Amos 6:12
“Ǹjẹ́ ẹṣin a máa sáré lórí àpáta bí? Ǹjẹ́ ènìyàn a máa fi akọ màlúù kọ ilẹ̀ níbẹ̀? Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yí òtítọ́ padà sí májèlé ẹ sì ti sọ èso òdodo di ìkorò.”
Amos 6:12 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 12 of 14 in Amos chapter 6 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Amos 6 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ará rọ̀ ní àti ẹ̀yin tí ẹ wà ní abẹ́ ààbò ní òkè àti ẹ̀yin olókìkí orílẹ̀-èdè tí ẹ̀yin ènìyàn ẹli máa ń tọ̀ ọ́ wá. Ẹ lọ kí ẹ lọ wò ó kí ẹ sí tí ibẹ̀ lọ sí ìlú ńlá a nì. Kí ẹ sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ ní ilẹ̀ . Ǹjẹ́ wọ́n ha dára ju ìpínlẹ̀ yín méjèèjì lọ? Ǹjẹ́ a ha rí ilẹ̀ tó tóbi ju tiyín lọ bí? Ẹ̀yin sún ọjọ́ ibi síwájú, ẹ sì mú ìjọba òǹrorò súnmọ́ tòsí. Ẹ̀yin sùn lé ibùsùn tí a fi eyín erin ṣe ẹ sì tẹ́ ara sílẹ̀ ni orí àwọn ibùsùn ẹyin pa èyí tí o dára nínú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yín jẹ ẹ sì ń pa àwọn ọ̀dọ́ màlúù láàrín agbo wọn jẹ. Ẹ̀yin ń lo ohun èlò orin bí i ẹ sì ń ṣe àwọn àpilẹ̀rọ àwọn ohun èlò orin. Ẹ̀yin mu wáìnì ẹ̀kún ọpọ́n kan àti ìkunra tí o dára jùlọ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò káàánú ilé ẹfu tí ó di ahoro. Nítorí náà, àwọn ni yóò lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn tí ó ti kó lọ sí ìgbèkùn àsè àwọn tí ń ṣe àṣelékè ni a ó mú kúrò. Olúwa Olódùmarè ti búra fúnra rẹ̀, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì ti wí pé: “Mo kórìíra ìgbéraga ọbu n kò sì ní inú dídùn sí odi alágbára rẹ̀, Èmi yóò sì fa ìlú náà lé wọn lọ́wọ́ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.” Bí ọkùnrin mẹ́wàá bá ṣẹ́kù nínú ilé kan, àwọn náà yóò kú. Bí ẹbí tí ó yẹ kí ó gbé òkú wọn jáde fún sínsin bá wọlé, bí o ba sì béèrè pé ǹjẹ́ ẹnìkan wa tí ó fi ara pamọ́ níbẹ̀, “Ǹjẹ́ ẹnìkankan wà lọ́dọ̀ yín?” tí ó bá sì dáhùn wí pé, “Rárá,” nígbà náà ni yóò wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́ àwa kò gbọdọ̀ dárúkọ Olúwa.” Nítorí Olúwa tí pa àṣẹ náà, Òun yóò sì wó ilé ńlá náà lulẹ̀ túútúú, àti àwọn ilé kéékèèké sí wẹ́wẹ́. Ǹjẹ́ ẹṣin a máa sáré lórí àpáta bí? Ǹjẹ́ ènìyàn a máa fi akọ màlúù kọ ilẹ̀ níbẹ̀? Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yí òtítọ́ padà sí májèlé ẹ sì ti sọ èso òdodo di ìkorò. Ẹ̀yin yọ̀ torí ìṣẹ́gun lórí Lo-, ẹ̀yin sì wí pé, “Ṣé kì í ṣe agbára wa ni àwa fi gba ?” Nítorí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Èmi yóò gbé orílẹ̀-èdè kan dìde sí ọ ìwọ ẹli, wọn yóò pọ́n yín lójú ní gbogbo ọ̀nà, láti -, títí dé pẹ̀tẹ́lẹ̀ .”
Every verse in Amos 6
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.