Hosea 14:8
“Ìwọ Efraimu, kín ló tún kù tí mo ní ṣe pẹ̀lú ère òrìṣà? Èmi ó dá a lóhùn, èmi ó sì ṣe ìtọ́jú rẹ. Mo dàbí igi junifa tó ń fi gbogbo ìgbà tutù, èso tí ìwọ ń so si ń wá láti ọ̀dọ̀ mi.””
Hosea 14:8 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 8 of 9 in Hosea chapter 14 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Hosea 14 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Yípadà ìwọ ẹli sí Olúwa Ọlọ́run rẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ló fa ìparun rẹ! Ẹ gba ọ̀rọ̀ Olúwa gbọ́, kí ẹ sì yípadà sí Olúwa. Ẹ sọ fún un pé, “Darí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá kí o sì fi oore-ọ̀fẹ́ gbà wá, kí àwa kí ó lè fi ètè wa sán an fún ọ Asiria kò le gbà wá là; a kò ní í gorí ẹṣin ogun. A kò sì ní tún sọ ọ́ mọ́ láé, ‘Àwọn ni òrìṣà wa’ sí àwọn ohun tí ó fi ọwọ́ wa ṣe; nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni àwọn aláìní baba tí ń rí àánú.” “Èmi wo àgàbàgebè wọn sàn, Èmi ó sì fẹ́ràn wọn, lọ́fẹ̀ẹ́, nítorí ìbínú mi ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn. Èmi o dàbí ìrì sí ẹli, wọn o sì yọ ìtànná bi ewéko lílì. Bi kedari ti yóò si ta gbòǹgbò. Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ẹ̀ka rẹ̀ yóò dàgbà, dídán ẹwà yóò rẹ̀ dànù bí igi olifi. Òórùn rẹ yóò sì dàbí igi kedari ti . Àwọn ènìyàn yóò tún padà gbé lábẹ́ òjijì rẹ̀. Yóò rúwé bi ọkà. Yóò sì yọ ìtànná bi àjàrà, òórùn rẹ yóò dàbí ti wáìnì . Ìwọ , kín ló tún kù tí mo ní ṣe pẹ̀lú ère òrìṣà? Èmi ó dá a lóhùn, èmi ó sì ṣe ìtọ́jú rẹ. Mo dàbí igi junifa tó ń fi gbogbo ìgbà tutù, èso tí ìwọ ń so si ń wá láti ọ̀dọ̀ mi.” Ta ni ọlọ́gbọ́n? Òun yóò mòye àwọn nǹkan wọ̀nyí. Ta a ní ó mọ̀? Òun yóò ní ìmọ̀ wọn. Títọ́ ni ọ̀nà Olúwa àwọn olódodo si ń rìn nínú wọn, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ni yóò kọsẹ̀ nínú wọn.
Every verse in Hosea 14
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.