Amos 1:3

“Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Damasku, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọn fi ohun èlò ìpakà pa Gileadi. Pẹ̀lú ohun èlò irin tí ó ní eyín mímú,”

Amos 1:3 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 3 of 15 in Amos chapter 1 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Amos 1 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Àwọn ọ̀rọ̀ , ọ̀kan lára àwọn olùṣọ́-àgùntàn ; ohun tí o rí nípa ẹli ní ọdún méjì ṣáájú ilẹ̀-rírì, nígbà tí ọba àti ọmọ ṣi jẹ́ ọba ní ilẹ̀ ẹli. Ó wí pé, “Olúwa yóò bú jáde láti , ohùn rẹ̀ yóò sì sán bí àrá láti ẹmu wá; ibùgbé àwọn olùṣọ́-àgùntàn yóò sì ṣọ̀fọ̀, orí òkè yóò sì rọ.” Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí , àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọn fi ohun èlò ìpakà pa . Pẹ̀lú ohun èlò irin tí ó ní eyín mímú, Èmi yóò rán iná sí ilé , èyí ti yóò jó àwọn ààfin - run. Èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá ìdábùú ; Èmi yóò sì pa ọba tí ó wà ní àfonífojì run àti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé mú ní -. Àwọn ará a yóò lọ sí ìgbèkùn sí ,” ni Olúwa wí. Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta , àní nítorí mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Gẹ́gẹ́ bí í íṣòwò ẹrú, ó kó gbogbo àwọn ènìyàn mi ní ìgbèkùn. Ó sì tà wọ́n fún , Èmi yóò rán iná sí ara odi tí yóò jó gbogbo ààfin rẹ̀ run. Èmi yóò ké àwọn olùgbé Aṣdodu kúrò, ti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé ní Aṣkeloni mú. Èmi yóò yí ọwọ́ mi sí títí tí ìyókù yóò fi ṣègbé,” ni Olúwa Olódùmarè wí. Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti àní nítorí mẹ́rin, Èmi kì yóò yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọ́n ta gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìgbèkùn fún . Wọn kò sì náání májẹ̀mú ọbàkan, Èmi yóò rán iná sí ara odi , tí yóò jó gbogbo àwọn ààfin rẹ̀ run.” Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí , àní nítorí mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí òhun fi idà lépa arákùnrin rẹ̀, Ó sì gbé gbogbo àánú sọnù, ìbínú rẹ̀ sì ń faniya títí, ó sì pa ìbínú rẹ̀ bí èéfín mọ́, Èmi yóò rán iná sí orí , tí yóò jó gbogbo ààfin run.” Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti , àní mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọn ti la inú àwọn aboyún kí wọ́n ba à lè fẹ ilẹ̀ wọn sẹ́yìn. Èmi yóò rán iná sí ara odi èyí tí yóò jó àwọn ààfin rẹ̀ run pẹ̀lú ìhó ayọ̀ ní ọjọ́ ogun, pẹ̀lú ìjì líle ni ọjọ́ àjà. Ọba wọn yóò sì lọ sí ìgbèkùn, òun àti àwọn ọmọ-aládé rẹ̀ lápapọ̀,” ni Olúwa wí.

Every verse in Amos 1

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00