Ezekiel 10:16
“Bí àwọn kérúbù yìí bá ń lọ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹgbẹ́ wọn náà yóò lọ; bẹ́ẹ̀ ni bí àwọn kérúbù bá tú ìyẹ́ wọn ká láti dìde nílẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ yìí kò ní kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn.”
Ezekiel 10:16 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 16 of 22 in Ezekiel chapter 10 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Ezekiel 10 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Mo sì wò ó, mo rí ohun kan tó dàbí òkúta safire nínú òfúrufú tó wà lókè orí kérúbù, ìrísí ohun yìí sì dàbí ìtẹ́. Olúwa sì sọ fún ọkùnrin tó wọ aṣọ funfun pé, “Lọ sí àárín àwọn kẹ̀kẹ́ tó wà lábẹ́ kérúbù. Bu ẹyin iná tó kúnwọ́ rẹ láàrín kérúbù, kí o sì fọ́n sórí ìlú náà.” Ó sì lọ lójú mi. Àwọn kérúbù dúró sí apá gúúsù tẹmpili nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ìkùùkuu sì bo inú àgbàlá. Ògo Olúwa sì kúrò lórí àwọn kérúbù, ó bọ́ sí ibi ìloro tẹmpili. Ìkùùkuu sì bo inú tẹmpili, àgbàlá sì kún fún ìmọ́lẹ̀ àti ògo Olúwa. A sì gbọ́ ariwo ìyẹ́ àwọn kérúbù yìí títí dé àgbàlá tó wà ní ìta gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí Ọlọ́run Olódùmarè bá ń sọ̀rọ̀. Nígbà tí Olúwa pàṣẹ fún ọkùnrin aláṣọ funfun yìí pé, “Mú iná láàrín àwọn kẹ̀kẹ́, láàrín àwọn kérúbù,” ó sì lọ dúró ṣẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ náà. Ọ̀kan nínú àwọn kérúbù sì nawọ́ sí ibi iná tó wà láàrín kérúbù yòókù. Ó mú lára rẹ, ó fi sínú ọwọ́ ọkùnrin aláṣọ funfun, òun náà gbà á, ó sì jáde lọ. (Ohun tó dàbí ọwọ́ ènìyàn wà lábẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù yìí.) Nígbà tí mo sì wò, kíyèsí i, àwọn kẹ̀kẹ́ mẹ́rin wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kérúbù yìí, kẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kérúbù kọ̀ọ̀kan; ìrí àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ń tàn yanran bí àwọ̀ òkúta berili. Ní ti ìrísí wọn, gbogbo wọn jọra wọn; ọ̀kọ̀ọ̀kan rí bí ìgbà tí kẹ̀kẹ́ kan wà nínú kẹ̀kẹ́ mìíràn. Nígbà tí wọ́n ń lọ, wọ́n tẹ̀lé ọ̀kan nínú ọ̀nà mẹ́rin tí àwọn kérúbù dojúkọ; àwọn kẹ̀kẹ́ náà kò yípadà bí àwọn kérúbù ti ń lọ. Àwọn kérúbù ń lọ sí ibi tí orí dojúkọ láì yà. Gbogbo ara wọn àti ẹ̀yìn, ọwọ́ wọn àti ìyẹ́ wọn, àti àwọn kẹ̀kẹ́ kún fún ojú yíkákiri kẹ̀kẹ́, tí àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní. Mo gbọ́ tí wọ́n pe àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ni “kẹ̀kẹ́ àjà.” Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kérúbù yìí ni ojú mẹ́rin: ojú èkínní jẹ́ ojú kérúbù, ojú kejì jẹ́ ti ènìyàn, ojú kẹta jẹ́ ti kìnnìún nígbà tí ojú kẹrin jẹ́ ti ẹyẹ idì. A gbé àwọn kérúbù sókè. Èyí ni àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo rí létí odò . Bí àwọn kérúbù yìí bá ń lọ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹgbẹ́ wọn náà yóò lọ; bẹ́ẹ̀ ni bí àwọn kérúbù bá tú ìyẹ́ wọn ká láti dìde nílẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ yìí kò ní kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Bí àwọn kérúbù bá dúró díẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ náà yóò dúró jẹ́ẹ́; bí àwọn kérúbù bá dìde àwọn kẹ̀kẹ́ náà yóò dìde, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí wà nínú wọn. Ògo Olúwa kúrò níbi ìloro tẹmpili, ó sì dúró sórí àwọn kérúbù. Àwọn kérúbù gbé ìyẹ́ wọn sókè, wọ́n sì fò kúrò nílẹ̀ lójú mi, wọ́n sì lọ pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ wọn lẹ́ẹ̀kan náà. Wọ́n dúró níbi ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà ìlà-oòrùn ilé Olúwa, ògo Ọlọ́run ẹli sì wà lórí wọn. Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀dá alààyè tí mo rí lábẹ́ Ọlọ́run ẹli létí odò , mo sì mọ̀ pé kérúbù ni wọ́n. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ mẹ́rin, lábẹ́ ìyẹ́ wọn ni ohun tó jọ ọwọ́ ènìyàn wà. Àfiwé ojú àti ìrísí wọn rí bákan náà pẹ̀lú àwọn tí mo rí létí odò . Olúkúlùkù wọn sì ń lọ sí ọ̀kánkán tààrà.
Every verse in Ezekiel 10
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.