Genesis 4:7

“Bí ìwọ bá ṣe ohun tí ó tọ́, ṣé ìwọ kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ṣe ohun tí ó tọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ ní ẹnu-ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ ní ọ ní ìní, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ ṣe àkóso rẹ̀.””

Genesis 4:7 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 7 of 26 in Genesis chapter 4 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

1 thread runs through this chapter

Genesis 4 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Adamu sì bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí . Ó wí pé, “Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa ni mo bí ọmọ ọkùnrin.” Lẹ́yìn náà, ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn tí a pè ní . Abeli jẹ́ darandaran, Kaini sì jẹ́ àgbẹ̀. Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Kaini mú ọrẹ wá fún Olúwa nínú èso ilẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n mú ẹran tí ó sanra wá fún Olúwa nínú àkọ́bí ẹran ọ̀sìn rẹ̀. Olúwa sì fi ojúrere wo àti ọrẹ rẹ̀, ṣùgbọ́n Olúwa kò fi ojúrere wo àti ẹbọ rẹ̀. Nítorí náà inú bí gidigidi, ojú rẹ̀ sì fàro. Nígbà náà ni Olúwa bi pé, “Èéṣe tí ìwọ ń bínú? Èéṣe tí ojú rẹ sì fàro? Bí ìwọ bá ṣe ohun tí ó tọ́, ṣé ìwọ kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ṣe ohun tí ó tọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ ní ẹnu-ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ ní ọ ní ìní, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ ṣe àkóso rẹ̀.” Kaini wí fún arákùnrin rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí a lọ sí oko.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti wà ní oko; Kaini da ojú ìjà kọ arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á. Nígbà náà ni Olúwa béèrè lọ́wọ́ pé, “Níbo ni arákùnrin rẹ wà?” Ó sì dáhùn pé, “Èmi kò mọ ibi tí ó wà, èmí ha ń ṣe olùṣọ́ arákùnrin mi bí?” Olúwa wí pé, “Kín ni ohun tí ìwọ ṣe yìí? Gbọ́! Ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ ń kígbe pè mí láti ilẹ̀ wá. Láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ ti wà lábẹ́ ègún, a sì ti lé ọ lórí ilẹ̀ tí ó ya ẹnu gba ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ lọ́wọ́ rẹ. Bí ìwọ bá ro ilẹ̀, ilẹ̀ kì yóò fi agbára rẹ̀ so èso rẹ̀ fún ọ mọ́. Ìwọ yóò sì jẹ́ ìsáǹsá àti alárìnkiri ni orí ilẹ̀ ayé.” Kaini wí fún Olúwa pé, “Ẹrù ìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi pọ̀ ju èyí tí mo le rù lọ. Lónìí, ìwọ lé mi kúrò lórí ilẹ̀, mó sì di ẹni tí ó fi ara pamọ́ kúrò ní ojú rẹ, èmi yóò sì di ìsáǹsá àti alárìnkiri ní ayé, ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi, yóò sì pa mí.” Ṣùgbọ́n, Olúwa wí fún pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ẹnikẹ́ni bá pa , èmi yóò gbẹ̀san ní ara ítọ̀hún ní ìgbà méje.” Nígbà náà ni Ọlọ́run fi àmì sí ara , kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ri má ba à pa á. Kaini sì kúrò níwájú Olúwa, ó sì ń gbé ilẹ̀ ní ìhà ìlà-oòrùn . Kaini sì bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí . Kaini sì tẹ ìlú kan dó, ó sì fi orúkọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin sọ ìlú náà. Enoku sì bí , Iradi sì ni baba , Mehujaeli sì bí ṣaeli, Metuṣaeli sì ni baba . Lameki sì fẹ́ aya méjì, orúkọ èkínní ni , àti orúkọ èkejì ni . Adah sì bí , òun ni baba irú àwọn tí ń gbé inú àgọ́, tí wọ́n sì ń sin ẹran ọ̀sìn. Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni , òun ni baba irú àwọn tí ń tẹ dùùrù tí wọ́n sì ń fọn fèrè. Silla náà sì bí ọmọkùnrin tí ń jẹ́ -, tí ó ń rọ oríṣìíríṣìí ohun èlò láti ara idẹ àti irin. Arábìnrin - ni . Lameki wí fún àwọn aya rẹ̀, “Adah àti , ẹ tẹ́tí sí mi; ẹ̀yin aya , ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Mo ti pa ọkùnrin kan tí ó kọlù mí, ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó pa mí lára. Bí a ó bá gbẹ̀san ní ìgbà méje, ǹjẹ́ kí a gba ti nígbà mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (77).” Adamu sì tún bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní , tí ó túmọ̀ sí pé, “Ọlọ́run fún mi ní ọmọkùnrin mìíràn ní ipò tí pa.” Seti náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní ṣi. Láti àkókò náà lọ ni àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ké pe orúkọ Olúwa.

Every verse in Genesis 4

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00