Esther 7:3
“Nígbà náà ni ayaba Esteri dáhùn, “Bí èmi bá rí ojúrere rẹ, ìwọ ọba, bí ó bá sì tẹ́ ọláńlá à rẹ lọ́rùn, fún mi ní ẹ̀mí mi, èyí ni ẹ̀bẹ̀ mi. Kí o sì pa àwọn ènìyàn mi mọ́—èyí ni ìbéèrè mi.”
Esther 7:3 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 3 of 10 in Esther chapter 7 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Esther 7 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Ọba àti sì lọ sí àpèjẹ pẹ̀lú ayaba, bí wọ́n sì ṣe ń mu wáìnì ní ọjọ́ kejì yìí, ọba sì tún béèrè pé, “Esteri ayaba, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó sì fi fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìdajì ìjọba à mi, n ó fi fún ọ.” Nígbà náà ni ayaba dáhùn, “Bí èmi bá rí ojúrere rẹ, ìwọ ọba, bí ó bá sì tẹ́ ọláńlá à rẹ lọ́rùn, fún mi ní ẹ̀mí mi, èyí ni ẹ̀bẹ̀ mi. Kí o sì pa àwọn ènìyàn mi mọ́—èyí ni ìbéèrè mi. Nítorí a ti ta èmi àti àwọn ènìyàn mi fún àwọn tí yóò pa wá run, à ti ṣe ìdájọ́ wa fún pípa àti píparẹ́. Bí a bá tilẹ̀ tà wá bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ǹ bá dákẹ́, nítorí irú ìpọ́njú bẹ́ẹ̀ kò tó èyí tí à ń yọ ọba lẹ́nu sí.” Ọba bi ayaba léèrè pé, “Ta a ni ẹni náà? Níbo ni ẹni náà wà tí kò bẹ̀rù láti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀?” Esteri sọ wí pé, “Alátakò àti ọ̀tá náà ni aláìníláárí yìí.” Nígbà náà ni wárìrì níwájú ọba àti ayaba. Ọba sì dìde pẹ̀lú ìbínú, ó fi wáìnì sílẹ̀ ó sì jáde lọ sí àgbàlá ààfin. Ṣùgbọ́n nígbà tí , ti rí i dájú pé ọba ti pinnu láti pa òun, ó dúró lẹ́yìn láti bẹ ayaba nítorí ẹ̀mí rẹ̀. Bí ọba ṣe padà dé láti àgbàlá ààfin wá sí gbọ̀ngàn àsè náà, Hamani ṣubú sórí àga tí ayaba fẹ̀yìn tì. Ọba sì pariwo pé, “Yóò ha tún tẹ́ ayaba níbí yìí, nínú ilé, ní ojú mi bí?” Ní kété tí ọba sọ ọ̀rọ̀ yìí jáde, wọ́n da aṣọ bo lójú. Nígbà náà ọ̀kan nínú àwọn ìwẹ̀fà tó ń dúró níwájú ọba, sọ wí pé, “Igi tí ó ga tó ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà marunlélaadọrin ni ti rì sí ẹ̀gbẹ́ ilé e rẹ̀. Ó ṣe é fún , ẹni tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọba.” Ọba wí pé, ẹ so ó rọ̀ sórí i rẹ́! Wọ́n sì so sórí igi tí ó ti pèsè sílẹ̀ fún , ìbínú ọba sì rọ̀.
Every verse in Esther 7
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.