Genesis 11:15
“Ṣela sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.”
Genesis 11:15 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 15 of 32 in Genesis chapter 11 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
1 thread runs through this chapter
Genesis 11 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Lẹ́yìn náà, gbogbo àgbáyé sì ń sọ èdè kan ṣoṣo. Bí àwọn ènìyàn ṣe ń tẹ̀síwájú lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, wọ́n rí pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan ní ilẹ̀ Ṣinari, wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀. Wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a mọ bíríkì kí a sì sún wọ́n jìnà.” Bíríkì ni wọ́n ń lò ní ipò òkúta, àti ọ̀dà ilẹ̀ tí wọn ń lò láti mú wọn papọ̀ dípò ẹfun (òkúta láìmù tí wọ́n fi ń ṣe símẹ́ńtì àti omi). Nígbà náà ni wọ́n wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú kan dó fún ara wa, kí a sì kọ́ ilé ìṣọ́ kan tí yóò kan ọ̀run, kí a ba à lè ní orúkọ, kí a má sì tú káàkiri sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Ṣùgbọ́n, Olúwa sọ̀kalẹ̀ láti wo ìlú àti ilé ìṣọ́ tí àwọn ènìyàn náà ń kọ́. Olúwa wí pé, “Bí àwọn ènìyàn bá ń jẹ́ ọ̀kan àti èdè kan tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ yìí, kò sí ohun tí wọ́n gbèrò tí wọn kò ní le ṣe yọrí. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ lọ, kí a da èdè wọn rú kí èdè wọn má ba à yé ara wọn mọ́.” Olúwa sì tú wọn ká sórí ilẹ̀ gbogbo, wọ́n sì ṣíwọ́ ìlú náà tí wọn ń tẹ̀dó. Ìdí èyí ni a fi pè é ní nítorí ní ibẹ̀ ni Olúwa ti da èdè gbogbo ayé rú. Olúwa tí sì tú àwọn ènìyàn ká sí gbogbo orí ilẹ̀ ayé. Wọ̀nyí ni ìran Ṣemu. Ọdún méjì lẹ́yìn ìkún omi, tí Ṣemu pé ọgọ́rùn-ún ọdún ni ó bí ṣadi. Lẹ́yìn tí ó bí ṣadi, Ṣemu tún wà láààyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. Nígbà tí ṣadi pé ọdún márùndínlógójì ni ó bí Ṣela. Arfakṣadi sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn. Nígbà tí Ṣela pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí . Ṣela sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí tán, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. Eberi sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n, ó sì bí . Eberi sì wà láààyè fún irinwó ọdún ó lé ọgbọ̀n (430) lẹ́yìn tí ó bí , ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. Nígbà tí pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí . Pelegi sì tún wà láààyè fún igba ọdún ó lé mẹ́sàn-án (209) lẹ́yìn tí ó bí , ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. Nígbà tí pé ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ni ó bí . Reu tún wà láààyè lẹ́yìn tí ó bí fún igba ọdún ó lé méje (207), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn. Nígbà tí pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí . Serugu sì wà láààyè fún igba ọdún lẹ́yìn tí ó bí , ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. Nígbà tí pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, ó bí Tẹra. Nahori sì wà láààyè fún ọdún mọ́kàn dín lọ́gọ́fà lẹ́yìn ìbí Tẹra, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. Lẹ́yìn tí Tẹra pé ọmọ àádọ́rin ọdún ó bí , Nahori àti . Wọ̀nyí ni ìran Tẹra. Tẹra ni baba , Nahori àti . Harani sì bí Lọti. Harani sì kú ṣáájú Tẹra baba rẹ̀ ní ilẹ̀ ìbí rẹ̀ ní ti ilẹ̀ . Abramu àti sì gbéyàwó. Orúkọ aya ni , nígbà tí aya ń jẹ́ , tí ṣe ọmọ . Harani ni ó bí àti . sì yàgàn, kò sì bímọ. Tẹra sì mú ọmọ rẹ̀ àti Lọti ọmọ , ọmọ ọmọ rẹ̀, ó sì mú tí i ṣe aya ọmọ rẹ̀. Abramu pẹ̀lú gbogbo wọn sì jáde kúrò ní ti láti lọ sí ilẹ̀ . Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn dé wọ́n tẹ̀dó síbẹ̀. Nígbà tí Tẹra pé ọmọ igba ọdún ó lé márùn-ún (205) ni ó kú ní .
Every verse in Genesis 11
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.