2 Kings 25:5

“Ṣùgbọ́n ogun àwọn ará Kaldea sì lépa ọba, wọ́n sì lé e bá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì yà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì túká,”

2 Kings 25:5 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 5 of 30 in 2 Kings chapter 25 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

2 Kings 25 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Nígbà tí ó di ọdún kẹsànán ìjọba . Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹwàá, Nebukadnessari ọba yan lọ sí ẹmu pẹ̀lú gbogbo àwọn ogun rẹ̀. Ó sì pàgọ́ sí ìta ìlú ó sì mu àwọn iṣẹ́ ìdọ̀tí fi yí gbogbo rẹ̀ ká. Ìlú náà sì wà ní ìhámọ́ lábẹ́ ìgbóguntì títí di ọdún kọkànlá ti ọba . Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹsànán oṣù kẹrin, ìyàn tí mú ní ìlú tí ó jẹ́ wí pé kò sí oúnjẹ fún àwọn ènìyàn láti jẹ. Nígbà náà odi ìlú náà sì fọ́nká, gbogbo àwọn ọmọ-ogun sálọ ní òru láti ẹnu-ọ̀nà bodè láàrín ògiri méjì ní ẹgbẹ́ ọgbà ọba, àwọn ará wọ́n sì yí ìlú náà ká. Wọ́n sálọ sí ìkọjá . Ṣùgbọ́n ogun àwọn ará sì lépa ọba, wọ́n sì lé e bá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ . Gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì yà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì túká, wọ́n sì mú un. Wọ́n sì mú lọ sí ọ̀dọ̀ ọba ní , níbi tí à ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀. Wọ́n sì pa ọmọ níwájú rẹ̀, wọ́n sì yọ ojú rẹ̀ jáde, wọn dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n idẹ wọ́n sì gbe é lọ sí . Ní ọjọ́ keje ní oṣù karùn-ún, ní ọdún kọkàndínlógún ti ọba , Nebusaradani olórí ẹ̀ṣọ́, ìránṣẹ́ ọba wá sí ẹmu; ó sì finá sí ilé Olúwa, ilé ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà ní ẹmu àti gbogbo ilé ńlá ńlá ni ó dáná sun. Gbogbo àwọn ogun , tí ó wà lọ́dọ̀ olórí ẹ̀ṣọ́, wó ògiri tí ó yí ẹmu ká lulẹ̀. Nebusaradani olórí ẹ̀ṣọ́ kó gbogbo àwọn tálákà àti gbogbo àwọn tí ó kù ní ìlú, ní ìgbèkùn lọ sí , pẹ̀lú àwọn tí ó ya lọ, tí ó sì ya tọ ọba lọ, àti ìyókù àwọn ènìyàn náà. Ṣùgbọ́n olórí ẹ̀ṣọ́ fi àwọn tálákà ènìyàn ilẹ̀ náà sílẹ̀ láti máa bojútó àjàrà àti láti máa ṣe aroko. Àwọn ará fọ́ ọ̀wọ̀n idẹ wọ̀n-ọn-nì àti àwọn ìjókòó wọ̀n-ọn-nì, àti agbada idẹ títóbi wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ilé Olúwa, àwọn ará fọ́ túútúú, wọ́n sì kó idẹ náà lọ sí . Wọ́n sì kó àwọn ìkòkò wọ̀n-ọn-nì, ọkọ́ wọ̀n-ọn-nì, ọ̀pá fìtílà wọ̀n-ọn-nì, síbí wọ̀n-ọn-nì àti gbogbo ohun èlò idẹ wọ̀n-ọn-nì tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ lọ. Olórí ẹ̀ṣọ́ kó ohun ìfọnná wọ̀n-ọn-nì, àti ọpọ́n wọ̀n-ọn-nì, èyí tí wọ́n fi wúrà àti fàdákà ṣe lọ. Àwọn ọ̀wọ́n méjì, agbada ńlá kan, àti ìjókòó wọ̀n-ọn-nì tí ti ṣe fún ilé Olúwa, idẹ ni gbogbo ohun èló wọ̀nyí, ó ju èyí tí a lé wọ́n lọ. Gíga ọ̀wọ́n kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlógún, àti ọnà-orí rẹ̀ idẹ ni: àti gíga ọnà-orí náà ni ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta; àti iṣẹ́ híhun náà, àti àwọn pomegiranate tí ó wà lórí ọnà-orí náà yíká, gbogbo rẹ̀ ti idẹ ni: gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́n yìí sì ni ọ̀wọ́n kejì pẹ̀lú iṣẹ́ híhun. Olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ sì mú gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, Seraiah olórí àwọn àlùfáà, Sefaniah àlùfáà kejì, àti àwọn olùṣọ́ ìloro mẹ́ta. Àti àwọn tí ó kù ní ìlú, ó mú ìwẹ̀fà kan tí ó fi se olórí àwọn ológun, àti ọkùnrin márùn-ún nínú àwọn tó ń gba ọba ní ìmọ̀ràn. Ó sì tún mú akọ̀wé olórí ogun, tí ó ń to àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà àti ọgọ́ta nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú. Nebusaradani, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn tọ ọba wá ní . Níbẹ̀ ní , ní ilẹ̀ , ọba sì kọlù wọ́n. Bẹ́ẹ̀ ni a mú kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀. Nebukadnessari ọba ó mú ọmọ ọmọ Ṣafani, láti jẹ baálẹ̀ lórí àwọn ènìyàn tí ó kù sílẹ̀ ní ilẹ̀ . Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ọkùnrin wọn gbọ́ pé ọba ti yan gẹ́gẹ́ bí baálẹ̀, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ ni . Iṣmaeli ọmọ , Johanani ọmọ , Seraiah ọmọ ará , Jaaṣaniah ọmọ ará , àti àwọn ọkùnrin wọn. Gedaliah sì búra láti fi dá àwọn ènìyàn rẹ̀ lójú. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn ìjòyè ará ,” ó wí pé, “Ẹ máa gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì sin ọba , yóò sì dára fún un yín.” Ní oṣù keje, ni Iṣmaeli ọmọ , ọmọ ṣama, nínú irú-ọmọ ọba, wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá, ó sì kọlù àti pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá ará àti àwọn ará tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní . Nítorí èyí, gbogbo àwọn ènìyàn láti ẹni kékeré títí dé ẹni ńlá, àti pẹ̀lú àwọn olórí ogun, sálọ si nítorí ẹ̀rù àwọn ará . Ní ọdún kẹtàdínlógójì ìgbèkùn ọba , ní oṣù kejìlá, ọjọ́ kẹtàdínlógbọ̀n oṣù, Efili- ọba , ní ọdún tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba, ó gbé orí ọba sókè, ó sì tú sílẹ̀ kúrò nínú túbú. Ó ń sọ̀rọ̀ rere fún un, ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ àwọn ọba tókù lọ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní . Ó sì pàrọ̀ àwọn aṣọ túbú rẹ̀, ó sì ń jẹun ní gbogbo ìgbà ní iwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Ní ojoojúmọ́, ọba fún ní ìpín tirẹ̀ bí ó tí ń bẹ láààyè.

Every verse in 2 Kings 25

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00