Acts 20:21

“Tí mo ń sọ fún àwọn Júù, àti fún àwọn Giriki pẹ̀lú, ní ti ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run, àti ti ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi Olúwa wa.”

Acts 20:21 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 21 of 38 in Acts chapter 20 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Acts 20 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Nígbà tí ariwo náà sí rọlẹ̀, Paulu ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú, ó dágbére fún wọn, ó dìde láti lọ sí . Nígbà tí ó sì tí la apá ìhà wọ̀nyí kọjá, tí ó sì ti fi ọ̀rọ̀ púpọ̀ gbà wọ́n ní ìyànjú, ó wá sí ilẹ̀ . Ó sì dúró níbẹ̀ ní oṣù mẹ́ta, nígbà tí àwọn Júù sì dènà dè é, bí ó ti ń pète àti bá ọkọ̀ ojú omi lọ sí , ó pinnu rẹ̀ láti gbà padà lọ. Sopateru ará ọmọ sì bá a lọ dé , àti nínú àwọn ará Tẹsalonika, Aristarku àti , àti ará , àti ; Tikiku àti ará . Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí tí lọ síwájú, wọ́n dúró dè wá ni . Àwa sì ṣíkọ̀ láti lọ lẹ́yìn àjọ àìwúkàrà, a sì dé ọ̀dọ̀ wọn ní ni ọjọ́ méje. Ọjọ́ èkínní ọ̀sẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn péjọ láti bu àkàrà, Paulu sì wàásù fún wọn, ó múra láti lọ ní ọjọ́ kejì: ó sì fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ gùn títí di àárín ọ̀gànjọ́. Fìtílà púpọ̀ sì wà ní iyàrá òkè náà, níbi tí wọn gbé péjọ sí. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí a ń pè ní sì jókòó lójú fèrèsé, oorun sì wọ̀ ọ́ lára; bí sì ti pẹ́ ní ìwàásù, ó ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lójú oorun, ó ṣubú láti òkè kẹta wá sílẹ̀, a sì gbé e dìde ní òkú. Nígbà tí sì sọ̀kalẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ tì i, ó sì gbé e mọ́ra, ó ní, “Ẹ má ṣe yọ ara yín lẹ́nu; nítorí tí òun wà láààyè.” Nígbà tí ó sì tún gòkè lọ, ó sì jẹ oúnjẹ Olúwa, ó sì sọ̀rọ̀ pẹ́ títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́, nígbà náà ni ó sì lọ. Wọ́n sì mú ọmọkùnrin náà lọ sílẹ̀ láààyè, inú gbogbo wọn sì dùn lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Nígbà ti àwa sì ṣáájú, àwa sì ṣíkọ̀ lọ sì , níbẹ̀ ni a ti lérò láti gba sínú ọkọ̀: nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó tí pinnu rẹ̀, òun tìkára rẹ̀ ń fẹ́ bá ti ọ̀nà-ẹsẹ̀ lọ. Nígbà tí ó sì pàdé wa ní , a gbà á sínú ọkọ̀, a sì wá sí . Nígbà tí a sì ṣíkọ̀ kúrò níbẹ̀, ní ọjọ́ kejì a dé ọ̀kánkán ; ní ọjọ́ kejì rẹ̀ a dé , ni ọjọ́ kejì rẹ̀ a sì dé . Paulu ṣa ti pinnu rẹ̀ láti bá ọkọ̀ ojú omi kọjá sí , nítorí ki ó má ba à lo àkókò kankan ni : nítorí tí ó ń yára bí yóò ṣe ṣe é ṣe fún un láti wà ní ẹmu lọ́jọ́ . Ní àti ni ti ránṣẹ́ sí , láti pé àwọn alàgbà ìjọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tìkára yín mọ̀, láti ọjọ́ kìn-ín-ní tí mo tí dé , bí mo ti bá yín gbé, ní gbogbo àkókò náà. Bí mo ti ń fi ìrẹ̀lẹ̀ inú gbogbo sin Olúwa, àti omijé púpọ̀, pẹ̀lú ìdánwò, tí ó bá mi, nípa rìkíṣí àwọn Júù. Bí èmí kò ti fàsẹ́yìn láti sọ ohunkóhun tí ó ṣàǹfààní fún un yín, àti láti máa kọ́ ọ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé. Tí mo ń sọ fún àwọn Júù, àti fún àwọn pẹ̀lú, ní ti ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run, àti ti ìgbàgbọ́ nínú Olúwa wa. “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, wò ó, ẹ̀mí mi ń fà sì ẹmu, láìmọ̀ ohun tí yóò bá mi níbẹ̀. Bí kò ṣe bí Ẹ̀mí Mímọ́ tí ń sọ ní ìlú gbogbo pé, ìdè àti ìyà ń bẹ fún mi. Ṣùgbọ́n èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan rárá bi ohun tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí mo tí gbà lọ́dọ̀ Olúwa, láti máa ròyìn ìyìnrere oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, wò ó, èmi mọ̀ pé gbogbo yín, láàrín ẹni tí èmi tí ń wàásù ìjọba Ọlọ́run, kì yóò rí ojú mi mọ́. Nítorí náà mo pè yín ṣe ẹlẹ́rìí lónìí yìí pé, ọrùn mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbogbo. Nítorí tí èmi kò fàsẹ́yìn láti sọ gbogbo ìpinnu Ọlọ́run fún un yin. Ẹ kíyèsára yin, àti sí gbogbo agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alábojútó rẹ̀, láti máa tọ́jú ìjọ Ọlọ́run, tí ó tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ rà. Nítorí tí èmi mọ̀ pé, lẹ́yìn lílọ mi, ìkookò búburú yóò wọ àárín yín, yóò sì tú agbo ká. Láàrín ẹ̀yin tìkára yín ni àwọn ènìyàn yóò sì dìde, tí wọn yóò máa sọ̀rọ̀-òdì, láti fa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sẹ́yìn wọn. Nítorí náà ẹ máa ṣọ́ra, ki ẹ sì máa rántí pé, fún ọdún mẹ́ta, èmi kò dẹ́kun láti máa fi omijé kìlọ̀ fún olúkúlùkù ní ọ̀sán àti ní òru. “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ará, mo fi yín lé Ọlọ́run lọ́wọ́ àti ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, tí ó lè gbé yín dúró, tí ó sì lè fún yín ní ìní láàrín gbogbo àwọn tí a sọ di mímọ́. Èmí kò ṣe ojúkòkòrò fàdákà, tàbí wúrà, tàbí aṣọ ẹnikẹ́ni. Ẹ̀yin tìkára yín sá à mọ̀ pé, ọwọ́ mi wọ̀nyí ni mo fi ṣiṣẹ́ láti fi pèsè fún àìní mi, àti tí àwọn tí ó wà pẹ̀lú mi. Nínú ohun gbogbo mo fi àpẹẹrẹ fún un yín pé, nípa ṣíṣe iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ki ẹ sì máa rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí òun tìkára rẹ̀ tí wí pé, ‘Láti fún ni ní ìbùkún ju láti gbà lọ.’ ” Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, ó kúnlẹ̀, ó sì bá gbogbo wọn gbàdúrà. Gbogbo wọn sì sọkún gidigidi, wọ́n sì rọ̀ mọ́ lọ́rùn, wọ́n sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Inú wọn sì bàjẹ́ jùlọ fún ọ̀rọ̀ tí ó sọ pé, wọn kì yóò rí ojú òun mọ́, wọ́n sì sìn ín títí dé inú ọkọ̀.

Every verse in Acts 20

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00