1 Samuel 22:23
“Ìwọ jókòó níhìn-ín lọ́dọ̀ mi, má ṣe bẹ̀rù, nítorí pé ẹni ti ń wá ẹ̀mí mi, ó ń wá ẹ̀mí rẹ, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ mi ni ìwọ ó wà ní àìléwu.””
1 Samuel 22:23 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 23 of 23 in 1 Samuel chapter 22 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
1 Samuel 22 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Dafidi sì kúrò níbẹ̀, ó sì sá sí ihò ; nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ìdílé baba rẹ̀ sì gbọ́, wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá níbẹ̀. Olúkúlùkù ẹni tí ó tí wà nínú ìpọ́njú, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ti jẹ gbèsè, àti olúkúlùkù ẹni tí ó wà nínú ìbànújẹ́, sì kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, òun sì jẹ́ olórí wọn; àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì tó ìwọ̀n irinwó (400) ọmọkùnrin. Dafidi sì ti ibẹ̀ náà lọ sí tí : ó sì wí fún ọba pé, “Jẹ́ kí baba àti ìyá mi, èmi bẹ̀ ọ́ wá bá ọ gbé, títí èmi yóò fi mọ ohun ti Ọlọ́run yóò ṣe fún mi.” Ó sì mú wọn wá síwájú ọba ; wọ́n sì bá á gbé ní gbogbo ọjọ́ tí fi wà nínú ihò náà. Gadi wòlíì sí wí fún pé, “Ma ṣe gbé inú ihò náà, yẹra, kí o sí lọ sí ilẹ̀ .” Nígbà náà ni sì yẹra, ó sì lọ sínú igbó . Saulu si gbọ́ pé a rí àti àwọn ọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀; Saulu sì ń bẹ ní lábẹ́ igi tamariski ní ; ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dúró tì í. Nígbà náà ni wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó dúró tì í, pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbọ́ ẹ̀yin ará , ọmọ yóò ha fún olúkúlùkù yín ni oko ọgbà àjàrà bí? Kí ó sì sọ gbogbo yin dì olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún bí? Tí gbogbo yín di ìmọ̀lù sí mi, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó sọ létí mi pé, ọmọ mi ti bá ọmọ mulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kó sì sí ẹnìkan nínú yín tí ó ṣàánú mi, tí ó sì sọ ọ́ létí mi pé, ọmọ mi mú kí ìránṣẹ́ mi dìde sí mi láti ba dè mí, bí ó ti rí lónìí.” Doegi ará tí a fi jẹ olórí àwọn ìránṣẹ́ , sì dáhùn wí pé, “Èmi rí ọmọ , ó wá sí , sọ́dọ̀ ọmọ . Òun sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa fún un, ó sì fún un ní oúnjẹ, ó sí fún un ni idà ará .” Ọba sì ránṣẹ́ pe àlùfáà, ọmọ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀, àwọn àlùfáà tí ó wà ni : gbogbo wọn ni ó sì wá sọ́dọ̀ ọba. Saulu sì wí pé, “Ǹjẹ́ gbọ́, ìwọ ọmọ .” Òun sì wí pé, “Èmi nìyìí olúwa mi.” Saulu sì wí fún un pé, “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi, ìwọ àti ọmọ , tí ìwọ fi fún un ní àkàrà, àti idà, àti ti ìwọ fi béèrè fún un lọ́dọ̀ Ọlọ́run kí òun lè dìde sí mi, láti ba dè mí, bí ó ti rí lónìí.” Ahimeleki sì dá ọba lóhùn, ó sì wí pé, “Ta ni ó jẹ́ olóòtítọ́ nínú gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ bí , ẹni tí ó jẹ́ àna ọba, ẹni tí ó ń gbọ́ tìrẹ, tí ó sì ni ọlá ní ilé rẹ. Òní lèmi ó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un bí? Kí èyí jìnnà sí mi: kí ọba má ṣe ka nǹkan kan sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́rùn, tàbí sí gbogbo ìdílé baba mi: nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ̀ kò mọ̀kan nínú gbogbo nǹkan yìí, díẹ̀ tàbí púpọ̀.” Ọba sì wí pé, “Ahimeleki, kíkú ni ìwọ yóò kú, ìwọ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀.” Ọba sì wí fún àwọn aṣáájú ti máa ń sáré níwájú ọba, tí ó dúró tì í pé, “Yípadà kí ẹ sì pa àwọn àlùfáà Olúwa; nítorí pé ọwọ́ wọn wà pẹ̀lú , àti nítorí pé wọ́n mọ ìgbà tí òun sá, wọn kò sì sọ ọ́ létí mi.” Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ ọba kò sì jẹ́ fi ọwọ́ wọn lé àwọn àlùfáà Olúwa láti pa wọ́n. Ọba sì wí fún pé, “Ìwọ yípadà, kí o sì pa àwọn àlùfáà!” ará sì yípadà, ó sì kọlu àwọn àlùfáà, ó sì pa wọ́n ní ọjọ́ náà, àrùnlélọ́gọ́rin ènìyàn ti ń wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ efodu. Ó sì fi ojú idà pa ara , ìlú àwọn àlùfáà náà àti ọkùnrin àti obìnrin, ọmọ wẹ́wẹ́, àti àwọn tí ó wà lẹ́nu ọmú, àti màlúù, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti àgùntàn. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọmọ tí a ń pè ní sì bọ́; ó sì sá àsálà tọ lọ. Abiatari sì fihan pé pa àwọn àlùfáà Olúwa tán. Dafidi sì wí fún pé, “Èmi ti mọ̀ ní ọjọ́ náà, nígbà tí ará ti wà níbẹ̀ pé, nítòótọ́ yóò sọ fún : nítorí mi ni a ṣe pa gbogbo ìdílé baba rẹ. Ìwọ jókòó níhìn-ín lọ́dọ̀ mi, má ṣe bẹ̀rù, nítorí pé ẹni ti ń wá ẹ̀mí mi, ó ń wá ẹ̀mí rẹ, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ mi ni ìwọ ó wà ní àìléwu.”
Every verse in 1 Samuel 22
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.