Ecclesiastes 6:8

“Kí ni àǹfààní tí ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní lórí aṣiwèrè? Kí ni èrè tálákà ènìyàn nípa mímọ bí yóò ṣe hùwà níwájú àwọn tókù?”

Ecclesiastes 6:8 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 8 of 12 in Ecclesiastes chapter 6 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Ecclesiastes 6 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Mo ti rí ibi mìíràn lábẹ́ oòrùn. Ọlọ́run fún ọkùnrin kan ní ọrọ̀, ọlá àti ọlà kí ó má ba à ṣe aláìní ohunkóhun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kò fún un ní àǹfààní láti gbádùn wọn, dípò èyí, àlejò ni ó ń gbádùn wọn. Asán ni èyí, ààrùn búburú gbá à ni. Ọkùnrin kan le è ní ọgọ́rùn-ún ọmọ kí ó sì wà láààyè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, síbẹ̀ kò sí bí ó ti le wà láààyè pẹ́ tó, bí kò bá le è gbádùn ohun ìní rẹ̀ kí ó sì gba ìsìnkú tí ó tọ́, mo sọ wí pé ọlẹ̀ ọmọ tí a sin sàn jù ú lọ. Ó wà láìní ìtumọ̀, ó lọ nínú òkùnkùn, nínú òkùnkùn sì ni orúkọ rẹ̀ fi ara pamọ́ sí. Bí ó ti jẹ́ wí pé kò rí oòrùn tàbí mọ ohunkóhun, ó ní ọ̀pọ̀ ìsinmi ju ti ọkùnrin náà lọ. Kódà, bí ó wà láààyè fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún méjì yípo ṣùgbọ́n tí ó kùnà láti gbádùn ohun ìní rẹ̀. Kì í ṣe ibìkan ni gbogbo wọn ń lọ? Gbogbo wàhálà tí ènìyàn ń ṣe nítorí àtijẹ ni síbẹ̀ ikùn rẹ̀ kò yó rí. Kí ni àǹfààní tí ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní lórí aṣiwèrè? Kí ni èrè tálákà ènìyàn nípa mímọ bí yóò ṣe hùwà níwájú àwọn tókù? Ohun tí ojú rí sàn ju ìfẹnuwákiri lọ. Asán ni eléyìí pẹ̀lú ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́. Ohunkóhun tí ó bá ti wà ti ní orúkọ, ohun tí ènìyàn jẹ́ sì ti di mí mọ̀; kò sí ènìyàn tí ó le è ja ìjàkadì pẹ̀lú ẹni tí ó lágbára jù ú lọ. Ọ̀rọ̀ púpọ̀, kì í ní ìtumọ̀ èrè wo ni ènìyàn ń rí nínú rẹ̀? Àbí, ta ni ó mọ ohun tí ó dára fún ènìyàn ní ayé fún ọjọ́ ayé kúkúrú àti asán tí ó ń là kọjá gẹ́gẹ́ bí òjìji? Ta ni ó le è sọ fún mi, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn lẹ́yìn tí ó bá lọ tán? Kò sí!

Every verse in Ecclesiastes 6

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00