2 Chronicles 26:15
“Ní Jerusalẹmu ó sì ṣe ohun ẹ̀rọ ìjagun, iṣẹ́ ọwọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn, láti wà lórí ilé ìṣọ́ àti lórí igun odi láti fi tafà àti láti fi sọ òkúta ńlá. Orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri, nítorí a ṣe ìrànlọ́wọ́ ìyanu fún un títí ó fi di alágbára.”
2 Chronicles 26:15 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 15 of 23 in 2 Chronicles chapter 26 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
2 Chronicles 26 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Nígbà náà gbogbo ènìyàn mú , ẹni tí ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún wọ́n sì fi jẹ ọba ní ipò baba rẹ̀ . Òun ni ẹni náà tí ó tún kọ́, ó sì mú padà sí lẹ́yìn ìgbà tí ọba ti sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Ussiah sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní ẹmu fún ọdún méjìléláàádọ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni ; ó sì wá láti ẹmu. Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bi baba rẹ̀ ti ṣe. Ó sì wá Olúwa ní ọjọ́ , ẹni tí ó ní òye nínú ìran Ọlọ́run. Níwọ́n ọjọ́ tí ó wá ojú Olúwa, Ọlọ́run fún un ní ohun rere. Ó sì lọ sí ogun pẹ̀lú ó sì wó odi lulẹ̀, Jabne àti Aṣdodu. Ó sì kó ìlú rẹ̀ tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ Aṣdodu àti níbìkan láàrín àwọn ará . Ọlọ́run sì ràn án lọ́wọ́ lórí àwọn ará àti tí ń gbé ní -baali àti lórí àwọn ará . Àwọn ará gbé ẹ̀bùn wá fún , orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri títí ó fi dé àtiwọ , nítorí ó ti di alágbára ńlá. Ussiah sì kọ́ ilé ìṣọ́ ní ẹmu níbi ẹnu-bodè igun, àti níbi ẹnu-bodè àfonífojì àti níbi ìṣẹ́po odi ó sì mú wọn le Ó sì tún ilé ìṣọ́ aginjù kọ́, ó sì gbẹ́ kànga púpọ̀, nítorí ó ni ẹran ọ̀sìn púpọ̀ ní ilẹ̀ ìsàlẹ̀ àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó sì ní àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ ní pápá àti ọgbà àjàrà ní orí òkè ní ilẹ̀ ọlọ́ràá, nítorí ó fẹ́ràn àgbẹ̀ ṣíṣe. Ussiah sì ní àwọn ẹgbẹ́ ogun tí wọ́n kọ́ dáradára, wọ́n múra tán láti lọ pẹ̀lú ẹgbẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí iye kíkà wọn gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ akọ̀wé àti ìjòyè lábẹ́ ọwọ́ , ọ̀kan lára àwọn olórí ogun ọba. Àpapọ̀ iye olórí àwọn alágbára akọni ogun jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá (2,600). Lábẹ́ olórí àti olùdarí wọn, wọ́n sì jẹ́ alágbára akọni ogun ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (307,500), tí ó ti múra fún ogun ńlá náà, àti alágbára ńlá jagunjagun kan láti ran ọba lọ́wọ́ sí ọ̀tá rẹ̀. Ussiah sì pèsè ọ̀kọ̀, asà, akọ́rọ́, àti ohun èlò ìhámọ́ra ọrun títí dé òkúta kànnàkànnà fún ọwọ́ àwọn ọmọ-ogun. Ní ẹmu ó sì ṣe ohun ẹ̀rọ ìjagun, iṣẹ́ ọwọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn, láti wà lórí ilé ìṣọ́ àti lórí igun odi láti fi tafà àti láti fi sọ òkúta ńlá. Orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri, nítorí a ṣe ìrànlọ́wọ́ ìyanu fún un títí ó fi di alágbára. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí jẹ́ alágbára tán, ìgbéraga rẹ̀ sì gbé e ṣubú. Ó sì di aláìṣòótọ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. Ó sì wọ ilé Olúwa láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí. Asariah àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọgọ́rin alágbára àlùfáà Olúwa mìíràn sì tẹ̀lé e. Wọ́n sì takò ọba , wọn sì wí pé, “Kò dára fún ọ, Ussiah, láti sun tùràrí sí Olúwa. Èyí fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ , ẹni tí ó ti yà sí mímọ́ láti sun tùràrí. Fi ibi mímọ́ sílẹ̀, nítorí tí ìwọ ti jẹ́ aláìṣòótọ́, ìwọ kò sì ní jẹ́ ẹni ọlá láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run.” Ussiah, ẹni tí ó ní àwo tùràrí ní ọwọ́ rẹ̀ tó ṣetán láti sun tùràrí sì bínú. Nígbà tí ó sì ń bínú sí àwọn àlùfáà níwájú wọn, níwájú pẹpẹ tùràrí ní ilé Olúwa, ẹ̀tẹ̀ sì yọ jáde ní iwájú orí rẹ̀. Nígbà tí olórí àlùfáà àti gbogbo àwọn àlùfáà yòókù sì wò ó, wọ́n sì rí i wí pé ó ní ẹ̀tẹ̀ níwájú orí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì sáré gbé e jáde pẹ̀lúpẹ̀lú, òun tìkára rẹ̀ ti fẹ́ láti jáde, nítorí tí Olúwa ti kọlù ú. Ọba sì ní ẹ̀tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Ó sì gbé ní ilé àwọn adẹ́tẹ̀, a sì ké e kúrò ní ilé Olúwa. Jotamu ọmọ rẹ̀ sì gba ipò rẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà. Ìyókù iṣẹ́ ìjọba láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ láti ọwọ́ wòlíì ọmọ . Ussiah sì sùn pẹ̀lú àwọn baba, rẹ̀ a sì sin sí ẹ̀gbẹ́ wọn nínú oko ìsìnkú fún ti iṣẹ́ tí àwọn ọba, nítorí àwọn ènìyàn wí pé “Ó ní ààrùn ẹ̀tẹ̀,” ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
Every verse in 2 Chronicles 26
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.