ láti ṣe búburú níwájú Olúwa. ‘Èmi yóò mú ibi wá sórí rẹ. Èmi yóò sì mú ìran rẹ kúrò, èmi yóò sì ké kúrò lọ́dọ̀ gbogbo ọmọdé ọkùnrin, àti ọmọ ọ̀dọ̀, àti òmìnira ní ẹli. Èmi yóò ṣe ilé rẹ bí ilé , ọmọ , àti bí ilé ṣa, ọmọ , nítorí ìwọ ti mú mi bínú, ìwọ sì ti mú ẹli ṣẹ̀.’ “Àti ní ti pẹ̀lú Olúwa wí pé, ‘Àwọn ajá yóò jẹ nínú yàrá .’ “Àwọn ajá yóò jẹ ẹni tí ó kú ní ìlú, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yóò jẹ àwọn ẹni tí ó kú ní igbó.” (Kò sí ẹnìkan bí tí ó ta ara rẹ̀ láti ṣe búburú níwájú Olúwa, ẹni tí aya rẹ̀ ń tì. Ó sì ṣe ohun ìríra gidigidi ní tí tọ òrìṣà lẹ́yìn, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí àwọn ará ti ṣe, tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ ẹli.) Nígbà tí sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ sí ara rẹ̀, ó sì gbààwẹ̀. Ó sì dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì ń lọ jẹ́ẹ́. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ ará Tiṣibi wá wí pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ti rí bí ti rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi? Nítorí tí ó ti rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀, èmi kì yóò mú ibi náà wá ní ọjọ́ rẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò mú u wá sí ilé rẹ̀ ní ọjọ́ ọmọ rẹ̀.”

Every verse in 1 Kings 21

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00