Ephesians 5:9

“(nítorí èso Ẹ̀mí ni ìṣoore, àti òdodo àti òtítọ́).”

Ephesians 5:9 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 9 of 33 in Ephesians chapter 5 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Ephesians 5 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Nítorí náà, ẹ máa ṣe àfarawé Ọlọ́run bí àwọn olùfẹ́ ọmọ, ẹ sì máa rìn ní ìfẹ́, gẹ́gẹ́ bí pẹ̀lú ti fẹ́ wa, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún wa ní ọrẹ àti ẹbọ fún Ọlọ́run fún òórùn dídùn. Ṣùgbọ́n àgbèrè àti gbogbo ìwà èérí, tàbí ojúkòkòrò, kí a má tilẹ̀ dárúkọ rẹ̀ láàrín yín mọ́, bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́. Ìbá à ṣe ìwà ọ̀bùn, àti ìṣọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ àwọn ohun tí kò tọ́; ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa dúpẹ́. Nítorí ẹ̀yin mọ èyí dájú pé, kò sí panṣágà, tàbí aláìmọ́ ènìyàn, tàbí wọ̀bìà (tí í ṣé abọ̀rìṣà), tí yóò ni ìpín kan ni ìjọba àti Ọlọ́run. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ: nítorí nípasẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ní ìbínú Ọlọ́run fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn. Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ alájọpín pẹ̀lú wọn. Nítorí ẹ̀yin tí jẹ́ òkùnkùn lẹ́ẹ̀kan ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin dí ìmọ́lẹ̀, nípa tí Olúwa: ẹ máa rín gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ (nítorí èso Ẹ̀mí ni ìṣoore, àti òdodo àti òtítọ́). Ẹ sì máa wádìí ohun tí í ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa. Ẹ má sì ṣe bá àwọn íṣẹ́ òkùnkùn kẹ́gbẹ́ pọ̀, ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa bá wọn wí. Nítorí ìtìjú tilẹ̀ ni láti máa sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí àwọn aláìgbọ́ràn ń ṣe ní ìkọ̀kọ̀. Ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí a tú síta ni ìmọ́lẹ̀ ń fì hàn: nítorí ohunkóhun tí ó bá fi nǹkan hàn, ìmọ́lẹ̀ ni. Nítorí náà ni ó ṣe wí pé, “Jí, ìwọ̀ ẹni tí ó sun, sí jíǹde kúrò nínú òkú yóò sì fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.” Nítorí náà ẹ kíyèsi láti máa rìn ní ìwà pípé, kì í ṣé bí àwọn òmùgọ̀, ṣùgbọ́n bí àwọn ọlọ́gbọ́n; ẹ máa ra ìgbà padà, nítorí búburú ní àwọn ọjọ́. Nítorí náà, ẹ má ṣé jẹ aláìlóye, ṣùgbọ́n ẹ máa mòye ohun tí ìfẹ́ Olúwa jásí. Ẹ má sí ṣe mú wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí rúdurùdu wà; ṣùgbọ́n ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ nínú , àti orin ìyìn, àti orin Ẹ̀mí, ẹ máa kọrin, kí ẹ sì máa kọrin dídùn ní ọkàn yín sí Olúwa. Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo fún ohun gbogbo lọ́wọ́ Ọlọ́run, àní , ní orúkọ Olúwa wá. Ẹ máa tẹríba fún ara yín ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa. Nítorí pé ọkọ ni ó ń ṣe orí aya, gẹ́gẹ́ bí tí i ṣe orí ìjọ, tí òun si ń ṣe ara rẹ̀, Òun sì ni Olùgbàlà rẹ̀. Nítorí náà gẹ́gẹ́ bí ìjọ tí i tẹríba fún , bẹ́ẹ̀ sì ní kì àwọn aya máa ṣe sí ọkọ wọn ní ohun gbogbo. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí tí fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un. Kí òun lè sọ ọ́ di mímọ́ lẹ́yìn tí ó tí fi ọ̀rọ̀ wẹ̀ ẹ́ nínú agbada omí. Kí òun lé mú un wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ bí ìjọ tí ó ní ògo ní àìlábàwọ́n, tàbí àlébù kan, tàbí irú nǹkan bá-wọ̀n-ọn-nì: ṣùgbọ́n kí ó lè jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù. Bẹ́ẹ̀ ní ó tọ́ kí àwọn ọkùnrin máa fẹ́ràn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. Nítorí kò sì ẹnìkan tí ó ti kórìíra ara rẹ̀; bí kò ṣe pé kí ó máa bọ́ ọ kí ó sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí sì ti ń ṣe sí ìjọ. Nítorí pé àwa ni ẹ̀yà ara rẹ̀, àti tí ẹran-ara rẹ̀, àti egungun ara rẹ̀. Nítorí èyí ní ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan. Àṣírí ńlá ní èyí: ṣùgbọ́n èmí ń sọ nípá ti àti tí ìjọ. Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù yín fẹ́ràn aya rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òun fúnra rẹ̀; kí aya kí ó sì bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀.

Every verse in Ephesians 5

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00