2 Kings 16:17

“Ahasi ọba sì gé igi-ìpílẹ̀ àwọn àgbédúró náà, ó ṣí agbada náà kúrò lára wọn; ó sì gbé agbada ńlá náà kalẹ̀ kúrò lára àwọn màlúù idẹ tí ń bẹ lábẹ́ rẹ̀, ó sì gbé e ka ilẹ̀ tí a fi òkúta tẹ́.”

2 Kings 16:17 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 17 of 20 in 2 Kings chapter 16 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

2 Kings 16 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ní ọdún kẹtàdínlógún ọmọ , Ahasi ọmọ ọba bẹ̀rẹ̀ sí i jẹ ọba. Ẹni ogún ọdún ni nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ọdún mẹ́rìndínlógún ní ẹmu, kò sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba ẹli, nítòótọ́, ó sì sun ọmọ rẹ̀ nínú iná, gẹ́gẹ́ bí ohun ìríra àwọn orílẹ̀-èdè, tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ ẹli. Ó sì rú ẹbọ, ó sì sun tùràrí ní àwọn ibi gíga, àti lórí àwọn òkè kéékèèké àti lábẹ́ gbogbo igi tútù. Nígbà náà ni ọba àti ọmọ ọba ẹli gòkè wá sí ẹmu láti jagun: wọ́n dó ti , ṣùgbọ́n wọn kò lè borí rẹ̀. Ní àkókò náà, Resini ọba gba padà fún , ó sì lé àwọn ènìyàn kúrò ní : àwọn ará sì wá sí , wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí. Ahasi sì rán íṣẹ́ sọ́dọ̀ - ọba wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni èmi, àti ọmọ rẹ; gòkè wá, kí o sì gbà mi lọ́wọ́ ọba , àti lọ́wọ́ ọba ẹli tí ó dìde sí mi.” Ahasi sì mú fàdákà àti wúrà tí a rí ní ilé Olúwa, àti nínú ìṣúra ilé ọba, ó sì rán an sí ọba ní ọrẹ. Ọba sì gbọ́ tirẹ̀: nítorí ọba gòkè wá sí , ó sì kó o, ó sì mú un ní ìgbèkùn lọ sí , ó sì pa . Ọba sì lọ sí láti pàdé -, ọba , ó sì rí pẹpẹ kan tí ó wà ní : Ahasi ọba sì rán àwòrán pẹpẹ náà, àti àpẹẹrẹ rẹ̀ sí àlùfáà, gẹ́gẹ́ bí gbogbo iṣẹ́ ọ̀nà rẹ̀. àlùfáà sì kọ́ pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí ọba fi ránṣẹ́ sí i láti ; bẹ́ẹ̀ ni àlùfáà ṣe é dé ìpadàbọ̀ ọba láti . Nígbà tí ọba sì ti dé, ọba sì rí pẹpẹ náà: ọba sì súnmọ́ pẹpẹ náà, ó sì rú ẹbọ lórí rẹ̀. Ó sì sun ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, o si ta ohun mímu rẹ̀ sílẹ̀, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ ọrẹ àlàáfíà rẹ̀ sí ara pẹpẹ náà. Ṣùgbọ́n ó mú pẹpẹ idẹ tí ó wà níwájú Olúwa kúrò láti iwájú ilé náà, láti àárín méjì pẹpẹ náà, àti ilé Olúwa, ó sì fi í sí apá àríwá pẹpẹ náà. Ahasi ọba sì pàṣẹ fún àlùfáà, wí pé, “Lórí pẹpẹ ńlá náà ni kó o máa sun ẹbọ sísun òròwúrọ̀ àti ọrẹ-jíjẹ alaalẹ́, àti ẹbọ sísun ti ọba, àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun tí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọrẹ-jíjẹ wọn, àti ọrẹ ohun mímu wọn; kí o sì wọ́n gbogbo ẹ̀jẹ̀ ẹbọ sísun náà lórí rẹ̀, àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ ẹbọ mìíràn, ṣùgbọ́n ní ti pẹpẹ idẹ náà èmi ó máa gbèrò ohun tí èmi ó fi ṣe.” Báyìí ni àlùfáà ṣe, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ọba pàṣẹ. Ahasi ọba sì gé igi-ìpílẹ̀ àwọn àgbédúró náà, ó ṣí agbada náà kúrò lára wọn; ó sì gbé agbada ńlá náà kalẹ̀ kúrò lára àwọn màlúù idẹ tí ń bẹ lábẹ́ rẹ̀, ó sì gbé e ka ilẹ̀ tí a fi òkúta tẹ́. Ibi ààbò fún ọjọ́ ìsinmi tí a kọ́ nínú ilé náà, àti ọ̀nà ìjáde sí òde ọba, ni ó yípadà kúrò ní ilé Olúwa nítorí ọba . Àti ìyókù ìṣe tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba ? Ahasi sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú : Hesekiah ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Every verse in 2 Kings 16

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00