Genesis 33:15
“Esau wí pé, “Jẹ́ kí n fi díẹ̀ sílẹ̀ fún ọ nínú àwọn ọkùnrin mi nígbà náà.” Jakọbu wí pé, “Èéṣe, àní kí n sá à rí ojúrere olúwa mi?””
Genesis 33:15 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 15 of 20 in Genesis chapter 33 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Genesis 33 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Jakọbu sì gbójú sókè, ó sì rí àti irinwó (400) ọkùnrin tí wọ́n ń bọ̀, ó sì pín àwọn ọmọ fún , Rakeli àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin méjèèjì. Ó sì ti àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ọmọ wọn síwájú, Lea àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọ̀wọ́ kejì tí ó tẹ̀lé wọn, Rakeli àti ẹfu sì wà lẹ́yìn pátápátá. Jakọbu fúnra rẹ̀ wa lọ síwájú pátápátá, ó sì tẹríba ní ìgbà méje bí ó ti ń súnmọ́ , arákùnrin rẹ̀. Ṣùgbọ́n sáré pàdé ọbu, ó sì dì mọ́ ọn, ó rọ̀ mọ́ ọn lọ́rùn, ó sì fẹnukò ó lẹ́nu. Àwọn méjèèjì sì sọkún. Nígbà tí sì ṣe àkíyèsí àwọn ìyàwó àti ọmọ ọbu, ó béèrè lọ́wọ́ ọbu pé, “Ti ta ni àwọn wọ̀nyí?” ọbu sì fèsì wí pé, “Èyí ni àwọn ọmọ tí Ọlọ́run nínú àánú rẹ̀ ti fi fún ìránṣẹ́ rẹ.” Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ọmọ wọn súnmọ́ tòsí, wọ́n sì tẹríba. Lẹ́yìn náà ni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú dé, wọ́n sì tún tẹríba. Ní ìkẹyìn ni ẹfu àti dé, wọ́n sì tún tẹríba pẹ̀lú. sì béèrè pé, “Kí ni èrò rẹ tí o fi to àwọn ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ tí mo pàdé wọ̀nyí?” ọbu dáhùn pé, “Kí n ba le rí ojúrere rẹ ni olúwa mi.” Ṣùgbọ́n wí pé, “Tèmi ti tó mi, pa èyí tí o ní mọ́ fún ara rẹ.” Jakọbu bẹ̀ ẹ́ wí pé, “Rárá bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ó bá ṣe pé, mo rí ojúrere rẹ, jọ̀wọ́ gba ọrẹ lọ́wọ́ mi. Bí mo ṣe rí ojú rẹ̀ yìí, ó dàbí wí pé mo rí ojú Ọlọ́run ni báyìí, tí inú rẹ̀ ti dùn sí mi. Jọ̀wọ́ gba àwọn ohun tí mo mú wá wọ̀nyí lọ́wọ́ mi. Nítorí Ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ hàn sí mi, gbogbo ohun tí mo fẹ́ sì ni mo ní.” Nígbà tí ọbu sì rọ̀ ọ́ pé gbọdọ̀ gbà wọ́n, sì gbà á. Nígbà náà ni wí pé, “Jẹ́ kí a máa lọ, n ó sìn ọ.” Ṣùgbọ́n ọbu wí fún un pé, “Ṣe ìwọ náà ṣe àkíyèsí pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ wọ̀nyí kéré, àwọn màlúù àti àgùntàn pẹ̀lú sì ní àwọn ọmọ kéékèèké. Bí a bá dà wọ́n rìn jìnnà ju bí agbára wọn ṣe mọ lọ, wọ́n lè kú. Èmi bẹ̀ ọ́, máa lọ síwájú ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ó sì máa rọra bọ̀, títí èmi àti àwọn ọmọ yóò fi dé ọ̀dọ̀ olúwa mi ní .” wí pé, “Jẹ́ kí n fi díẹ̀ sílẹ̀ fún ọ nínú àwọn ọkùnrin mi nígbà náà.” ọbu wí pé, “Èéṣe, àní kí n sá à rí ojúrere olúwa mi?” Ní ọjọ́ náà gan an ni padà lọ sí . Jakọbu sì lọ sí , ó sì kọ́ ilé fún ara rẹ̀, ó sì ṣe ọgbà fún àwọn ẹran. Ìdí èyí ní a fi ń pe ibẹ̀ ní . Lẹ́yìn ìgbà tí ọbu tí - dé, àlàáfíà ni ọbu dé ìlú Ṣekemu ní ilẹ̀ , ó sì pàgọ́ sí itòsí ìlú náà. Ó sì ra ilẹ̀ kan tí ó pàgọ́ sí ni ọgọ́rùn-ún owó fàdákà lọ́wọ́ àwọn ọmọ tí í ṣe baba Ṣekemu. Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan tí ó pè ní El ẹli.
Every verse in Genesis 33
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.