2 Chronicles 5:3
“Gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli péjọ sí ọ̀dọ̀ ọba ní àkókò àjọ àgọ́.”
2 Chronicles 5:3 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 3 of 14 in 2 Chronicles chapter 5 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
2 Chronicles 5 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Nígbà tí gbogbo iṣẹ́ tí ti ṣe fún tẹmpili Olúwa ti parí, ó kó gbogbo àwọn nǹkan tí baba rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀: wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun èlò ọ̀ṣọ́, ó sì fi wọ́n sínú ìṣúra ilé Ọlọ́run. Nígbà náà ni pe àwọn àgbàgbà ẹli jọ sí ẹmu, gbogbo àwọn olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan àti àwọn olóyè àwọn ìdílé ẹli, kí wọn kí ó gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa gòkè wá láti ìlú . Gbogbo àwọn ọkùnrin ẹli péjọ sí ọ̀dọ̀ ọba ní àkókò àjọ àgọ́. Gbogbo àwọn àgbàgbà ẹli sì wá, àwọn ọmọ gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa. Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí náà gòkè àti àgọ́ ìpàdé àti gbogbo ohun èlò mímọ́ tí ó wà nínú àgọ́. Àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ ni ó mú wọn gòkè wá. Nígbà náà ni ọba àti gbogbo ìjọ ènìyàn ẹli tí ó péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wà níwájú àpótí ẹ̀rí náà wọ́n sì fi àgùntàn àti màlúù tí a kò le è kà tán rú ẹbọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è mọ iye wọn tán nítorí bí wọ́n ti pọ̀ tó. Nígbà náà ni àwọn àlùfáà gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa wá sí ipò rẹ̀, sí ibi inú lọ́hùn ún ilé Olúwa, Ibi Mímọ́ Jùlọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù. Àwọn Kérúbù na ìyẹ́ wọn bo ibi àpótí ẹ̀rí náà àti àwọn ọ̀pá tí ó gbé e ró. Àwọn ọ̀pá rẹ̀ náà gùn tó bẹ́ẹ̀ tí a fi rí orí àwọn ọ̀pá náà láti ibi àpótí ẹ̀rí náà níwájú Mímọ́ náà, ṣùgbọ́n a kò rí wọn lóde. Níbẹ̀ ni ó sì wà títí di òní yìí. Kò sí ohun kan nínú àpótí ẹ̀rí náà bí kò ṣe wàláà méjì tí fi sínú rẹ̀ ní , ní ìgbà tí Olúwa fi bá àwọn ọmọ ẹli dá májẹ̀mú lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde wá láti ilẹ̀ . Lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà jáde wá láti Mímọ́. Gbogbo àwọn àlùfáà tí ó wà níbẹ̀ ni ó ya ara wọn sí mímọ́ láìbìkítà fún ìpín wọn. Gbogbo àwọn ọmọ tí wọ́n jẹ́ akọrin: Asafu, Hemani, Jedutuni àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ẹbí wọn, wọ́n dúró ní igun ìlà-oòrùn pẹpẹ náà wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ tuntun wọ́n ń lo kimbali, dùùrù àti ohun èlò orin olókùn. Ìwọ̀n ọgọ́fà àwọn àlùfáà tí wọ́n ń fun ìpè ni wọ́n tẹ̀lé wọn. Àwọn afùnpè àti àwọn akọrin pa ohùn wọn pọ̀ sí ọ̀kan ṣoṣo, láti fi ìyìn àti ọpẹ́ fun Olúwa. Wọ́n fi ìpè, kimbali àti àwọn ohun èlò orin mìíràn mọ́ ọn, wọ́n gbé ohùn wọn sókè láti fi yin Olúwa, wọ́n ń kọrin pé, “Ó dára; ìfẹ́ rẹ̀ wà títí láéláé.” Nígbà náà ni ìkùùkuu ojú ọ̀run kún inú tẹmpili Olúwa, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn àlùfáà kò le è ṣiṣẹ́ ìsìn wọn nítorí ìkùùkuu náà, nítorí ògo Olúwa kún inú tẹmpili Ọlọ́run.
Every verse in 2 Chronicles 5
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.