1 Timothy 3:5

“Ṣùgbọ́n bí ènìyàn kò bá mọ̀ bí a ti ń ṣe ìkáwọ́ ilé ara rẹ̀, òun ó ha ti ṣe lè tọ́jú ìjọ Ọlọ́run?”

1 Timothy 3:5 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 5 of 16 in 1 Timothy chapter 3 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

1 Timothy 3 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, bí ẹnìkan bá fẹ́ ipò alábojútó, iṣẹ́ rere ni ó ń fẹ́. Ǹjẹ́ alábojútó yẹ kí ó jẹ́ aláìlẹ́gàn, ọkọ aya kan, olùṣọ̀ràn, aláìrékọjá, íwà rere, olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, ẹni tí ó lè ṣe olùkọ́. Kí ó má jẹ́ ọ̀mùtí, tàbí íjàgídíjàgan, tàbí olójúkòkòrò, bí kò ṣe ísùúrù, kí ó má jẹ́ íjà, tàbí olùfẹ́ owó. Ẹni tí ó káwọ́ ilé ara rẹ̀ gírígírí, tí ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ tẹríba pẹ̀lú ìwà àgbà gbogbo. Ṣùgbọ́n bí ènìyàn kò bá mọ̀ bí a ti ń ṣe ìkáwọ́ ilé ara rẹ̀, òun ó ha ti ṣe lè tọ́jú ìjọ Ọlọ́run? Kí ó má jẹ́ ẹni tuntun ti ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàgbọ́, kí ó má ba à gbéraga, a sì ṣubú sínú ẹ̀bi èṣù. Ó sì yẹ kí ó ni ẹ̀rí rere pẹ̀lú lọ́dọ̀ àwọn tí ń bẹ lóde; kí ó má ba à bọ́ sínú ẹ̀gàn àti sínú ìdẹ̀kùn èṣù. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn Díákónì láti ní ìwà àgbà, kí wọ́n máa jẹ́ ẹlẹ́nu méjì, kí wọ́n máa fi ara wọn fún wáìnì púpọ̀, kí wọ́n má jẹ́ olójúkòkòrò. Kí wọn máa di ohun ìjìnlẹ̀ ìgbàgbọ́ mú pẹ̀lú ọkàn funfun. Kí a kọ́kọ́ wádìí àwọn wọ̀nyí dájú pẹ̀lú; nígbà náà ni kí a jẹ́ kí wọn ó ṣiṣẹ́ díákónì, bí wọn bá jẹ́ aláìlẹ́gàn. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn obìnrin láti ni ìwà àgbà, kí wọn má jẹ́ asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn bí kò ṣe aláìrékọjá, olóòtítọ́ ní ohun gbogbo. Kí àwọn díákónì jẹ́ ọkọ obìnrin kan, kí wọn káwọ́ àwọn ọmọ àti ilé ara wọn dáradára. Nítorí àwọn tí ó lo ipò díákónì dáradára ra ipò rere fún ara wọn, àti ìgboyà púpọ̀ nínú ìgbàgbọ́ tí ń bẹ nínú . Ìwé nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ sí ọ, mo sì ń retí àti tọ̀ ọ́ wá ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Ṣùgbọ́n bí mo bá pẹ́, kí ìwọ lè mọ̀ bí ó ti yẹ fún àwọn ènìyàn láti máa hùwà nínú ilé Ọlọ́run, tì í ṣe ìjọ Ọlọ́run alààyè, ọ̀wọ́n àti ìpìlẹ̀ òtítọ́. Láìṣiyèméjì, títóbi ní ohun ìjìnlẹ̀ ìwà-bí-Ọlọ́run: ẹni tí a fihàn nínú ara, tí a dá láre nínú Ẹ̀mí, ti àwọn angẹli rí, tí a wàásù rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, tí a gbàgbọ́ nínú ayé, tí a sì gbà sókè sínú ògo.

Every verse in 1 Timothy 3

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00