2 Chronicles 24:13
“Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ náà, sì lọ síwájú àti síwájú ní ọwọ́ wọn, wọ́n sì tún mú ilé Ọlọ́run dúró sí ipò rẹ̀, wọ́n mú un le.”
2 Chronicles 24:13 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 13 of 27 in 2 Chronicles chapter 24 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
2 Chronicles 24 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Joaṣi jẹ́ ọmọ ọdún méje nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ní ẹmu fún ogójì ọdún. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni ti ṣeba. Joaṣi ṣe ohun tí ó dára ní ojú Olúwa ní gbogbo àkókò àlùfáà. Jehoiada yan ìyàwó méjì fún un, ó sì ní àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Ní àkókò kan, Joaṣi pinnu láti tún ilé Olúwa ṣe. Ó pe àwọn àlùfáà àti àwọn ará jọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí àwọn ìlú , kí ẹ sì gba owó ìtọ́sí láti ọwọ́ gbogbo ẹli láti fi tún ilé Ọlọ́run yín ṣe.” Ṣùgbọ́n àwọn ará kò ṣe é lẹ́ẹ̀kan náà. Nítorí náà ọba pa á láṣẹ fún olórí àlùfáà ó sì wí fún un pé, “Kí ni ó dé tí o kò béèrè lọ́wọ́ àwọn ará láti mú wá láti àti ẹmu, owó orí tí ìránṣẹ́ Olúwa ti fi lélẹ̀ àti nípasẹ̀ àpéjọ gbogbo ẹli fún àgọ́ ẹ̀rí?” Nísinsin yìí, àwọn ọmọkùnrin obìnrin búburú ni ti fọ́ ilé Ọlọ́run, ó sì ti lo àwọn nǹkan ìyàsọ́tọ̀ fún àwọn . Nípasẹ̀ ọba, wọn ṣe àpótí wọ́n sì gbé e sí ìta, ní ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa. A ṣe ìkéde ní àti ẹmu wí pé wọ́n gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa, owó orí tí ìránṣẹ́ Olúwa ti béèrè lọ́wọ́ ẹli ní aginjù. Gbogbo àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn ènìyàn sì yọ̀, wọ́n sì mú un wá, wọ́n ń jù ú sínú àpótí títí tí ó fi kún. Nígbàkígbà tí a bá gbé àpótí wọlé láti ọwọ́ àwọn ará sí ọwọ́ àwọn ìjòyè ọba, tí wọ́n bá sì rí wí pe owó ńlá wà níbẹ̀ àwọn akọ̀wé ọba àti ìjòyè olórí àlùfáà yóò wá láti kó owó rẹ̀ kúrò, wọn yóò sì dá a padà sí ààyè rẹ̀. Wọ́n ṣe èyí déédé, wọ́n sì kó iye owó ńlá. Ọba àti fi fún àwọn ọkùnrin náà tí ó sì ń ṣiṣẹ́ nínú ilé Olúwa. Wọ́n fi owó gba ẹni tí ń fi òkúta mọ ilé àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà láti kọ́ ilé Olúwa padà, àti àwọn òṣìṣẹ́ pẹ̀lú irin àti idẹ láti tún ilé Olúwa ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ náà, sì lọ síwájú àti síwájú ní ọwọ́ wọn, wọ́n sì tún mú ilé Ọlọ́run dúró sí ipò rẹ̀, wọ́n mú un le. Nígbà tí wọ́n sì parí rẹ̀ tán, wọ́n mú owó ìyókù wá sí iwájú ọba àti , a sì fi ohun èlò fún ilé Olúwa, àní ohun èlò fún ìsìn àti fún ẹbọ pẹ̀lú ọpọ́n, àní ohun èlò wúrà àti fàdákà. Wọ́n sì ń rú ẹbọ sísun ní ilé Olúwa nígbà gbogbo ní gbogbo ọjọ́ . Ṣùgbọ́n di arúgbó, ó sì kún fún ọjọ́, ó sì kú, ẹni àádóje ọdún ni nígbà tí ó kú. Wọ́n sì sin ín ní ìlú pẹ̀lú àwọn ọba, nítorí tí ó ṣe rere ní ẹli, àti sí Ọlọ́run àti sí ilé rẹ̀. Lẹ́yìn ikú , àwọn íṣẹ́ wá láti fi ìforíbalẹ̀ wọn hàn sí ọba. Ó sì fèsì sí wọn. Wọ́n pa ilé Olúwa tì, Ọlọ́run baba a wọn. Wọ́n sì ń sin àwọn ère Aṣerah àti àwọn òrìṣà. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn yìí, ìbínú Ọlọ́run dé sórí àti ẹmu. Bí ó ti wù kí ó rí, Olúwa rán àwọn wòlíì sí àwọn ènìyàn láti mú wọn padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, wọ́n jẹ́rìí nípa wọn, wọn kì yóò gbọ́. Nígbà náà, Ẹ̀mí Ọlọ́run wá sórí ọmọ wòlíì, ó dúró níwájú àwọn ènìyàn ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Kí ni ó dé tí ẹ̀yin kò fi tẹ̀lé àṣẹ Olúwa? Ìwọ kì yóò ṣe rere. Nítorí tí ìwọ ti kọ Olúwa sílẹ̀, òun pẹ̀lú ti kọ̀ yín sílẹ̀.’ ” Ṣùgbọ́n wọ́n dìtẹ̀ sí i, àti nípa àṣẹ ọba, wọ́n sọ ọ́ lókùúta pa nínú àgbàlá ààfin ilé Olúwa. Ọba ṣi kò rántí inú rere tí baba ti fihàn án ṣùgbọ́n, ó pa ọmọ rẹ̀, tí ó wí bí ó ti ń kú lọ pé, “Kí Olúwa kí ó rí èyí kí ó sì pè ọ́ sí ìṣirò.” Ní òpin ọdún, àwọn ọmọ-ogun yàn láti dojúkọ ṣi; wọ́n gbógun ti àti ẹmu, wọ́n sì pa gbogbo àwọn aṣáájú àwọn ènìyàn. Wọ́n rán gbogbo àwọn ìkógun sí ọba wọn ní . Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ-ogun ti wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀ Olúwa sì fi ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ogun lé wọn lọ́wọ́, nítorí tí ti kọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe ìdájọ́ ṣi. Nígbà tí àwọn ará kúrò, wọ́n fi ṣi sílẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ọgbẹ́. Àwọn íṣẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ si fún pípa ọmọ àlùfáà, wọ́n sì pa á ní orí ibùsùn rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ó sì kú, a sì sin ín sínú ìlú ńlá ti , ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú àwọn ibojì àwọn ọba. Àwọn tí ó dìtẹ̀ sì jẹ́ , ọmọ Ṣimeati arábìnrin àti ọmọ Ṣimiriti arábìnrin . Àkọsílẹ̀ àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀, àti àkọsílẹ̀ ti ìmúpadà sípò ilé Ọlọ́run ní a kọ sínú ìwé ìtumọ̀ ti àwọn ọba. Amasiah ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
Every verse in 2 Chronicles 24
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.