Genesis 39:3
“Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ rí i pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀, àti pé Olúwa jẹ́ kí ó máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ rẹ̀ lé.”
Genesis 39:3 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 3 of 23 in Genesis chapter 39 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Genesis 39 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Nígbà tí wọ́n mú ẹfu dé , Potifari, ará tí i ṣe ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè . Òun ni olórí àwọn ọmọ-ogun . Ó ra ẹfu lọ́wọ́ àwọn ará Iṣmaeli tí wọ́n mú un lọ síbẹ̀. Olúwa sì wà pẹ̀lú ẹfu, ó sì bùkún un, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀gá rẹ̀ ará . Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ rí i pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀, àti pé Olúwa jẹ́ kí ó máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ rẹ̀ lé. Josẹfu sì rí ojúrere , ó sì di aṣojú rẹ̀, Potifari fi ẹfu ṣe olórí ilé rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní. Láti ìgbà tí ó ti fi ẹfu jẹ olórí ilé rẹ̀ àti ohun ìní rẹ̀ gbogbo, ni Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bùkún àwọn ará nítorí ẹfu. Ìbùkún Olúwa wà lórí gbogbo ohun tí ní, nílé àti lóko. Ó sì fi ẹfu ṣe àkóso gbogbo ohun tí ó ní. Kò sì ṣe ìyọnu lórí ohunkóhun mọ àyàfi nípa oúnjẹ tí ó ń jẹ láti ìgbà tí ó ti fi ẹfu ṣe àkóso ilé e rẹ̀. Josẹfu sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin ní ìdúró àti ìrísí rẹ̀, lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya rẹ̀ ṣe àkíyèsí ẹfu, ó sì wí fún un pé, “Wá bá mi lòpọ̀!” Ṣùgbọ́n ẹfu kọ̀, ó sì wí fún aya ọ̀gá rẹ̀ pé, “Kíyèsi, Olúwa mi kò fi ohunkóhun dù mi nínú ilé yìí, gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó fi lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó jù mi lọ nínú ilé yìí, ọ̀gá mi kò fi ohunkóhun dù mi àyàfi ìwọ, tí í ṣe aya rẹ̀. Báwo ni mo ṣe lè ṣe ohun búburú yìí, kí ń sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run?” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni ó ń tẹnumọ́ èyí fún ẹfu, Josẹfu kọ̀ láti bá a lòpọ̀. Ó tilẹ̀ kọ̀ láti máa dúró ni ibi tí ó bá wà. Ní ọjọ́ kan, Josẹfu lọ sínú ilé láti ṣe iṣẹ́, kò sì sí èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ ní tòsí. Ó sì di aṣọ ẹfu mú, ó sì wí pé, “Wá bá mi lòpọ̀!” Ṣùgbọ́n ẹfu fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí i lọ́wọ́, ó sì sá jáde. Nígbà tí ó rí i pé ó ti fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, ó sì ti sá jáde, ó pe àwọn ìránṣẹ́ ilé náà, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkọ ọ̀ mi mú kan wọlé tọ̀ wá wá láti fi wá ṣe ẹlẹ́yà. Ó wọlé tọ̀ mí wá, láti bá mi lòpọ̀, ṣùgbọ́n mo kígbe. Nígbà tí ó gbọ́ pé mo gbé ohùn mi sókè, tí mo sì kígbe, ó jọ̀wọ́ aṣọ rẹ̀ sọ́dọ̀ mi, ó sì sá, ó bọ́ sóde.” Ó sì fi aṣọ náà sọ́dọ̀ títí tí ọkọ rẹ̀ fi dé. Ó rò fún un pé, “Ẹrú ará tí o rà wá ilé láti fi wá ṣẹlẹ́yà wá láti bá mi lòpọ̀. Ṣùgbọ́n bí mo ti kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ó sì sá kúrò nínú ilé.” Nígbà tí gbọ́ ọ̀rọ̀ aya rẹ̀ pé báyìí ni ẹrú rẹ̀ ṣe sí aya rẹ̀, ó bínú gidigidi. Ó sì ju ẹfu sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí a ń ju àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba sí. Ṣùgbọ́n, nígbà tí ẹfu wà nínú ẹ̀wọ̀n níbẹ̀, Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ṣàánú fún un, ó sì mú kí ó rí ojúrere àwọn alábojútó ọgbà ẹ̀wọ̀n. Nítorí náà, alábojútó ọgbà ẹlẹ́wọ̀n fi ẹfu ṣe alákòóso ohun gbogbo tí ó wà nínú ẹ̀wọ̀n, àti ohun tí wọn ń ṣe níbẹ̀. Wọ́dà náà kò sì mikàn nípa gbogbo ohun tí ó fi sí abẹ́ àkóso ẹfu, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú ẹfu, ó sì ń jẹ́ kí ó ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́lé.
Every verse in Genesis 39
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.