Exodus 17:12

“Ṣùgbọ́n apá ń ro Mose, wọ́n mú òkúta, wọ́n sì fi sí abẹ́ rẹ̀, ó sì jókòó lé òkúta náà; Aaroni àti Huri sì mu ní apá rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àti èkejì ni apá òsì; apá rẹ̀ méjèèjì sì dúró gangan títí di ìgbà ti oòrùn wọ.”

Exodus 17:12 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 12 of 16 in Exodus chapter 17 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

1 thread runs through this chapter

Exodus 17 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Gbogbo ìjọ ènìyàn ẹli si gbéra láti jáde kúrò láti aginjù wọ́n ń lọ láti ibi kan de ibi kan gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ. Wọ́n pàgọ́ sí , ṣùgbọ́n kò sí omi fún àwọn ènìyàn láti mú. Àwọn ènìyàn sì sọ̀ fún , wọ́n wí pé, “Fún wa ni omi mu.” dá wọn lóhùn wí pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń bá mi jà? Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dán Olúwa wò?” Ṣùgbọ́n òǹgbẹ ń gbẹ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń kùn sí , wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde kúrò ní láti mú kí òǹgbẹ pa àwa, àwọn ọmọ wa àti ohun ọ̀sìn wa ku fún òǹgbẹ.” Nígbà náà ni gbé ohùn rẹ̀ sókè sí Olúwa pé, “Kí ni kí èmi kí ó ṣe fún àwọn ènìyàn yìí? Wọ́n múra tan láti sọ mi ni òkúta.” Olúwa sì dá lóhùn pé, “Máa lọ síwájú àwọn ènìyàn, mú nínú àwọn àgbàgbà ẹli pẹ̀lú rẹ, mú ọ̀pá tí ìwọ fi lu odò lọ́wọ́ kí ó sì máa lọ. Èmi yóò dúró ni ibẹ̀ dè ọ ni orí àpáta ni . Ìwọ ó sì lu àpáta, omi yóò sì jáde nínú rẹ̀ fún àwọn ènìyàn láti mu.” sì ṣe bẹ́ẹ̀ ni iwájú àwọn àgbàgbà ẹli. Ó sì sọ orúkọ ibẹ̀ ni àti , nítorí àwọn ọmọ ẹli sọ̀, wọ́n sì dán Olúwa wò, wọ́n wí pé, “Ǹjẹ́ Olúwa ń bẹ láàrín wa tàbí kò sí?” Àwọn ara jáde, wọ́n sì dìde ogun sí àwọn ọmọ ẹli ni . Mose sì sọ fún Joṣua pé, “Yàn lára àwọn ọkùnrin fún wa, kí wọn ó sì jáde lọ bá àwọn ará jà. Ní ọ̀la, èmi yóò dúró ni orí òkè pẹ̀lú ọ̀pá Ọlọ́run ní ọwọ́ mi.” Joṣua ṣe bí ti wí fún un, ó sì bá àwọn ará jagun; nígbà tí , Aaroni àti lọ sí orí òkè náà. Níwọ́n ìgbà tí bá gbé apá rẹ̀ sókè, Israẹli n borí ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá sì rẹ apá rẹ̀ sílẹ̀, Amaleki a sì borí. Ṣùgbọ́n apá ń ro , wọ́n mú òkúta, wọ́n sì fi sí abẹ́ rẹ̀, ó sì jókòó lé òkúta náà; Aaroni àti sì mu ní apá rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àti èkejì ni apá òsì; apá rẹ̀ méjèèjì sì dúró gangan títí di ìgbà ti oòrùn wọ. Joṣua sì fi ojú idà ṣẹ́gun àwọn ará . Olúwa sì sọ fun pé. “Kọ èyí sì inú ìwé fún ìrántí, kí o sì sọ fún Joṣua pẹ̀lú; nítorí èmi yóò pa ìrántí run pátápátá kúrò lábẹ́ ọ̀run.” Mose sì tẹ́ pẹpẹ kan, ó sì sọ orúkọ pẹpẹ náà ní Olúwa ni Àsíá mi. Ó wí pé, “A gbé ọwọ́ sókè sí ìtẹ́ Olúwa. Olúwa yóò bá jagun láti ìran dé ìran.”

Every verse in Exodus 17

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00