2 Samuel 20:8
“Nígbà tí wọ́n dé ibi òkúta ńlá tí ó wà ní Gibeoni, Amasa sì ṣáájú wọn, Joabu sì di àmùrè sí agbádá rẹ̀ tí ó wọ̀, ó sì sán idà rẹ̀ mọ́ ìdí, nínú àkọ̀ rẹ̀, bí ó sì ti ń lọ, ó yọ́ jáde.”
2 Samuel 20:8 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 8 of 26 in 2 Samuel chapter 20 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
2 Samuel 20 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Ọkùnrin kan sì ń bẹ níbẹ̀ orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Ṣeba ọmọ ará ; ó sì fún ìpè ó sì wí pé, “Àwa kò ní ipa nínú , bẹ́ẹ̀ ni àwa kò ni ìní nínú ọmọ ! Kí olúkúlùkù ọkùnrin lọ sí àgọ́ rẹ̀, ẹ̀yin ẹli!” Gbogbo àwọn ọkùnrin ẹli sì lọ kúrò lẹ́yìn , wọ́n sì ń tọ́ Ṣeba ọmọ lẹ́yìn, ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin sì fi ara mọ́ ọba wọn láti odò wá títí ó fi dé ẹmu. Dafidi sì wà ní ilé rẹ̀ ní ẹmu; ọba sì mú àwọn obìnrin mẹ́wàá tí í ṣe àlè rẹ̀, àwọn tí ó ti fi sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ilé, Ó sì há wọn mọ́ ilé, ó sì ń bọ́ wọn, ṣùgbọ́n kò sì tún wọlé tọ̀ wọ́n mọ́. A sì sé wọn mọ́ títí di ọjọ́ ikú wọn, wọ́n sì wà bí opó. Ọba sì wí fún pé, “Pe àwọn ọkùnrin fún mi ní ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta òní, kí ìwọ náà kí o sì wà níhìn-ín yìí.” Amasa sì lọ láti pe àwọn ọkùnrin ; ṣùgbọ́n ó sì dúró pẹ́ ju àkókò tí a fi fún un. Dafidi sì wí fún ṣ pé, “Nísinsin yìí Ṣeba ọmọ yóò ṣe wá ní ibi ju ti lọ; ìwọ mú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ, kí o sì lépa rẹ̀, kí ó má ba à rí ìlú olódi wọ̀, kí ó sì bọ́ lọ́wọ́ wa.” Àwọn ọmọkùnrin sì jáde tọ̀ ọ́ lọ, àti àwọn , àti àwọn , àti gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára, wọ́n sì ti ẹmu jáde lọ, láti lépa Ṣeba ọmọ . Nígbà tí wọ́n dé ibi òkúta ńlá tí ó wà ní , Amasa sì ṣáájú wọn, Joabu sì di àmùrè sí agbádá rẹ̀ tí ó wọ̀, ó sì sán idà rẹ̀ mọ́ ìdí, nínú àkọ̀ rẹ̀, bí ó sì ti ń lọ, ó yọ́ jáde. Joabu sì bi léèrè pé, “Àlàáfíà ha kọ́ ni bí, ìwọ arákùnrin mi?” sì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, di ní irùngbọ̀n mú láti fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Ṣùgbọ́n kò sì kíyèsi idà tí ń bẹ lọ́wọ́ , bẹ́ẹ̀ ni òun sì fi gún un ní ikùn, ìfun rẹ̀ sì tú dà sílẹ̀, òun kò sì tún gún un mọ́, Amasa sì kú. Joabu àti ṣ arákùnrin rẹ̀ sì lépa Ṣeba ọmọ . Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ sì dúró tì , ó sì wí pé, “Ta ni ẹni tí ó fẹ́ràn ? Ta ni ó sì ń ṣe ti , kí ó máa tọ lẹ́yìn.” Amasa sì ń yíràá nínú ẹ̀jẹ̀ láàrín ọ̀nà. Ọkùnrin náà sì rí i pé gbogbo ènìyàn sì dúró tì í, ó sì gbé kúrò lójú ọ̀nà lọ sínú igbó, ó sì fi aṣọ bò ó, nígbà tí ó rí i pé ẹnikẹ́ni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, á dúró. Nígbà tí ó sì gbé kúrò lójú ọ̀nà gbogbo ènìyàn sì tọ lẹ́yìn láti lépa Ṣeba ọmọ . Ṣeba kọjá nínú gbogbo ẹ̀yà ẹli sí --, àti gbogbo àwọn ará ; wọ́n sì kó ara wọn jọ, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pẹ̀lú. Wọ́n wá, wọ́n sì dó tì Ṣeba ní --, wọ́n sì mọ odi ti ìlú náà, odi náà sì dúró ti odi ìlú náà, gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ sì ń gbìyànjú láti wó ògiri náà lulẹ̀. Obìnrin ọlọ́gbọ́n kan sì kígbe sókè láti ìlú náà wá pé, “Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀! Èmi bẹ̀ yín, ẹ sọ fún pé, ‘Súnmọ́ ìhín yìí èmi ó sì bá a sọ̀rọ̀.’ ” Nígbà tí òun sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, obìnrin náà sì wí pé, “Ìwọ ni bí?” Òun sì dáhùn wí pé, “Èmi náà ni.” Obìnrin náà sì wí fún un pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́bìnrin rẹ.” Òun sì dáhùn wí pé, “Èmi ń gbọ́.” Ó sì sọ̀rọ̀ wí pé, “Wọ́n ti ń wí ṣáájú pé, ‘Gba ìdáhùn rẹ ní ,’ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì parí ọ̀ràn náà. Èmi ni ọ̀kan nínú àwọn ẹni àlàáfíà àti olóòtítọ́ ní ẹli, ìwọ ń wá ọ̀nà láti pa ìlú kan run tí ó jẹ́ ìyá ní ẹli, èéṣe tí ìwọ ó fi gbé ìní Olúwa mì.” Joabu sì dáhùn wí pé, “Kí a má rí i, kí a má rí i lọ́dọ̀ mi pé èmi gbé mì tàbí èmi sì parun. Ọ̀ràn náà kò sì rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ọkùnrin kan láti òkè , tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ , ni ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ọba, àní sí : fi òun nìkan ṣoṣo lé wa lọ́wọ́, èmi ó sì fi ìlú sílẹ̀.” Obìnrin náà sì wí fún pé, “Wò ó, orí rẹ̀ ni a ó sì sọ láti inú odi wá.” Obìnrin náà sì mú ìmọ́ràn rẹ̀ tọ gbogbo àwọn ènìyàn náà, wọ́n sì bẹ Ṣeba ọmọ lórí, wọ́n sì sọ ọ́ sí . Òun sì fún ìpè, wọ́n sì túká ní ìlú náà, olúkúlùkù sí àgọ́ rẹ̀. Joabu sí padà lọ sí ẹmu àti sọ́dọ̀ ọba. Joabu sì ni olórí gbogbo ogun ẹli; Benaiah ọmọ sì jẹ́ olórí àwọn , àti ti àwọn . Adoniramu sì jẹ́ olórí àwọn agbowó òde; Jehoṣafati ọmọ sì jẹ́ olùkọsílẹ̀ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní ìlú. Ṣefa sì jẹ́ akọ̀wé; Sadoku àti sì ni àwọn àlùfáà. Ira pẹ̀lú, ará ni ń ṣe àlùfáà lọ́dọ̀ .
Every verse in 2 Samuel 20
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.