Esther 6:10
“Ọba pàṣẹ fún Hamani pé, “Lọ lẹ́sẹ̀kan náà. Mú aṣọ náà àti ẹṣin kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí o ṣe sọ fún Mordekai ará a Júù, ẹni tí ó jókòó sí ẹnu-ọ̀nà ọba. Má ṣe fi ohunkóhun sílẹ̀ nínú ohun tí o ti yàn.””
Esther 6:10 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 10 of 14 in Esther chapter 6 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Esther 6 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Ní òru ọjọ́ náà ọba kò le è sùn; nítorí náà, ó pàṣẹ kí wọn mú ìwé ìrántí wá, àkọsílẹ̀ ìjọba rẹ̀, wọ́n mú un wá wọ́n sì kà á sí létí. Wọ́n rí àkọsílẹ̀ níbẹ̀ pé tí sọ àṣírí àti ṣi, àwọn ìjòyè ọba méjì tí wọ́n ń ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà, tí wọ́n ń gbèrò láti pa ọba . Ọba béèrè pé, “Kí ni ọlá àti iyì tí ti gbà fún èyí?” Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dáhùn pé, “Kò tí ì sí ohun tí a ṣe fún un.” Ọba wí pé, “Ta ni ó wà nínú àgbàlá?” Nísinsin yìí, Hamani ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ àgbàlá ìta ààfin ni láti sọ fún ọba nípa síso lórí igi tí ó ti rì fún un. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dáhùn pé, “Hamani ni ó wà níbẹ̀ ó dúró sí inú àgbàlá.” Ọba pàṣẹ pé, “Ẹ mú un wọlé wá.” Nígbà tí wọlé, ọba béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni kí a ṣe fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti bu ọlá fún?” Nísinsin yìí sì ro èyí fúnra rẹ̀ pé, “Ta ni ó wà níbẹ̀ tí ọba fẹ́ dá lọ́lá ju èmi lọ?” Nítorí náà dá ọba lóhùn pé, “Fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá, jẹ́ kí wọn kí ó mú aṣọ ọba èyí tí ọba ń wọ̀ àti ẹṣin tí ọba máa ń gùn, pẹ̀lú ọ̀kan lára adé ọba kí a fi dé e ní orí. Jẹ́ kí a fi aṣọ àti ẹṣin lé ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ọba tí ó ga jùlọ lọ́wọ́, kí wọn wọ aṣọ náà fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá, kí wọn sì sìn ín gun ẹṣin jákèjádò gbogbo ìgboro ìlú, kí wọn máa kéde níwájú rẹ̀ pé, ‘Èyí ni a ṣe fún ọkùnrin náà ẹni tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá!’ ” Ọba pàṣẹ fún pé, “Lọ lẹ́sẹ̀kan náà. Mú aṣọ náà àti ẹṣin kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí o ṣe sọ fún ará a Júù, ẹni tí ó jókòó sí ẹnu-ọ̀nà ọba. Má ṣe fi ohunkóhun sílẹ̀ nínú ohun tí o ti yàn.” Bẹ́ẹ̀ ni ṣe mú aṣọ àti ẹṣin náà. Ó fi wọ , Mordekai sì wà lórí ẹṣin jákèjádò gbogbo ìgboro ìlú, ó sì ń kéde níwájú rẹ̀ pé, “Èyí ni a ó ṣe fún ọkùnrin náà ẹni tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá!” Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí padà sí ẹnu-ọ̀nà ọba. Ṣùgbọ́n sáré lọ ilé, ó sì bo orí rẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, Hamani sì sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ sí i fún ṣi ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àwọn olùbádámọ̀ràn rẹ̀ àti ìyàwó o rẹ̀ sọ fún un pé, “Níwọ́n ìgbà tí ti jẹ́ ẹ̀yà Júù, níwájú ẹni tí ìṣubú rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀, ìwọ kò lè rí ẹ̀yìn in rẹ̀—dájúdájú ìwọ yóò parun!” Bí wọ́n ṣe ń bá a sọ̀rọ̀, àwọn ìwẹ̀fà ọba wọlé, wọ́n sì kán lójú láti lọ sí ibi àsè tí ti pèsè.
Every verse in Esther 6
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.