Amos 2:7
“Wọ́n fi ẹsẹ̀ tẹ orí àwọn tálákà mọ́lẹ̀, bí wọ́n ti ń tẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ tí wọ́n ko sì ṣe òtítọ́ si àwọn tí a ni lára. Baba àti ọmọ ń wọlé tọ wúńdíá kan náà, láti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́.”
Amos 2:7 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 7 of 16 in Amos chapter 2 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Amos 2 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti , àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà, nítorí ó ti sun ún, di eérú, egungun ọba , Èmi yóò rán iná sí orí èyí tí yóò jó àwọn ààfin run. Moabu yóò sì kú pẹ̀lú ariwo pẹ̀lú igbe àti pẹ̀lú ìró ìpè. Èmi yóò ké ídàájọ́ rẹ̀ kúrò, Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn ọmọ-aládé rẹ́ nínú rẹ̀,” ni Olúwa wí. Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti , àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọn ti kọ òfin Olúwa sílẹ̀, wọn kò sì pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́. Nítorí àwọn òrìṣà ti sì wọ́n lọ́nà, òrìṣà tí àwọn ńlá wọn ń tẹ̀lé, Èmi yóò rán iná sí orí èyí tí yóò jó àwọn ààfin ẹmu run.” Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ẹli àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Wọ́n ta olódodo fún fàdákà àti aláìní fún bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì. Wọ́n fi ẹsẹ̀ tẹ orí àwọn tálákà mọ́lẹ̀, bí wọ́n ti ń tẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ tí wọ́n ko sì ṣe òtítọ́ si àwọn tí a ni lára. Baba àti ọmọ ń wọlé tọ wúńdíá kan náà, láti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́bàá a pẹpẹ, lórí aṣọ tí wọ́n fi jẹ́ ẹ̀jẹ́ ní ilé òrìṣà wọn wọ́n sì mu ọtí tí wọ́n san fún ìtánràn. “Mo pa àwọn ará run níwájú wọn gíga ẹni tí ó dàbí igi kedari. Òun sì le koko bí igi óákù mo pa èso rẹ̀ run láti òkè wá àti egbò rẹ̀ láti ìsàlẹ̀ wá. Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ wá, mo sì sìn yín la aginjù já ní ogójì ọdún láti fi ilẹ̀ àwọn ará fún un yín. “Èmi sì tún gbé àwọn wòlíì dìde láàrín àwọn ọmọ yín àti láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín láti jẹ èyí kò ha jẹ́ òtítọ́ bí ará ẹli?” ni Olúwa wí. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin fún àwọn ní ọtí mu e sì pàṣẹ fún àwọn wòlíì kí wọ́n má ṣe sọtẹ́lẹ̀. “Ní báyìí, èmi yóò tẹ̀ yín mọ́lẹ̀ bí kẹ̀kẹ́ tí ó kún fún ìtí ti í tẹ̀. Ẹni tí ó yára bí àṣá kò ní rí ọ̀nà àbáyọ alágbára kò ní le è dúró lé agbára rẹ̀ jagunjagun kì yóò le gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là. Tafàtafà kì yóò dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó gún ẹṣin kì yóò gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là. Àní jagunjagun tí ó gbóyà jùlọ yóò sálọ ní ìhòhò ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí.
Every verse in Amos 2
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.