Deuteronomy 33:10
“Ó kọ́ Jakọbu ní ìdájọ́ rẹ̀ àti Israẹli ní òfin rẹ̀. Ó mú tùràrí wá síwájú rẹ̀ àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹbọ sísun sórí i pẹpẹ rẹ̀.”
Deuteronomy 33:10 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 10 of 29 in Deuteronomy chapter 33 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Deuteronomy 33 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Èyí ni ìbùkún tí ènìyàn Ọlọ́run bùkún fún àwọn ọmọ ẹli kí ó tó kú. Ó sì wí pé, “Olúwa ti wá, ó sì yọ sí wọn láti wá ó sì tàn án jáde láti òkè wá. Ó ti ọ̀dọ̀ ẹgbẹgbàarùn-ún àwọn mímọ́ wá láti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni òfin kan a mú bí iná ti jáde fún wọn wá. Nítòótọ́, ó fẹ́ràn àwọn ènìyàn an rẹ̀, gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ wà ní ọwọ́ rẹ̀. Ní ẹsẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti foríbalẹ̀, àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti ń gba ọ̀rọ̀, òfin tí fi fún wa, ìní ti ìjọ ènìyàn ọbu. Òun ni ọba lórí Jeṣuruni ní ìgbà tí olórí àwọn ènìyàn péjọpọ̀, pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà ẹli. “Jẹ́ kí yè kí ó má ṣe kú, tàbí kí ènìyàn rẹ mọ níwọ̀n.” Èyí ni ohun tí ó sọ nípa : “Olúwa gbọ́ ohùn kí o sì mú tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ wá. Kí ọwọ́ rẹ̀ kí ó tó fún un, kí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀!” Ní ti ó wí pé, “Jẹ́ kí àti rẹ kí ó wà pẹ̀lú ẹni mímọ́ rẹ. Ẹni tí ó dánwò ní , ìwọ bá jà ní omi . Ó wí fún baba àti ìyá rẹ pé, ‘Èmi kò buyì fún wọn.’ Kò mọ àwọn arákùnrin rẹ̀, tàbí mọ àwọn ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́. Ó kọ́ ọbu ní ìdájọ́ rẹ̀ àti ẹli ní òfin rẹ̀. Ó mú tùràrí wá síwájú rẹ̀ àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹbọ sísun sórí i pẹpẹ rẹ̀. Bùsi ohun ìní rẹ̀, Olúwa, kí o sì tẹ́wọ́gbà iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Lu ẹgbẹ́ àwọn tí ó dìde sí i; àwọn tí ó kórìíra rẹ̀, kí wọn kí ó má ṣe dìde mọ́.” Ní ti ó wí pé, “Jẹ́ kí olùfẹ́ Olúwa máa gbé ní àlàáfíà lọ́dọ̀ rẹ̀, òun a máa bò ó ní gbogbo ọjọ́, ẹni tí Olúwa fẹ́ràn yóò máa sinmi láàrín èjìká rẹ̀.” Ní ti ẹfu ó wí pé, “Kí Olúwa bùkún ilẹ̀ rẹ, fún ohun iyebíye láti ọ̀run pẹ̀lú ìrì àti ibú tí ó ń bẹ níṣàlẹ̀; àti fún èso iyebíye tí ọ̀run mú wá àti ti ohun iyebíye tí ń dàgbà ní oṣooṣù; pẹ̀lú ohun pàtàkì òkè ńlá ìgbàanì àti fún ohun iyebíye ìgbà ayérayé; Pẹ̀lú ohun iyebíye ayé àti ẹ̀kún un rẹ̀ àti fún ìfẹ́ ẹni tí ó ń gbé inú igbó. Jẹ́ kí gbogbo èyí sinmi lé orí ẹfu, lórí àtàrí ẹni tí ó yàtọ̀ láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀. Ní ọláńlá ó dàbí àkọ́bí akọ màlúù; ìwo rẹ̀, ìwo àgbáǹréré ni. Pẹ̀lú wọn ni yóò fi ti àwọn orílẹ̀-èdè, pàápàá títí dé òpin ayé. Àwọn sì ni ẹgbẹẹgbàárùn mẹ́wàá , àwọn sì ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún .” Ní ti ó wí pé, “Yọ̀ , ní ti ìjáde lọ rẹ, àti ìwọ , nínú àgọ́ rẹ. Wọn yóò pe àwọn ènìyàn sórí òkè àti níbẹ̀ wọn yóò rú ẹbọ òdodo, wọn yóò mu nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òkun, nínú ìṣúra tí ó pamọ́ nínú iyanrìn.” Ní ti ó wí pé, “Ìbùkún ni ẹni tí ó mú gbilẹ̀! Gadi ń gbé níbẹ̀ bí kìnnìún, ó sì fa apá ya, àní àtàrí. Ó sì yan ilẹ̀ tí ó dára jù fún ara rẹ̀; ìpín olórí ni a sì fi fún un. Nígbà tí ó rí tí gbogbo àwọn ènìyàn péjọ, ó mú òdodo Olúwa ṣẹ, àti ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹli.” Ní ti ó wí pé, “Ọmọ kìnnìún ni , tí ń fò láti Baṣani wá.” Ní ti ó wí pé, “Ìwọ , kún fún ojúrere Ọlọ́run àti ìbùkún Olúwa; yóò jogún ìhà ìwọ̀-oòrùn àti gúúsù.” Ní ti Aṣeri ó wí pé, “Ìbùkún ọmọ ni ti Aṣeri; jẹ́ kí ó rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ kí ó sì ri ẹsẹ̀ rẹ̀ sínú òróró. Bàtà rẹ̀ yóò jẹ́ irin àti idẹ, agbára rẹ̀ yóò sì rí bí ọjọ́ rẹ̀. “Kò sí ẹlòmíràn bí Ọlọ́run Jeṣuruni, ẹni tí ń gun ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́ rẹ àti ní ojú ọ̀run nínú ọláńlá rẹ̀. Ọlọ́run ayérayé ni ibi ìsádi rẹ, àti ní ìsàlẹ̀ ni apá ayérayé wà. Yóò lé àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ, ó sì wí pé, ‘Ẹ máa parun!’ Israẹli nìkan yóò jókòó ní àlàáfíà, orísun ọbu nìkan ní ilẹ̀ ọkà àti ti ọtí wáìnì, níbi tí ọ̀run ti ń sẹ ìrì sílẹ̀. Ìbùkún ni fún ọ, Israẹli, ta ni ó dàbí rẹ, ẹni tí a gbàlà láti ọ̀dọ̀ Olúwa? Òun ni asà àti ìrànwọ́ rẹ̀ àti idà ọláńlá rẹ̀. Àwọn ọ̀tá rẹ yóò tẹríba fún ọ, ìwọ yóò sì tẹ ibi gíga wọn mọ́lẹ̀.”
Every verse in Deuteronomy 33
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.