Ezekiel 25:1
“Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:”
Ezekiel 25:1 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 1 of 17 in Ezekiel chapter 25 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Ezekiel 25 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí àwọn ará kí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí wọn. Sì wí fún àwọn ará pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè tí ó wí pé. Nítorí tí ìwọ wí pé, “Á hà!” Sí ibi mímọ́ mi nígbà tí ó di àìlọ́wọ̀ àti sí orí ilẹ̀ ẹli nígbà tí ó di ahoro; àti sí ilẹ̀ , nígbà tí wọ́n lọ sí ìgbèkùn, kíyèsi i, nítorí náà ni èmi yóò fi fi ọ lé àwọn ènìyàn ìlà-oòrùn lọ́wọ́ ni ohun ìní. Wọn yóò sì gbé ààfin wọn kalẹ̀ nínú rẹ, wọn yóò sì gbé ibùgbé wọn nínú rẹ, wọn yóò jẹ èso rẹ, wọn yóò sì mu wàrà rẹ. Èmi yóò sì sọ di ibùjẹ, fún àwọn ìbákasẹ àti àwọn ọmọ di ibùsùn fún agbo ẹran. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa. Nítorí báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí. Nítorí pé ìwọ pàtẹ́wọ́, ìwọ sì jan ẹsẹ̀ mọ́lẹ̀, tí ìwọ ń yọ̀ pẹ̀lú gbogbo àrankàn rẹ sí ilẹ̀ ẹli nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mi lé ọ, èmi yóò sì fi ọ fún àwọn aláìkọlà fún ìkógun. Èmi yóò sì gé ọ kúrò láàrín àwọn ènìyàn, èmi yóò sì jẹ́ kí o parun kúrò ni ilẹ̀ gbogbo. Èmi yóò sì pa ọ́ run, ìwọ yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ” “Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: ‘Nítorí pé àti sọ wí pé, “Wò ó, ilé ti dàbí gbogbo àwọn kèfèrí,” nítorí náà, Èmi yóò ṣí sílẹ̀ láti àwọn ìlú gbogbo tí ó wà ní ààlà rẹ̀, ògo ilẹ̀ náà, Beti-Jeṣimoti, Baali- àti . Èmi yóò fi pẹ̀lú àwọn ará lé àwọn ènìyàn ìlà-oòrùn ní ìní, kí a má bà á lè rántí àwọn ará láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo. Èmi yóò sì mú ìdájọ́ sẹ sí lára, wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ” “Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí pé: ‘Nítorí pé gbẹ̀san lára ilé , ó sì jẹ̀bi gidigidi nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, nítorí náà báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí pé: Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí èmi yóò sì pa àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko rẹ̀. Èmi yóò fi ṣófo láti dé yóò ti ipa idà ṣubú. Èmi yóò gbẹ̀san lára láti ọwọ́ àwọn ènìyàn mi ẹli, wọn sì ṣe sí gẹ́gẹ́ bí ìbínú àti ìrunú mi, wọn yóò mọ̀ ìgbẹ̀san mi ní Olúwa Olódùmarè wí.’ ” “Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí pé: ‘Nítorí tí àwọn ará hùwà ẹ̀san tí wọ́n sì gbẹ̀san pẹ̀lú odì ní ọkàn wọn, àti pẹ̀lú ìkórìíra gbangba àtijọ́ ní wíwá ọ̀nà láti pa run, nítorí náà báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí pé, “Èmi ti ṣetán láti na ọwọ́ mi jáde sí àwọn ará , èmi yóò sì ké àwọn ará kúrò, èmi yóò sì pa àwọn tí ó kù ní etí kún run. Èmi yóò sì gbẹ̀san ńlá lára wọn nípa ìbáwí gbígbóná; wọn yóò sì mọ̀ wí pé, Èmi ni Olúwa. Nígbà tí èmi yóò gba ẹ̀san lára wọn.” ’ ”
Every verse in Ezekiel 25
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.