Amos 3:14

““Ní ọjọ́ tí mo fìyà jẹ Israẹli lórí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, Èmi yóò pa pẹpẹ Beteli run; ìwo pẹpẹ ni a ó ké kúrò yóò sì wó lulẹ̀.”

Amos 3:14 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 14 of 15 in Amos chapter 3 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Amos 3 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn ẹli nípa àwọn ìdílé tí mo mú jáde láti : “Ìwọ nìkan ni ẹni tí mo yàn nínú gbogbo àwọn ìran ayé yìí; nígbà náà èmi ó jẹ ọ́ ní yà fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.” Ẹni méjì ha à le rìn pọ̀ láìjẹ́ pé wọ́n ti pinnu láti ṣe bẹ? Ǹjẹ́ Kìnnìún yóò ha bú úù nínú igbó, bí kò bá ní ohun ọdẹ? Ọmọ kìnnìún yóò ha ké jáde nínú ìhó rẹ̀ bí kò bá rí ohun kan mú? Ǹjẹ́ ẹyẹ ṣubú sínú okùn ọdẹ lórí ilẹ̀ nígbà tí a kò dẹ okùn ọdẹ fún un? Okùn ọdẹ ha lè hù jáde lórí ilẹ̀ nígbà tí kò sí ohun tí yóò mú? Nígbà tí ìpè bá dún ní ìlú, àwọn ènìyàn kò ha bẹ̀rù? Tí ewu bá wa lórí ìlú kò ha ṣe Olúwa ni ó fà á? Nítòótọ́ Olúwa Olódùmarè kò ṣe ohun kan láìfi èrò rẹ̀ hàn fun àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀. Kìnnìún ti bú úù ta ni kì yóò bẹ̀rù? Olúwa Olódùmarè ti sọ̀rọ̀ ta ni le ṣe àìsọ àsọtẹ́lẹ̀? Ẹ kéde ní ààfin Aṣdodu àti ní ààfin ní ilẹ̀ . “Ẹ kó ara yín jọ sí orí òkè ńlá ; kí ẹ sì wo ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láàrín rẹ̀ àti ìnilára láàrín àwọn ènìyàn rẹ.” “Wọn kò mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe rere,” ni Olúwa wí, “àwọn ẹni tí ó gba àwọn ìwà ipá àti olè sí ààfin rẹ̀.” Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “Àwọn ọ̀tá yóò pa ilẹ̀ náà run; yóò wó ibi gíga yín palẹ̀ a ó sì ba ààfin rẹ̀ jẹ́.” Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Bí olùṣọ́-àgùntàn ti ń gbà itan méjì kúrò ní ẹnu kìnnìún tàbí ẹ̀là etí kan bẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ ẹli, tí ń gbé kúrò ní igun ibùsùn wọn ní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní .” “Gbọ́ èyí kí o sì jẹ́rìí nípa ilé ọbu,” ni Olúwa wí, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. “Ní ọjọ́ tí mo fìyà jẹ ẹli lórí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, Èmi yóò pa pẹpẹ run; ìwo pẹpẹ ni a ó ké kúrò yóò sì wó lulẹ̀. Èmi yóò wó ilé òtútù lulẹ̀ pẹ̀lú ilé ooru; ilé tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ yóò ṣègbé a ó sì pa ilé ńlá náà run,” ni Olúwa wí.

Every verse in Amos 3

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00