2 Samuel 23:7
“Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí yóò tọ́ wọn yóò fi irin àti ọ̀pá ọ̀kọ̀ ṣagbára yí ara rẹ̀ ká; wọ́n ó jóná lúúlúú níbìkan náà.””
2 Samuel 23:7 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 7 of 39 in 2 Samuel chapter 23 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
2 Samuel 23 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ ìkẹyìn . “Dafidi ọmọ , àní ọkùnrin tí a ti gbéga, ẹni àmì òróró Ọlọ́run ọbu, àti olórin dídùn ẹli wí pé, “Ẹ̀mí Olúwa sọ ọ̀rọ̀ nípa mi, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ ní ahọ́n mi. Ọlọ́run ẹli ni, àpáta ẹli sọ fún mi pé, ‘Ẹnìkan ti ń ṣe alákòóso ènìyàn lódodo, tí ń ṣàkóso ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Yóò sì dàbí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn bá là, òwúrọ̀ tí kò ní ìkùùkuu, nígbà tí koríko tútù bá hù wá láti ilẹ̀ lẹ́yìn òjò.’ “Lóòtítọ́ ilé mi kò rí bẹ́ẹ̀ níwájú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó ti bá mi dá májẹ̀mú àìnípẹ̀kun, tí a túnṣe nínú ohun gbogbo, tí a sì pamọ́; nítorí pé gbogbo èyí ni ìgbàlà, àti gbogbo ìfẹ́ mi, ilé mi kò lè ṣe kí ó má dàgbà. Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọ yóò dàbí ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n tí a ṣá tì, nítorí pé a kò lè fi ọwọ́ kó wọn. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí yóò tọ́ wọn yóò fi irin àti ọ̀pá ọ̀kọ̀ ṣagbára yí ara rẹ̀ ká; wọ́n ó jóná lúúlúú níbìkan náà.” Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn akọni ọkùnrin tí ní: Joṣebu-ṣebeti ará ni olórí àwọn balógun, òun sì ni akọni rẹ̀ tí ó pa ẹgbẹ̀rin (800) ènìyàn lẹ́ẹ̀kan náà. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni ọmọ ará , ọ̀kan nínú àwọn alágbára ọkùnrin mẹ́ta ti ó wà pẹ̀lú , nígbà tí wọ́n pe àwọn ní ìjà, àwọn ọkùnrin ẹli sì ti lọ kúrò. Òun sì dìde, ó sì kọlu àwọn títí ọwọ́ fi kún un, ọwọ́ rẹ̀ sì lẹ̀ mọ́ idà; Olúwa sì ṣiṣẹ́ ìgbàlà ńlá lọ́jọ́ náà, àwọn ènìyàn sì padà bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ láti kó ìkógun. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Ṣamma ọmọ ará , àwọn sì kó ara wọn jọ láti piyẹ́, oko kan sì wà níbẹ̀ tí ó kún fun lẹntili, àwọn ọmọ-ogun ẹli sì sá kúrò níwájú àwọn . Ṣamma sì dúró láàrín méjì ilẹ̀ náà, ó sì gbà á sílẹ̀, ó sì pa àwọn Olúwa sì ṣe ìgbàlà ńlá. Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n ìjòyè sọ̀kalẹ̀, wọ́n sì tọ wá ní àkókò ìkórè nínú ihò , ọ̀wọ́ àwọn sì dó sí àfonífojì . Dafidi sì wà nínú odi, ibùdó àwọn sì wà ní Bẹtilẹhẹmu nígbà náà. Dafidi sì ń pòǹgbẹ, ó wí báyìí pé, “Ta ni yóò fún mi mu nínú omí kànga tí ń bẹ ní Bẹtilẹhẹmu, èyí tí ó wà ní ìhà ẹnu-bodè.” Àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta sì la ogún àwọn lọ, wọ́n sì fa omi láti inú kànga Bẹtilẹhẹmu wá, èyí tí ó wà ní ìhà ẹnu-bodè, wọ́n sì mú tọ wá, òun kò sì fẹ́ mu nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tú u sílẹ̀ fún Olúwa. Òun sì wí pé, “Kí a má rí, Olúwa, tí èmi ó fi ṣe èyí; ṣé èyí ni ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkùnrin tí ó lọ tí àwọn tí ẹ̀mí wọn lọ́wọ́?” Nítorí náà òun kò sì fẹ́ mú un. Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ṣe. Abiṣ, arákùnrin , ọmọ , òun náà ni pàtàkì nínú àwọn mẹ́ta. Òun ni ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè sí ọ̀ọ́dúnrún (300) ènìyàn, ó sì pa wọ́n, ó sì ní orúkọ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ọlọ́lá jùlọ ni òun jẹ́ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ó sì jẹ́ olórí fún wọn, ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ìṣáájú. Benaiah, ọmọ , ọmọ akọni ọkùnrin kan tí ṣeeli, ẹni tí ó pọ̀ ní iṣẹ́ agbára, òun pa àwọn ọmọ méjì ti ; ó sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ó sì pa kìnnìún kan nínú ihò lákoko òjò-dídì. Ó sì pa ará kan, ọkùnrin tí ó dára láti wò, ará náà sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́, ó sì gba ọ̀kọ̀ náà lọ́wọ́ ará náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa á. Nǹkan wọ̀nyí ní ọmọ ṣe, ó sì ní orúkọ nínú àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta náà. Nínú àwọn ọgbọ̀n náà, òun ní ọlá jùlọ, ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ti ìṣáájú. Dafidi sì fi í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn ọgbọ̀n náà: Asaheli arákùnrin sì Jásí ọmọ ti Bẹtilẹhẹmu; Ṣamma ará , Elika ará . Helesi ará , Ira ọmọ Ikẹsi ará ; Abieseri ará , Sibekai ará Huṣati; Salmoni ará , Maharai ará ; Heledi ọmọ , ará , Ittai ọmọ to ti àwọn ọmọ ; Benaiah ará , Hiddai ti àfonífojì ṣi, Abi- ará , Asmafeti ; Eliaba ará Ṣaalboni, àwọn ọmọ Jaṣeni, Jonatani; ọmọ Ṣamma ará , Ahiamu ọmọ Ṣarari ará ; Elifeleti ọmọ , ọmọ ará , Eliamu ọmọ ará ; Hesro ará , Paarai ará ; Igali ọmọ ti , Bani ará ; Seleki ará , Naharai ará , ẹni tí ń ru ìhámọ́ra ọmọ ; Ira ará , Garebu ará . ará . Gbogbo wọn jẹ́ mẹ́tàdínlógójì.
Every verse in 2 Samuel 23
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.