Ezra 6:2
“A rí ìwé kíká kan ní Ekbatana ibi kíkó ìwé sí ní ilé olódi agbègbè Media, wọ̀nyí ni ohun tí a kọ sínú rẹ̀. Ìwé ìrántí.”
Ezra 6:2 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 2 of 22 in Ezra chapter 6 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Ezra 6 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Nígbà náà ni ọba pàṣẹ, wọ́n sì wá inú ilé ìfí nǹkan pamọ́ sí ní ilé ìṣúra ní . A rí ìwé kíká kan ní ibi kíkó ìwé sí ní ilé olódi agbègbè , wọ̀nyí ni ohun tí a kọ sínú rẹ̀. Ìwé ìrántí. Ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba ọba , ọba pa àṣẹ kan nípa tẹmpili Ọlọ́run ní ẹmu. Jẹ́ kí a tún tẹmpili ibi tí a ti ń rú írúú ẹbọ kọ́, kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ ni gíga àti fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ àádọ́rùn-ún ẹsẹ̀ bàtà, pẹ̀lú ipele òkúta ńlá ńlá mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ipele pákó kan, kí a san owó rẹ̀ láti inú ilé ìṣúra ọba. Sì jẹ́ kí wúrà àti àwọn ohun èlò fàdákà ti ilé Ọlọ́run, tí kó láti ilé Olúwa ní ẹmu tí ó sì kó lọ sí , di dídápadà sí ààyè wọn nínú tẹmpili ní ẹmu; kí a kó wọn sí inú ilé Ọlọ́run. Nítorí náà, kí ìwọ, Tatenai baálẹ̀ agbègbè àti Ṣetar-bosnai àti àwọn ẹlẹgbẹ́ yín, àwọn ìjòyè ti agbègbè náà kúrò níbẹ̀. Ẹ fi iṣẹ́ ilé Ọlọ́run yìí lọ́rùn sílẹ̀ láì dí i lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí baálẹ̀ àwọn Júù àti àwọn àgbàgbà Júù tún ilé Ọlọ́run yín kọ́ sí ipò rẹ̀. Síwájú sí i, mo pàṣẹ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe fún àwọn àgbàgbà Júù wọ̀nyí lórí kíkọ́ ilé Ọlọ́run yìí. Gbogbo ìnáwó àwọn ọkùnrin yìí ni kí ẹ san lẹ́kùnrẹ́rẹ́ lára ìṣúra ti ọba, láti ibi àkójọpọ̀ owó ìlú ti agbègbè kí iṣẹ́ náà má bà dúró. Ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́—àwọn ọ̀dọ́ akọ màlúù, àwọn àgbò, ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun sí Ọlọ́run ọ̀run, àti jéró, iyọ̀, wáìnì àti òróró, bí àwọn àlùfáà ní ẹmu ti béèrè ni ẹ gbọdọ̀ fún wọn lójoojúmọ́ láìyẹ̀. Kí wọn lè rú àwọn ẹbọ tí ó tẹ́ Ọlọ́run ọ̀run lọ́rùn kí wọ́n sì gbàdúrà fún àlàáfíà ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀. Síwájú sí i, mo pàṣẹ pé tí ẹnikẹ́ni bá yí àṣẹ yìí padà, kí fa igi àjà ilé rẹ̀ yọ jáde, kí a sì gbe dúró, kí a sì fi òun náà kọ́ sí orí rẹ̀ kí ó wo ilé rẹ̀ palẹ̀ a ó sì sọ ọ́ di ààtàn. Kí Ọlọ́run, tí ó ti jẹ́ kí orúkọ rẹ̀ máa gbé ibẹ̀, kí ó pa gbogbo ọba àti orílẹ̀-èdè rún tí ó bá gbé ọwọ́ sókè láti yí àṣẹ yìí padà tàbí láti wó tẹmpili yìí tí ó wà ní ẹmu run. Èmi n pàṣẹ rẹ̀, jẹ́ kí ó di mímúṣẹ láìyí ohunkóhun padà. Nígbà náà, nítorí àṣẹ tí ọba pa, Tatenai, baálẹ̀ ti agbègbè , àti Ṣetar-bosnai pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn pa á mọ́ láìyí ọ̀kan padà. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbàgbà Júù tẹ̀síwájú wọ́n sì ń gbèrú sí i lábẹ́ ìwàásù wòlíì àti wòlíì , ìran . Wọ́n parí kíkọ́ ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run ẹli àti àwọn àṣẹ , Dariusi àti àwọn ọba pọ̀. A parí ilé Olúwa ní ọjọ́ kẹta, oṣù tí í se oṣù kejì ní ọdún kẹfà ti ìjọba ọba . Nígbà náà ni àwọn ènìyàn ẹli—àwọn àlùfáà, àwọn àti àwọn ìgbèkùn tí ó padà, ṣe ayẹyẹ yíya ilé Ọlọ́run sí mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀. Fún yíya ilé Ọlọ́run yìí sí mímọ́, wọ́n pa ọgọ́rùn-ún akọ màlúù, igba àgbò àti irinwó (400) akọ ọ̀dọ́-àgùntàn, àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo ẹli, àgbò méjìlá, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún olúkúlùkù àwọn ẹ̀yà ẹli. Wọ́n sì fi àwọn àlùfáà sí àwọn ìpín wọ́n àti àwọn sì ẹgbẹẹgbẹ́ wọn fún ìsin ti Ọlọ́run ní ẹmu, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú ìwé . Ní ọjọ́ kẹrìnlá ti oṣù , àwọn tí a kó ní ìgbèkùn ṣe ayẹyẹ àjọ ìrékọjá. Àwọn àlùfáà àti àwọn ará ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì jẹ́ mímọ́. Àwọn ará pa ọ̀dọ́-àgùntàn ti àjọ ìrékọjá fún gbogbo àwọn tí a kó ní ìgbèkùn, fún àwọn àlùfáà arákùnrin wọn àti fún ara wọn. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ẹli tí ó ti dé láti ìgbèkùn jẹ ẹ́ lápapọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó ti ya ara wọn kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ àìmọ́ ti àwọn kèfèrí aládùúgbò wọn láti wá Olúwa Ọlọ́run ẹli. Fún ọjọ́ méje, wọ́n ṣe ayẹyẹ àkàrà àìwú pẹ̀lú àjẹtì àkàrà. Nítorí tí Olúwa ti kún wọn pẹ̀lú ayọ̀ nípa yíyí ọkàn ọba padà, tí ó fi ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ ilé Ọlọ́run, Ọlọ́run ẹli.
Every verse in Ezra 6
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.