Genesis 29:6

“Jakọbu béèrè pé, “Ṣe àlàáfíà ni ó wà?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni. Wò ó, Rakeli ọmọ rẹ̀ ni ó ń bọ̀ yìí pẹ̀lú agbo àgùntàn.””

Genesis 29:6 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 6 of 35 in Genesis chapter 29 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Genesis 29 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Jakọbu sì tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò rẹ̀, ó sì dé ilẹ̀ àwọn ará ìlà-oòrùn. Ó sì rí kànga kan ní pápá, agbo àgùntàn mẹ́ta sì dúró láti mu omi ní ibi kànga náà, nítorí pé láti inú kànga náà ni wọ́n ti ń fi omi fún agbo àgùntàn. Òkúta tí a gbé dí ẹnu kànga náà sì tóbi gidigidi. Nígbà tí gbogbo agbo ẹran bá péjọpọ̀ sí ibẹ̀ tán ni àwọn darandaran yóò tó yí òkúta náà kúrò, tí wọn yóò sì fún àwọn ẹran náà ní omi, tí wọ́n bá sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ tán, wọn yóò tún yí òkúta náà padà sí ẹnu kànga náà. Jakọbu béèrè lọ́wọ́ àwọn darandaran náà pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi níbo ni ẹ̀yin ti wá?” Àwọn náà sì dáhùn pé, “Láti ni.” Ó sì bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ ọmọ ọmọ ?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa mọ̀ ọ́n.” Jakọbu béèrè pé, “Ṣe àlàáfíà ni ó wà?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni. Wò ó, Rakeli ọmọ rẹ̀ ni ó ń bọ̀ yìí pẹ̀lú agbo àgùntàn.” Ó sì wí pé, “Kíyèsi, ilẹ̀ ò tí ì ṣú, kò tì í tó àkókò fún àwọn ohun ọ̀sìn láti wọ̀. Ẹ fún àwọn ẹran wọ̀nyí ní omi, kí ẹ ba à le tètè dà wọ́n padà láti jẹun.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa kì í yí òkúta kúrò ní ẹnu kànga láti pọn omi fún àwọn ẹran títí gbogbo àwọn darandaran àti àwọn ẹran yóò fi péjọ tán.” Bí wọ́n sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni dé pẹ̀lú agbo àgùntàn baba rẹ̀, nítorí darandaran ni òun náà. Nígbà tí ọbu rí ọmọbìnrin tí í ṣe ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀, pẹ̀lú àgùntàn , Jakọbu súnmọ́ kànga náà, ó sì yí òkúta kúrò lẹ́nu rẹ̀, ó sì fún àwọn ẹran arákùnrin ìyá rẹ̀ ní omi. Jakọbu sì fẹnu ko ní ẹnu. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún. Jakọbu sì wí fún pé ìbátan baba rẹ̀ ni òun, àti pé, òun jẹ́ ọmọ . Rakeli sì sáré lọ sọ fún baba rẹ̀. Ní kété tí gbúròó ọbu ọmọ arábìnrin rẹ̀, ó jáde lọ pàdé ọbu, ó dì mọ́ ọn, ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu, ó sì mú un lọ sí ilé. Nígbà náà ni ọbu ròyìn ohun gbogbo fún un. Labani sì wí pé, “Ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ ara mi ni ìwọ jẹ́.” Lẹ́yìn tí ọbu sì wà pẹ̀lú rẹ̀ fún odidi oṣù kan, Labani wí fún ọbu pé, “Bí a tilẹ̀ jẹ́ ìbátan, kò yẹ kí o máa ṣiṣẹ́ fún mi lásán láìgba ohun kankan. Sọ ohun tì ìwọ fẹ́ gbà fún iṣẹ́ tí ìwọ ń ṣe fún mi!” Wàyí o, Labani ní ọmọbìnrin méjì, orúkọ èyí ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ , orúkọ àbúrò sì ń jẹ́ . Lea kò ní ẹwà púpọ̀, ṣùgbọ́n ní ẹwà gidigidi. Ojú rẹ̀ sì fanimọ́ra. Jakọbu sì fẹ́ràn , ó sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Èmi yóò ṣiṣẹ́ sìn ọ fún ọdún méje, bí ìwọ yóò bá fún mi ní ọmọ rẹ ní aya.” Labani sì dáhùn wí pé, “Ó kúkú sàn kí ń fi fún ọ, ju kí ń fi fún ẹlòmíràn lọ, nítorí náà wà ní ọ̀dọ̀ mi.” Jakọbu sì ṣiṣẹ́ sin fún ọdún méje láti fẹ́ . Àwọn ọdún wọ̀nyí sì dàbí ọjọ́ díẹ̀ lára rẹ̀, nítorí ó fẹ́ràn rẹ̀. Jakọbu sì wí fún pé, “Mo ti parí àsìkò tí a jọ ṣe àdéhùn rẹ̀, nítorí náà fún mi ní aya mi, kí òun lè ṣe aya fún mi.” Labani sì pe gbogbo ènìyàn ibẹ̀ jọ, ó sì ṣe àsè ìyàwó fún wọ́n. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di òru, Labani mú tọ ọbu lọ. Jakọbu sì bá a lòpọ̀. Labani sì fi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́. Sì kíyèsi, nígbà ti ilẹ̀ mọ́, Jakọbu rí i pé ni! Ó sì wí fún pé, “Èwo ni ìwọ ṣe sí mi yìí? Ṣe bí nítorí ni mo ṣe ṣiṣẹ́ sìn ọ, èéṣe tí ìwọ tàn mi?” Labani sì dáhùn pé, “Kò bá àṣà wa mu láti fi àbúrò fún ọkọ ṣáájú ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Mú sùúrù parí ọ̀sẹ̀ ìgbéyàwó yìí náà, nígbà náà ni èmi yóò fi àbúrò rẹ̀ fún ọ pẹ̀lú, bí ìwọ ó bá ṣiṣẹ́ sìn mi fún ọdún méje mìíràn.” Jakọbu sì gbà láti sin fún ọdún méje mìíràn. Labani sì fi ọmọ rẹ̀ fún un bí aya. Labani sì fi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún bí ìránṣẹ́. Jakọbu sì bá náà lòpọ̀. Ó sì fẹ́ràn ju lọ, ó sì ṣiṣẹ́ sin fún ọdún méje mìíràn. Nígbà tí Olúwa sì ri pé, Jakọbu kò fẹ́ràn , ó ṣí i ni inú ṣùgbọ́n yàgàn. Lea sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní , nítorí ó wí pé, “Nítorí Olúwa ti mọ ìpọ́njú mi, dájúdájú, ọkọ mi yóò fẹ́ràn mi báyìí.” Ó sì tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní , wí pé, “Nítorí tí Olúwa ti gbọ́ pé a kò fẹ́ràn mi, ó sì fi èyí fún mi pẹ̀lú.” Ó sì tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì wí pé, “Nígbà yìí ni ọkọ mi yóò fi ara mọ́ mi, nítorí tí mo ti bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún un,” nítorí náà ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ní . Ó sì tún lóyún, ó sì tún jẹ́ pé ọmọkùnrin ni ó bí, ó sì wí pé, “Nígbà yìí ni èmi yóò yin Olúwa.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní . Ó sì dáwọ́ ọmọ bíbí dúró.

Every verse in Genesis 29

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00